Go to full page →

Iṣẹ́ ẹ Ìjọ Kọ̀ọ̀kan IIO 135

Iṣẹ iranṣẹ nípa ti àtúnṣe ètò ìlera tí a ní láti gbé lárugẹ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan.- Testimonies, vol.6, p.370. IIO 135.6

Iṣẹ oniṣegun ihinrere gbọdọ̀ jẹ́ ara iṣẹ́ ti ijọ kọọkan ni ilẹ ẹ wa.- Testimonies, vol.6, p.289. IIO 135.7

A ti wà ní àsìkò tí ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ di iṣẹ́ oníṣègùn ajihinrere mú.- Testimonies, vol.7, p.62. IIO 135.8

Iṣẹ atunṣe ti ètò ìlera jẹ́ ọ̀nà tí Oluwa láti dín ìrora tí ó wà nínú ayé e wa kù àti fún sísọ ìjọ ọ RẸ̀ di mímọ́. Kọ́ àwọn eniyan pé wọ́n le è kópa bí ọwọ́ Ọlọ́run tí ń ran ni lọ́wọ́, nípa sísowọ́pọ̀ pẹ̀lú òṣìṣẹ́ Olùkọ́ nípa mímú ti ara àti ti ẹ̀mi bọ́ sípò.Iṣẹ́ yìí ní ìfọwọ́sí i ti ọ̀run, yóò sì ṣí awọn ilẹ̀kùn fún wíwọlé àwọn òtítọ́ mìíràn tí ó ṣe iyebíye. Ààyè wà fun gbogbo eniyan láti ṣiṣẹ́ tani yóò sì gba iṣẹ́ náà pẹ̀lú oye.Testimonies,vol.9, pp.112,113. IIO 135.9

Àsìkò àwọn ìkọlù wà níwájú u wa, ṣùgbọ́n ẹ máṣe jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ àìgbàgbọ́ tàbí rẹ̀wẹ̀sì. Ẹ jẹ́ kí a rántí pé a gbé iṣẹ́ ẹ ti ìwòsàn lọ sí àgbáyé tí ó kún fún àwọn ọkàn tí ó ń ṣàárẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀.- Special Testimonies, Series B, No8, P.24. IIO 136.1

Tí a bá ṣe àkóso, iṣẹ́ yìí, dáadáa yóò gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtòṣì ẹlẹ́ṣẹ̀ là àwọn tí àwọn ìjọ kò bìkítà fún. Ọ̀pọ̀ tí kò sí nínú ìgbàgbọ́ ọ wa ni wọn ń wọ̀nà fún irú ìrànlọ́wọ́ tí ó jẹ́ iṣẹ́ àwọn onígbàgbọ́ tí a ní láti ṣe. Ti awọn eniyan Ọlọryn yóò bá fi ìfẹ́ ojúlówó hàn sí àwọn aládúgbò o wọn, ọpọlọpọ ni a yóò dé ọ̀dọ̀ ọ wọn nípa àwọn òtítọ́ ọ ti àsìkò yìí. Kò sí n ǹkan tí tàbí tí yóò lè fún iṣẹ́ yìí ní ìwà bíi ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ níbi tí wọ́n bá wà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún le è má a yayọ̀ lónìí nínú iṣẹ́ yìí, tí àwọn ti wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ Ọlọrun àwọn sì ń pa àwọn òfin-in RẸ̀ mọ́ yóò ṣiṣẹ́ bí Kristi ṣe ṣiṣẹ́. Nigba tí iṣẹ́ oniṣegun ajihinrere bá jèrè àwọn ọkunrin ati obinrin, ìmọ̀ ìgbàlà a ti Kristi àti òtítọ́ ọ RẸ̀, owó ati sí ṣiṣẹ́ tìtara tìtara ni a le è ná sórí i rẹ̀; nítorí ó jẹ́ iṣẹ́ tí yóò ní ìforítì.- Testimonies, vol.6, p.280. IIO 136.2

