Go to full page →

Ìmọ́lẹ̀ Nínú Òkùnkùn IIO 165

Láàrín àwọn olùgbé ayé tí wọn tàn kálẹ káàkiri ni a ti rí àwọn tí wọn kò tíì foríbalẹ fún òrìṣa báálì. Gẹgẹbí ìràwọ ojú ọrun èyí tí ó máa ń yọ lálẹ, àwọn olótìtọọ wọnyí yóò tàn nígbà tí òkùnkùn bá bo ayé mọle. Ní ibi gbogbo ní ilè ayé, ní ilẹ adúláwọ ní o tàbí ní ìjọ Àgùdà ní Yúròpù, tàbi gúsù Amẹríkà tàbí ní Ṣaínà, tàbí ní Ińdìà, ní erékùsù lórí òkun àti ní gbogbo ibi tí òkùnkùn gbogbo ti bo ayé mọlẹ ni Ọlọrun ti ní àwọn ènìyàn tí wọn yóò tàn láàrin òkùnkùn ayé láti fi ìmọlẹ Rẹ hàn tí wọn yóò fi ọnà ìṣìnà tí ayé ń rìn hàn wọn ti wọn yóò gba agbára ìsọdọtun láti gbọràn sí òfín Ọlọrun hàn. Ǹjẹ nísisìnyí tí wọn ń fi ara hàn níbi gbogbo jákèjádò àgbáyé tí Sátánì sì ń halẹ láti ṣe ikú pa gbogbo enití kò bá jẹ olótìtóó sí òfin ọjọ ìsimi èké, nígbà náà ni olótìtọọ wọnyí tí wọn kò ní ẹgàn, àwọn ọmọ Ọlọrun tí wọn kò lábùkù yóò tàn gẹgẹbí ìmọlẹ ní gbogbo ayé. Bí òkùnkùn ṣe kùn tó bẹẹ ni ìmọlẹ wọn ń tán síi (Prophets and Kings, pp. 188, 189). IIO 165.2

Nígbà tí ìgbì ìpọnjú bá bì lù wá, àwọn àgùtàn tòótọ yóò gbọ ohùn olùṣọ àgùtàn. Ipa takun-takun ni a óò sà láti gba àwọn tí ń ṣègbé là, ọpọlọpọ tí ó sì ti ṣáko lọ ni yóò sí padà tọ Olùṣọ Àgùntàn wa.-Signs of the Times (Australia), Supplement, Jan. 26, 1903. IIO 166.1