Go to full page →

TÍTÒ LẸ́SẸẸSẸ FÚN IṢẸ́ ÌSÌN IIO 34

Ọ̀dọ́ l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin, ṣé ẹ kò lé dá ẹgbẹ́ sílẹ̀, àti,bí àwọn ọmọ ogun fún Krístì, fi orúkọ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ yìí, fi gbogbo ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti ẹ̀bun rẹ sínú iṣẹ́ ìsìn Mèsáyà, kí o lè gba ọkàn là kúrò nínú ègbé? Jẹ́ kí ẹgbẹ́ wà ní dídá sílẹ̀ nínú ìjọ láti ṣe isẹ́ yìí….Ṣé ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n fẹ́ Jésù dá ẹgbẹ́ sílẹ̀ fún ara wọn bí àwọn òṣìṣẹ́, kìí ṣe fún àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ẹni tí ń pa sátidé mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ ìjọ ọ wa? - Signs of the Times, May 29, 1893. IIO 34.1

Jẹ́ kí ọ̀dọ́ l’ọ́kùnrin àti l’óbinrin àti àwọn ọmọdé lọ ṣiṣẹ́ ní orúkọ Jésù.Jẹ́ kí wọn wà ní ìṣọ̀kan lórí àwọn ètò àti àwọn ìgbésẹ̀ .Sé o kò lè ṣe àkójọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́, kí ẹ sì ní àkókò láti gbàdúrà papọ̀ kí ẹ sì béèrè ki Olúwa fún-un yin ni oore-ọ̀fẹ́ ẹ RẸ̀, kí ẹ sì ní igbesẹ ìṣòkan?-Youth Instructor, Aug.9, 1884. IIO 34.2