Go to full page →

Àṣírí Àṣeyọrí IIO 144

Mú ìtara pẹ̀lú ìgbónára wọ inú àwọn àdúrà à rẹ àti sínú Bíbélì kíkà à rẹ, àti sínú ìwàásù ù rẹ, kí o ba à le tẹ̀ ´ẹ mọ́ wọn létí pé àwọn òtítọ́ tí ó jẹ́ mímọ́ tí ò ń sọ fún àwọn ẹlòmíìràn jẹ́ òtítọ́ tí ó yè sí ìwọ náà. Ohunkóhun tí o ṣe fún Jesu, wá pẹ̀lú u gbogbo agbára à rẹ láti ṣe é pẹ̀lú ìtara, máṣe ní ìmọ̀lára pé o ti dé ipò gíga, o kò sì lè lọ síwájú mọ́….Fún ọkàn-àn rẹ ní iṣẹ́, kí o le è gbé òtítọ́ náà kalẹ̀ ní ọ̀nà tí wọn yóò fi ní ìfẹ́ síi. Mú àwọn abala Ìwé Mímọ́ tí ó dùn jù nínú Ìwé Mímọ́ tí o lè gbé ka iwájú u wọn, sọ ojú abẹ níkòó, kí o sì wá ìfarabalẹ̀ ẹ wọn, kí o sì kọ́ wọn ní ọ̀nà a ti Ọlọrun.- Review and Herald, July 28, 1887. IIO 144.1

A le è ṣe iṣẹ́ ń lá yì í nípa fífi Bíbélì lọ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe kà á. Gbé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé olúkúlùkù, rọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀ tòótọ́ sí ẹ̀rí ọkàn ènìyàn,ṣe àwítúnwí fún gbogbo ènìyàn àṣẹ Olùgbàlà, “Wá inú Ìwé Mímọ́”. Kì wọ́n nílọ̀ láti gba Bíbélì bí ó ṣe rí, bẹ̀bẹ̀ fún ìlani lóye ọ̀run, áti nígbà tí ìmọ́lẹ̀ bá tàn, wọn yóò lè fi inú dídùn gba ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ ẹ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan, wọn yóò sì lè gbà á ní abẹ́ ìkọ́ni láìbẹ̀rù.- Testimonies, vol.5, p.338. IIO 144.2