Go to full page →

Ọ̀DỌ́ NÍNÚ IṢẸ́ ÌJỌ IIO 30

Ẹ̀bùn ọ̀dọ́mọdé tí a gbé kalẹ̀ dáadáa, tí a sì kọ́ dáadáa, ni a nílò nínú àwọn ìjọ wa.Àwọn ọ̀dọ́ á ṣe nǹkan pẹ̀lú gbogbo agbára,bi ko ba jẹ pe a bá darí àwọn agbára yìí s’ọ́nà tòòtọ̀ wọn yóò lò ó l’ọ́nà tí yóò fi pa ohun ẹ̀mí i wọn lára, tí yóò si mú ìfarapa bá àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn.- Gospel Workers, p.211 IIO 30.4

Nígbà tí ọ̀dọ́ bá fi ọkàn wọn fún Ọlọ́run, ipa wa lórí i wọn kò gbọdọ̀ dẹ́kun.Wọ́n gbọdọ̀ nífẹ̀ ẹ́ sí iṣẹ́ Ọlọ́run, tí yóò sì darí i wọn láti rí i pé Ó ń retí wọn láti ṣe nǹkan fún ìdàgbà sókè iṣẹ́ ẹ rẹ̀, kò tó láti fihàn bí a ṣe nílò láti ṣe é,àti láti rọ̀ awọ́n ọdọ láti kópa. A ní láti kọ́ wọn láti ṣiṣẹ́ fún Olúwa wọn, a ní láti kọ́ wọn, bá wọn wí,kí a sún wọ́n jiná lọ́nà tí wọn yóò lò láti jèrè àwọn ọkàn fún Krístì. Kọ́ wọn láti gbìyànjú ní ìdákẹ́jẹ́, láì díbọ́sn l’ọ́nà tí wọn yóò ṣe ran àwọn ọ̀dọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn lọ́wọ́ láti jẹ́ kí àwọn ẹ̀ka ọlọ́kan òjọ̀kan ti iṣẹ́ ìhìnrere gbìyànjú láti tò lẹ́sẹẹsẹ,lọ́nà tí wọn yóò fi kópa,jẹ́ kí wọn fún wọn ní àṣẹ àti ìrànlọ́wọ́.Nípa báyìí,wọn yóò lè kọ́ láti ṣiṣẹ́ f’Ọ́lọ́run.-Gospel Workers, p.210. IIO 30.5