Go to full page →

Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì IIO 80

A gbé ayérayé ṣíwájú ù wa.A fẹ́rẹ̀ gbé aṣo ìlékè náà sókè . Kíni à ń rò nípa, tí a dìrọ̀ mọ́ ìdẹ̀rùn ìfẹ́ ìmọ-tara-ẹni-nìkan-an wa nígbà tí àyíká a wa kún fún àwọn ọkàn tó ń ṣègbé? IIO 80.1

Ǹ jẹ́ ọkàn-an wa ti yigbì pátápátá? IIO 80.2

Ṣé a kò rí tàbí lóye pé a níṣẹ́ láti ṣe fún àwọn ẹnìkejì i wa? IIO 80.3

Ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ṣé o wà lára àwọn tí wọ́n lójú tí wọn kò fi ríran, wọ́n létí wọn kò fi gbọ́ràn? IIO 80.4

Ṣé lásán ni Ọlọ́run fún ọ ní ìmọ̀ ti ara à rẹ? IIO 80.5

Ṣé láṣán ni ó ti rán ìkìlọ̀ lẹ́yin ìkìlọ̀ sí ọ pé òpin ń súnmọ́? IIO 80.6

Ṣé o gbàgbọ́ nínú jíjẹ́wọ́ ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀ nípa ohun tí ó ń bọ̀ wá sórí aye? IIO 80.7

Ṣé o gbàgbọ́ pé ìdájọ́ Ọlọ́run ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí àwọn olùgbé inú ayé? IIO 80.8

Báwo ni ó wa ṣe le jòkó pẹ̀lú ìdẹ̀ra láìbìkítà àti láì náání?- Testimonies, vol.9, pp. 26, 27. IIO 80.9