Go to full page →

Iṣẹ́ Ní Àwọn Ìlú Ń lá IIO 152

À ń gbé ní àsìkò tí a ní láti ṣe iṣẹ́ tí ó tóbi. Ìyàn wà ní ilẹ̀ fún ìhìnrere tí ó tọ́, a sì ní láti fún àwọn ọkàn tí ebi ń pa ní oúnjẹ ìyè. Kò sí ànfààní mìíràn tí ó dára láti ṣe iṣẹ́ yìí ju èyi tí a ti fún àwọn òǹtàwé tí wọ́n ya ara a wọn sí mímọ́. Ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún àwọn ìwé tí ó kún fún ìmọ́lẹ̀ iyebíye ti àsìkò yìí ni a gbọdọ̀ fi sínú ilé àwọn ènìyàn ní àwọn ìlú ń lá ń lá a wsa.- Southern Watchman, Nov.20, 1902. IIO 152.2

Alábùkún fún, òtítọ́ ọ Bíbélì tí ń gba ọ̀kan là ni a ti tẹ̀ jáde nínú àwọn tákààdá. Ọ̀pọ̀ ló wà tí wọ́n lè ṣe ìrànlọ́wọ́ nínú u títa àwọn ìwé àsìkò o wa. Ọlọ́run ń pe gbogbo o wa láti wá àti láti gba ọkàn tí ó ń ṣègbé là. Sátánì wà lẹ́nu iṣẹ́ láti tan àwọn àyànfẹ́, àsìkò nìyí fún wa láti ṣiṣẹ́ kí a sì ṣọ́nà. Àwọn ìwé e wa àti tákààdá ni a ní láti mú wá sí etígbọ̀ ọ́ àwọn ènìyàn; Iṣẹ́ ìhìnrere òtítọ́ ọ ti àsìkò yìí ni a ní láti fún àwọn ìlú ń lá ń lá láì jáfara. Ṣé a kò ní dìde sí àwọn iṣẹ́ ẹ swa?- Testimonies, vol.9, p.63. IIO 152.3