Go to full page →

Ríran Àwọn Òṣìṣẹ́ Lọ́wọ IIO 201

Inú Ọlọ́run yóò ti dùn tó láti ríi wí pé àwọn ènìyàn Rẹ̀ mú òtítọ́ ìsìsìnyí lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àlejò tí ó wà ní Amẹ́ríkà ju bí wọ́n ti ṣe láti ẹ̀yìn wá lọ. Ẹ jẹ́ kí a jẹ olùgbọ̀wọ́ fún alàgbà Olsen àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ẹ máà ṣe jẹ́ kí a dá iṣẹ́ náà dá wọn pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń lo ìwọ̀ǹba owó díẹ̀ tí wọ́n ní láti ṣe iṣẹ́ náà.-Review and Herald, Oct. 29, 1914. IIO 201.2

Alàgbà Olsen sọ fún wa láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí láti ibìkan ní mímu òtítọ́ yìí lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Italy, Serbia, Rumania, Russia àti àwọn orílẹ̀ èdè gbogbo tó kù. A bá a yọ̀ púpọ̀ nínú ohun gbogbo tí ó ti ṣe ṣùgbọ́n síbẹ̀ ọkàn wa bàjẹ́ nígbà tí a mọ̀ wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ni a kò tí ì ṣe nítorí pé kò sí owó. A lérò wípé owó ọrẹ pàtàkì tí a gbà nínú àwọn ìjọ wa ní Amẹ́ríkà yóò lè jẹ́ kí àwọn tí wọ́n ti fi ara wọn jìn fún iṣẹ́ yìí ṣe iṣẹ́ náà takuntakun ní àwọn ìlú ńlá tí ó wà ní ilẹ̀ náà. Nípa ṣíṣe báyìí ni a ó lè jèrè ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sí ọ̀dọ̀ wa àti láti ọ̀dọ̀ àwọn tí a jèrè wọ̀nyìí a ó lè rí àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn yóò polongo òtítọ́ yìí sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tiwọn bákan náà, èyí tí ó wà ní ilẹ̀ wa àti tí àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé mìíràn.-Review and Herad, Oct. 29, 1914. IIO 201.3