Go to full page →

Gbèdéke Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run IIO 62

Olúwa ń fẹ́ kí a gba gbogbo ẹ̀kọ́ tí ó yẹ pẹ̀lú ohun tí ó wà níwájú u wa ní èrò láti fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Kò sí ẹni tí ó mọ ibi tàbí báwo ni wọ́n ṣe le pè wọ́n láti ṣiṣẹ́ tàbi sọ̀rọ̀ fún Ọlọ́run. Bàbá a wa tí ń bẹ lọ́run nìkan rí ohun tí ó lè mú jáde láti ara ènìyàn. Àwọn ohun tí a lè ṣe wà níwájú u wa èyí tí àìlera ìgbàgbọ́ ọ wa kò jẹ́ kí a mọ̀. Ọkàn an wa ni a gbọdọ̀ kọ́ pé tí ó bá ṣe é ṣe a lè gbé òtítọ ọ̀rọ̀ ọ Rẹ̀ síwájú àwọn aláṣẹ ayé tí ó ga jù ní ọ̀nà láti fi yin orúkọ ọ Rẹ̀ lógo.- Christ’s Object Lessons, pp.333,334. IIO 62.4

Àwọn wo ni ó ti gbáradì láti lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà a Rẹ̀? Ọlọ́run kò ní inú dídùn sí aláìmọ̀kan. Ó fẹ́ kí a lo ohun tí ó dára jùlọ àti ohun tí ó ga níti àwọn ẹ̀bùn tí ó ti fifún wa.- Review and Herald,April 2, 1889. IIO 62.5