Go to full page →

Àwọn Ilé-Ìwé Fún Oúnjẹ Sísè IIO 139

A ti fun mi ní ìmọ̀ láti gbìyànjú láti ṣe àkóso ètò ẹ̀kọ́ fún oúnjẹ ṣíṣè ní àwọn ilé-ìwé e wa ní ibi gbogbo tí a ti ń ṣe iṣẹ́ oníṣègùn ajíhìnrere. Gbogbo rírọ̀ láti darí àwọn eniyan láti ṣàtúnṣe ni a gbọdọ̀ gbé síwájú u wọn. Kọ́ wọn láti ṣe àtúnṣe tí wọ́n bá lè ṣe nínú pípèsè ounjẹ, kí o sì gbà wọ́n níyànjú láti fihan àwọn mìíràn tí wọn fẹ́ kẹ́kọ̀ ọ́.- Gospel Workers, pp.362,363. IIO 139.2

Ile ẹ̀kọ́ fún ounjẹ sísè ni a gbọdọ̀ dìmú. A ní láti kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ láti ṣe oúnjẹ tí ó péye. A gbọdọ fihàn wọ́n ìdí tí wọ́n fi ní láti kọ àwọn ounjẹ tí kò le è mú ìlera bá ara. IIO 139.3

Ṣùgbọ́n a kò gbọdọ̀ ṣe alágbàwí fún oúnjẹ tí ó lè fi ẹbi pa ènìyàn. Ó ṣe é ṣe kí a ní ounjẹ tí ó ń fún ni lókun láì sí lílo ewé igi wẹ́ẹ́wẹ́ tí a ń fi sínú omi (Tea), coffee, ati ẹran. Iṣẹ́ ẹ kíkọ́ àwọn ènìyàn bí a ṣe lè ṣe oúnjẹ tí ó péye tí ó sì ń mú kí ènìyàn nífẹ̀ ẹ́ sí ounjẹ jíjẹ, ni ó ṣe pàtàkì jù. - Testimonies, vol.9, p.112. IIO 139.4