Go to full page →

Pípè sí Ìpàdé Ìhìnrere IIO 130

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ n ǹkan ni àwọn ènìyàn lè ṣe tí wọ́n bá ní ọkàn láti ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sì wà tí wọn kò ní lọ sí ilé ìjọsìn láti gbọ́ ìwàásù òtítọ́ tí wọ́n wà. Pẹ̀lú ìgbìyànjú ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà tí ó rọrùn àti ọgbọ́n a le è rọ àwọn wọ̀nyí láti yí ẹsẹ̀ ẹ wọn lọ sí ilé Oluwa. Ìdálẹ́bi le è wà lọ́kàn-an wọn nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n bá gbọ́ ìwàásù lórí òtítọ́ ọ ti àsìkò yìí. Ìbá jẹ́ pé wọ́n kọ ẹ̀bẹ̀ ẹ̀ rẹ, máṣe rẹ̀wẹ̀sì. Forítì í títí tí àṣeyọrí yóò fi dé ìgbìyànjú ù rẹ ládé.- Review and Herald, June 10, 1880. IIO 130.1