Go to full page →

Tọ Àwọn Ènìyàn IIO 121

A kò nílò láti dúró de àwọn ọkàn láti wá bá wa; o ní láti wá wọn níbi tí wọ́n bá wà. Nígbà tí a bá ti wàásù ọ̀rọ̀ náà ní orí i pẹpẹ, iṣẹ́ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni a kò ní lè fi ìhìnrere lọ̀ àyàfi tí a bá gbé e tọ̀ wọ́n lọ.- Christ’s Object Lessons, p.229. IIO 121.3

Iṣẹ́ ìhìnrere jẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ àdéhùn ń lá sí ìjọba ọ̀run. Àwọn àtẹ̀lé e RẸ̀ ní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìtara fún àwọn ọkàn, láti fún wọn ní ìwé ìpè àánú, wọn kò ní láti dúró de àwọn ènìyàn láti wá sí ọ̀dọ̀ ọ wọn; àwọn ni ó ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn pẹ̀lú ìhìnrere e wọn.- The Acts of the Apostles, p.28. IIO 121.4