Jẹ́ kí àwọn ènìyàn-an wa fihàn pé wọ́n ní ìfẹ́ tòótọ́ nínú iṣẹ́ oníṣègùn ajíhìnrere. Jẹ́ kí wọn múra sílẹ̀ fún ìwúlò nípa kíka àwọn ìwé tí wọ́n kọ fún ìkọ́ni i wa ní ipa àwọn ọ̀nà yìí. Ohun tí ó tọ́ sí àwọn ìwé yìí ju ìfetísílẹ̀ àti ìmọrírì tí wọ́n rí gbà lọ, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà fún ànfààní i gbogbo eniyan láti ní òye a ti kọ ọ́ fún ìdí pàtàkì fún ìkọ́ni àwọn ìpìlẹ̀ ẹ ti ètò ìlera. Awọn tí wọ́n ti kọ́ tí wọ́n sì ti mú àwọn ìpìlẹ̀ yìí lò ni yóò ní ìbùkún tí ó pọ̀ lára àti ní ẹ̀mí. Níní òye ìmọ̀ ọ ti ètò ìlera yóò jẹ́ ìdáàbò bò ní ìtakò ọ̀pọ̀ ohun búburú tí ó ń pọ̀ ọ sí i léraléra.- Testimonies, vol.7, p.63. IIO 136.3

A ti fún mi ní ẹ̀kọ́ pé àwọn iṣẹ́ oniṣegun ajihinrere yóò ṣe àwárí, nínú ìjìnlẹ̀ ẹ ti ìrẹ̀sílẹ̀, àwọn ènìyàn tí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fi ara wọn fún àìní-wọ̀n-tún-wọ̀n-sì, tí wọ́n ní àwọn ìwàkiwà, yóò dáhùn sí irú iṣẹ́ tí ó tọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n nílò láti dá wọn mọ̀ kí a sì gbà wọ́n níyànjú.Dídúró ṣinṣin,sùúrù, ìtara ìgbìyànjú ni wọn yóò béèrè láti gbé wọn sókè. Wọn kò lè mú ara a wọn bọ́ sípò. Wọ́n le è gbọ́ ìpè Kristi, ṣùgbọ́n etí i wọn wúwo láti ní ìtumọ̀ ọ rẹ̀; àwọn ojú u wọn ti fọ́ jù láti rí ohun rere tí a fi pamọ́ fún wọn. Wọ́n ti kú sínú ìrékọjá ẹ̀ṣẹ̀. Síbẹ̀, kò yẹ kí a yọ àwọn wọ̀nyí sílẹ̀ nínú àpèjẹ ìhìnrere. Wọ́n ní láti gba ìpè, “Wá”. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè jẹ́ aláìyẹ, Olúwa wípé, “Ẹ fi tipátipá mú wọn wọlé.” Ẹ máṣe fetí sílẹ̀ sí àwáwí kankan. Nípa ìfẹ́ àti inúrere dì wọ́n mú dáadáa.- Testimonies, vol.6, pp.279,280. IIO 136.4

Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ yìí (pínpín àwọn ìwé àtẹ̀jáde) ni láti lọ múra láti ṣe iṣẹ́ oniṣegun ajihinrere. Àwọn aláìsàn àti àwọn tí ó ń kérora ni a ní láti ràn lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tí a ti ṣe iṣẹ́ àánú yìí fún yóò gbọ́ wọn yóò sì gba àwọn ọ̀rọ̀ ìyè.- Testimonies, vol.9, p.34. IIO 137.1

Tani ó múra sílẹ̀ láti di oyè ti oníṣègùn ajíhìnrere mú?...Òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ó gbọdọ̀ ní òye tí ó dángájíá. Báyìí ní ọ̀nà tí ó ga, tí ó sì gbòòrò o le è fi òtítọ́ lọ̀ wọ́n bí ó ṣè wà nínú u Jesu.- Testimonies, vol.7, p.70. IIO 137.2

Ẹ jẹ́ kí iṣẹ́ Olúwa tẹ̀síwájú. Ẹ jẹ́ kí iṣẹ́ oniṣegun ajihinrere ati iṣẹ́ ẹ̀kọ́ kíkọ́ tẹ̀síwájú. Ó dámi lójú pé èyí jẹ́ aláìtó fún wa, - ìtara, fífi àsìkò sílẹ̀, òye àwọn òṣìṣẹ́ tó dáńgájíá. - Testimonies, vol.9, pp.168, 169. IIO 137.3

Jẹ́ kí wọn gbé àtúnṣe ètò ìlera tí ó yè tọ ará ìlú tí óye e wọn kò tó n ǹkan lọ níti àwọn ìlànà yìí. - Testimonies, vol.9, p.118. IIO 137.4

A ti fi àṣẹ fún mi láti sọ fún àwọn olùkọ alátùńṣe ètò ìlera, Lọ síwájú. Ayé nílò gbogbo ipa tí a ba le sà láti dena iwa. Jẹ́ kí àwọn tí ó ń kọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ angẹ́lì kẹta dúró nítòótọ́ sí ohun tí a mọ̀ wọ́n mọ.- Testimonies, vol.9, p.113. IIO 137.5