Go to full page →

Ọ̀nà Bí Ọ̀run Ti Ń Ṣẹ Àkọsílẹ̀ IIO 222

Gbogbo iṣẹ́ rere tí à ń ṣe láyé ni àwọn ángẹ́lì ń fi òtítọ́ inú kọ ọ́ sílẹ̀.-Testimonies, Vol. 1, p. 198. IIO 222.1

Gbogbo iṣẹ̀ ìfẹ́, ọ̀rọ̀ rere, àdúrà fún àwọn tí ń jìyà tí a ń pọ́n lójú ni a ń kọ sílẹ̀ níwájú ìtẹ́ ayérayé tí a sì fí ń pamọ́ sínú àkọsílẹ̀ tí kò leè parun.-Testimonies, Vol. 5, p. 133. IIO 222.2

Gbogbo ìròyìn àṣeyọrí wa nípa tún tú iṣẹ́ òkùnkùn ká àti títan ìmọ̀ Kírísítì sí òkèèrè ni a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀run. Bí a ṣe ń sọ àwọn ìwà rere yìí níwájú Bàbá bẹ́ẹ̀ni ayọ̀ ń kún inú gbogbo àwọn ogun ọ̀run.-The Acts of the Apostles, p. 154. IIO 222.3

Àwọn ángẹ́lì ní a gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àwọn olùránlọ́wọ̀ wa. Wọ́n rí àwọn àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ọmọ ènìyàn lọ́ sí ọ̀run nígbà gbogbo.-Southern Watchman, April 2. 1903. IIO 222.4

Ìbá dára láti rántí àwọn àkọsílẹ̀ ní ọ̀run wí pé láti inú ìwé tí a kọ sílẹ̀ láìsí àṣìṣe ni a ó ti dá wa lẹ́jọ́. Gbogbo ànfààní tí a ní láti ṣiṣẹ́ Ọlọ́run tí a fi ojú parẹ́ ni a kọ sílẹ̀ àti nínú ìwé ìrántí ni a ń ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo iṣẹ́ ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́.-Prophets and Kings, p. 639. IIO 222.5