Go to full page →

Ìyàsótò IIO 235

Ìwà mímó tòótó ni fífi gbogbo ara wa jìn nínú isé Olúwa. Èyí jé ipò tí Krìstèénì gbodò gbé nítòótó. Ó ń fé okàn, èmí, ara àti agbára wa. A kò gbodò ké ara wa. Enití ó bá gbé fún ara rè nìkan kìí se Krìstèénì,-Christ’s Object Lesson, pp. 48-49. IIO 235.3

Ohun àkókó láti kó fún àwon tí ó fé jé òsísé Olórun ni láti kú sí ara won, wón pèsè won láti ní ìwà bí ti Kristi. Èyí kìí se ohun tí ó gba nípa èkó ní àwon ilé ìwé sáyéǹsì. Èso ogbón tí o ń rí gbà láti òdò Olùko mímó ni.-The Desire of Ages, pp. 249-250. IIO 235.4

Kìí se érí tí ó múná dóko ni láti so pé Krìstèéní ni ènìyàn nítorí pé ó sàfihàn ayò púpò níti èmí ni àwon ohun síse tí ó jé àrà òtò. Ewà mímó kìí se ìgbàsókè. Ó jé jíjowú ara eni pàápàá fún ohun ti Olórun, ó jé gbígbé nípa òrò gbogbo tí ó ti enu Olórun jáde, ó jé síse ìfé Olórun, ó jé gbígbàgbó nínú Olórun nígbà ìdánwò, nínú òkùnkùn àti ìmólè, rínrìn pèlú ìgbàgbó láì wojú, gbígbékèlé Olórun pèlú èmí ìgboyà láì siyèméjì àti síninmi nínú ìfé Rè.-The Act of Apostle, p. 51. IIO 235.5