Go to full page →

Apá Ọ̀tún Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ IIO 134

Léra léra, A ti fún mi ní àṣẹ pé iṣẹ́ oníṣègùn ajihinrere ní láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ iranṣẹ angẹli kẹta bí apá àti ọwọ́ ṣe gbé ara. Lábẹ́ ìtọ́ni Olóri ọ̀run wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ ní ìṣọ̀kan nípa pípèsè ọ̀nà fún wíwá a Kristi.Ọwọ́ ọ̀tun ara òtítọ́ ni ó ní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára,kí ó ṣiṣẹ́ léra léra, Ọlọrun yóò sì fún un ní agbára. Ṣùgbọ́n a kò ṣẹ̀dá a rẹ̀ fún ara. Bákan náà ara kò le è sọ fún apá,“Èmi kò nílò ò rẹ.” Ara nílò apá láti le è ṣiṣẹ́ tí ó lágbára, iṣẹ́ tótọ̀. Àwọn méjèèjì ni wọ́n ní iṣẹ́ tí a yàn wọ́n, ọ̀kọ̀ọ̀kan-an wọn ni yóò sì pàdánù ń lá tí ọ̀kan bá dá ṣiṣẹ́ ní òhun nìkan láì sí èkejì.- Testimonies, vol.6, p.288. IIO 134.4

Iṣẹ́ oniṣegun ajíhìnrere ní láti jẹ́ ṣíṣe....Ó ní láti jẹ́ iṣẹ́ ẹ ti Ọlọrun bí ọwọ́ ṣe jẹ́ sí ara.- Testimonies, vol.8, p.160. IIO 134.5