Go to full page →

Àṣírí Àṣeyege IIO 33

Ní ìtẹ̀síwájú, awọn ọ̀dọ́kùnrin, ní láti mọ Olúwa, ìwọ yóò sì mọ̀ pé “Ìjádelọ ọ RẸ̀ dàbí òwúrọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ ọ́.” Wá ọ̀nà ní lemọ́ lemọ́ láti mú dára síi. Gbìyànjú tọkàn tọkán láti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Olùgbàlà. Gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ nínú Krístì.Se isẹ́ tí ó ṣe wà láàyè láti gba àwọn ọkàn là fún àwọn tí ó fi ẹ̀mí i rẹ̀ lélẹ̀ fún.. Gbìyànjú ní gbogbo ọ̀nà láti ran àwọn tí o ń bá pàdé lọ́wọ́.... sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó jù ọ́ lọ, àwọn tí yóò ṣe àṣeparí ẹ̀kọ́ ọ̀ rẹ, lẹ́sẹ lẹ́sẹ,àṣẹ lé àṣẹ, díẹ̀ níhìn ín díẹ̀ lọ́hùn ún.Ìbáṣepọ̀ tímọ́ tímọ́ pẹ̀lú u rẹ̀ ẹni tí ó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ bí ìrúbọ láti gba ayé tí ó ń ṣègbé là, yóò mú ọ jẹ́ òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ìtẹ́wẹ́gbà.- Testimonies, vol.6,p.416. IIO 33.4