Go to full page →

Àpẹẹrẹ Rere IIO 71

Àpóstélì (Pọ́ọ̀lù) rò pé lọ títí ni òun wà fún ìṣàkóso ti ìlera ti ẹ̀mi àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yípadà ní abẹ́ iṣẹ́ ẹ rẹ̀. Ohun tí ó fẹ́ fún wọn ni pé kí wọn lè dàgbà nínú ìmọ̀ ọ ti Ọlọ́run òtítọ́ nìkan, àti Jésù Krístì ẹni tí Ó rán. Báyì í nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ yóò bá àwọn ẹgbẹ́ ké kè ké lọ́kùnrin àti lóbìnrin pàdé tí wọ́n fẹ́ Jésù tí wọ́n sì tẹríba nínú àdúrà, tí wọ́n sì ń bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè dúró nínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú u Rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó ń gbà wọ́n nímọ̀ràn bí fún ìlànà tí ó dára nípa fí fifún àwọn mìràn ìmọ́lẹ̀ ti òtítọ́ ìhìnrere. Àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ó ń bẹ Ọlọ́run láti pa wọ́n mọ́ lọ́wọ́ ewu, kí ó sì rán wọ́n lọ́wọ́ láti lè jẹ́ olùfọkànsìn ajíhìnrere tí ó sì jẹ́ akíkanjú.- The Acts of The Apostles, p.262. IIO 71.1