Go to full page →

Ṣíṣe Lọ́jọ̀ Fún Ààyè Tí ó Ṣófo IIO 32

Àwọn alábá pín ìnira láarin wa ń ṣubú sínú ikú, ọ̀pọ̀ tí ó jẹ́ aṣáájú nínú ṣíṣe àtúnṣe tí a là kalẹ̀ nípasẹ̀ àwa ènìyàn, ní báyìí, wọ́n ti ń darúgbó, agbára wọn sì ń dínkù nínú ara àti nínú ọpọlọ. Nínú àníyàn wa, a le bèèrè ìbéèrè pé, Tani yóò gba ipò o wọn? Àwọn tì a gbè iṣẹ̀ Pàtàkì tí ó jẹ ìjọ lógún nígbà tí àwọn tí a lè fi ṣe òdiwọ̀n bá ń ṣubú. A kò le saláì má wo àwọn ọ̀dọ́ ti òde òní bí àwọn tí ó lè gbé àwọn ẹrù, àti tí iṣẹ́ yìí máa dá lé lórí. Àwọn yìí ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ gbé isẹ́ níbi tí àwọn tókù fi sílẹ̀ sí, àti ipa wọn yóò ṣ’òdiwọ̀n bóyá iṣẹ́ rere, ẹ̀sìn in wọn àti ìwàbí Ọlọ́run yóò jọba tàbí ìwà àídara àti kèfèrí yóò mú ìdibàjẹ́ àti àídúró ṣinṣin bá àwọn ohun tí ó ṣe iyebíye.-Gospel Workers, p.68. IIO 32.1