Go to full page →

Ọ̀dọ́ Lásán ni Tímótíù nígbà Tí a Yàn-án. IIO 31

Pọ́ọ̀lù rí i pé Tìmótíù jẹ́ olódodo, olùfọkànsìn, àti olóótọ́, ó wá yàn àn gẹ́gẹ́ bí ẹnìkejì i rẹ̀ nínú iṣẹ́ àti ìrìn àjò.Àwọn tí wọ́n ń kọ́ Tìmótíù nígbà èwe rẹ̀ rí èrè iṣẹ́ wọn nípa rírí ọmọkùnrin tí a fi sí ìkáwọ́ wọn tí ó ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú àpóstélì alágbára. Tìmótíù jẹ́ ọ̀dọ́ lásán nígbà tí Ọlọ́run yàn án láti jẹ́ olùkọ́. Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ tí ó ní fẹsẹ̀múlẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ tí ó kọ́ níbẹ̀rẹ̀ pé ó yẹ láti gba ipò gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù. Bí ó ṣe kéré, ó sa ipá a rẹ̀ pẹ̀lu ìwà tútù onígbàgbọ́.- The Acts of the Apostles,pp.203,204. IIO 31.5