Go to full page →

Àkójọpọ̀ ìyílọ́kàn padà IIO 67

Awọn àgbáyé ni á yóò yí l’ọ́kàn padà, kì í ṣe nípa ìwáásù orí i pẹpẹ, bíkòṣe ìgbé ayé ìjọ. Alufaa tí ó wà níbi ìkọ̀wé kéde ìmọ̀ ti ìhìnrere; ìwúlò ìbọ̀wọ̀fún Ọlọ́run ti ijọ fi agbára rẹ̀ hàn.- Testimonies, vol.7, p.16. IIO 67.5

Iṣẹ́ Oluwa ninu ayé yìí kò le è parí tán àyàfi tí àwọn ọkunrin ati awọn obinrin tí a kàkún ọmọ ìjọ bá ṣa ara wọn jọ sí iṣẹ́ náà, tí wọ́n sì ṣọ̀kan pẹ̀lu ìgbìyànjú pẹ̀lú awọn alufaa ati awọn oṣiṣẹ ijọ.-Gospel Workers, p.352. IIO 68.1

Iwaasu jẹ́ abala iṣẹ́ tí ó kéré jù tí a níláti ṣẹ fún ìgbàlà àwọn ọkàn. Ẹ̀mí Ọlọ́run ń yí ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pada nípa ti òtítọ́, ó sì ń fi wọ́n sí ọwọ́ àwọn ijọ. Awọn alufaa lè kó ipa tí ó yẹ kí wọn kó, ṣugbọn wọn kò le ṣe iṣẹ́ tí ìjọ yẹ kí ó ṣe.- Testimonies, vol.4, p.69. IIO 68.2

Ìtànkálẹ̀ òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò wà fún àwọn àlùfáà tí a gbọ́wọ́ lé lórí nikan. A gbọdọ̀ tan òtítọ́ yìí kálẹ̀ nípasẹ̀ àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní àtẹ̀lé Krístì. A gbọdọ fúrúgbìn ní ẹ̀gbẹ́ ẹ (gbogbo omi (Correct.)Review and Herald, Aug.22, 1899. IIO 68.3

Awọn alufaa le wàásù tí ó wuyì àti ọ̀rọ̀ sísọ tí ó lágbára, ati ọ̀pọ̀ iṣẹ́ lè jáde láti mú kí ijọ dàgbà kí ó sì ṣe rere; ṣùgbọ́n àyàfi ti ọmọ ijọ kọọkan ba ṣa ipá a wọn gẹgẹ bi iranṣẹ ti Jesu Kristi,ijọ yoo wa ninu òkùnkùn wọn kò sì ní lágbára. Pẹ̀lú u bí ilé ayé ṣe dúdú tí ó sì le tó, dídúró ṣinṣin láì yẹsẹ̀ yóò nípa rere. - Testimonies, vol.4, pp, 285,286. IIO 68.4