Go to full page →

Ìkáààánú Àti Ìbánisé IIO 232

Ní síse isé Olúwa, a nílò okùnrin àti obìnrin tí ó ní ìkáánú fún ìjìyà omo aráyé, sùgbón irú ìkáánú yìí kò wópò.-Review and Herald, May 6, 1890. IIO 232.5

A nílò ìkáàánú bí ti Jésù, kì sé bí ti ìbádárò àwon tí ó rò pé wón pé, sùgbón ìkáàánú fún àwon tálákà, àwon tí ó ń jìyà, okàn tó ń pòruurù, àwon okàn tí ìdálébi ń bá jà, èsè, ìrònúpìwàdà, ìdánwò àti ìrèlè ń bá fínra. A ní láti to àwon ènìyàn lò, kí a bá won se bí alàànù Olòrì Àlùfáà wa,ṣe nì ìmọ̀lárá ti àilera a wọn.-Gospel Workers, p. 141. IIO 232.6

Gégébí ènìyàn à ń pàdánù púpò nípa ìwà àìníkáánú àti àìbánisépọ̀ pèlú elòmíràn. Eni tí ó ń hùwà mó lè dá gbé, dá se ohun gbogbo ń tàpá sí ìlànà tí Olorun gbé kalè fún ìbásepò èdá. Omo Olorun ni a jé, a nílò ara wa fún ìdùnnú àti ayò. Olorun tí ó dá gbogbo ènìyàn ló ni wá, gbogbo wa ni a sì gbodò kópa nínú ayé yìí. Nípa ìbágbépò ní ònà tòótó ni a ti ní ìkáánú pèlú àwon ará wa, béè ni à sì má láyò nínú akitiyan wa láti bùkún elòmíràn.-Testimonies, Vol. 4, p.71. IIO 233.1

Olùgbàlà wa jé àlejò níbi àpèje Farisií, Ó lo sí ibi àpèje àwon olówó, àti tálákà, bí ìse rè, gbobgo ohun tí ó bá dojúko lo ǹ se pèlú èkó òtító rè, kìí se eléyàmèyà.-Christ’s Object Lessons, p. 219. IIO 233.2