Go to full page →

Àgbékalẹ̀ Tó Léwu IIO 214

Ẹ̀rù wípé àwọn yóò pàdánù àwọn ohun ọrọ̀ ayé yíì ni ó mú wọn kọ àdúrà àti pípéjọpọ̀ àwọn ará láti sin Olúwa sílẹ̀, kí wọ́n baà lè ní àkókò fún iṣẹ́ wọn. Nípa ìṣe wọn ni wọ́n ti fihàn ẹni tí àwọn ń gbé lárugẹ. Wọn kọ gbogbo iṣẹ̀ ìsìn sílẹ̀ èyí tí ó lèè mú wọn dàgbà nínú ẹ̀mí, nítorí ohun ti ayé yìí, wọ́n kọ̀ láti gba ìmọ̀ ìfẹ́ ti ọ̀run. Wọ́n kùnnà ìwà pípé tí Onígbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ni wọn kò kójú òṣùwọ̀n níwájú Ọlọ́run. Wọ́n kọ́kọ́ lépa ohun ìfẹ́ ti ayé tí ó wà fún ìgbà díẹ̀ bẹ́ẹ̀ni wọ́n ja Ọlọ́run lólè àkókò wọn tí wọn ìbá lò láti fi jìn fún iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀. Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run ti sààmì sí lára láti gba ègún dípò ìbùkún.-Testimonies, Vol. 2, p. 654. IIO 214.1