Go to full page →

Sùúrù IIO 230

Láti jé òsìsé pèlú Jésù, a gbodò ní òpòlopò sùúrù pèlú àwon tí ò ń sisé fún, kìí se kí o máa kégàn isé náà bíkòse kí o máa fojú sónà sí èsì ayò. Nígbà tí àwon tí à ń sisé fún kò bá se ìfé okàn rè, nígbà náà ni o ó wá so ní okàn re pé “Jé kí won máa lo, won kò tilè ye ní eni ìgbàlà”. Sé Krístì náà ì bá ti se béè hùwà s’áwon òtòsì tí a ti tanù láwùjo ní irú ònà béè? Ó kú láti gba òtòsì elésè là, tí a bá fi irú èmí kan-náà sisé pèlú Enití ó jé àpeere wa, Enití àwa ń tèlé, kí a sì wá fi èsì sílè sí owó Olórun, a kò ní leè se òdiwòn ohun rere èyí tí àwa ti se.-Testimonies, Vol. 4, p. 132. IIO 230.4

E sisé pèlú ìfé àti sùúrù fún gbogbo àwon tí e bá se alábápàdé rè. E má se fi èmí àìní-sùúrù bá won lò. E máse so òrò búburú kankan. E jé kí ìfé Kristi kó wà nínú okàn yín, kí òfin inú rere sì wà létè yín.-Testimonies, Vol. 9, p.41. IIO 230.5