Go to full page →

Àwọn Ẹ̀ka Iṣẹ́ IIO 33

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka ló wà tí àwọn ọ̀dọ́ fi lè rí àǹfààní fún ìgbìyànjú tó le è ranilọ́wọ́. A ní láti kó àwọn ẹgbẹ́ jọ pẹ̀lú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó yè kooro láti ṣiṣẹ́ bí àwọn olùtọ́jú aláìsàn, awọn ajihinrere,ati olùkọ ọ Bíbélì, bí olùtàwé, ajíhìnrere àti ajíhìnrere oníṣègùn.- Counsel to Teachers, p.546. IIO 33.1

Á gbọdọ̀ kọ́ àwọn ọ̀dọ́ láti ran ọ̀dọ́ lọ́wọ́, bí wọ́n sì ṣe ń wá ọ̀nà láti ṣe iṣẹ́ yìí, wọn yóò kẹ́kọ̀ọ́ tàbí ní òye tí yóò mú wọn yẹ láti jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ ní ọ̀nà tí ó gbòòrò.- Testimonies,vol.6, p.115. IIO 33.2

A gbọdọ̀ kọ́ àwọn ọ̀dọ́ l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin láti jẹ́ òṣìṣẹ́ ní àdúgbò o wọn àti níbòmíràn. Jẹ́ kí wọ́n fi àwọn ọkàn àti inú u wọn jẹ́ ẹni tí ó l’ọ́gbọ́n nípa iṣẹ́ àsíkò yìí, kí wọn mú kí ara wọn tọ́ ;láti ṣe iṣẹ́ tí ó mú wọn yẹ.- Testimonies,vol.9,pp.118,119. IIO 33.3