Go to full page →

KI ISE LASAN IOK 94

1. Iwọ ti a ti s̩e li as̩epe nipa Ijiya
Lori ẹniti a gbe agbelebu buburu ni le
Ni wakati ibanujẹ, aisan ati ikerora,
Ko si ojiya kan ti o yipada si ọ lasan.

2. Awọn arọ alabukù, alaisàn ati afọju
Ko wa ibagbe rere rẹ lasan ;
Nisisiyi awa ri ọ ninu airi rẹ,
A si njis̩ẹ fun ọ nipa wọn.

3. A! Olugbala alanu Iwo le wo
Awọn irora ati ọgbẹ ti Iwọ jiya sàn
Nitori gbogbo ẹnito o ba nfẹ Õnisegun nla
Ikunra iwosan Rẹ li a bẹbẹ fun.

4. Jowọ wo ọkan ti o gbọgbẹ san
Jọwọ gba okan wa ti o kun fun ẹs̩ẹ la
Fun wa ni ẹ̀kun iye ati ilera.
Ki awa le mã sin Ọ titi lai. Amin. IOK 94.2