Go to full page →

IPÒ ÀÌLÓKUN TI Ẹ̀MÍ IIO 39

Àkójọpọ̀ ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni kò bìkítà láti tẹ̀lé ìmọ́lẹ̀, fún ìdí èyí wọ́n ti wà ní ipò àìlókun ń lá ti ohun ẹ̀mí.Kì í ṣe ti àìní ìmọ̀ pé àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń ṣègbé báyìí. Wọn kò ní dá wọn lẹ́bi nítorí wọn kò mọ ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè.Òtítọ́ tí ó ti kọjá ìmọ̀ wọn,ìmọ́lẹ̀ tí ó ti tàn sí ọkàn ṣùgbọ́n tí wọn kò bìkítà fún ni yóó dá wọn lẹ́bi. Àwọn tí kò ní ìmọ́lẹ̀ láti bìkítà fún kò ní sí nínú ìdálẹ́bi. Kíni n ǹkan tí a lè ṣe nínú ọgbà àjàrà Ọlọ́run ju èyí tí a ti ṣe? Ìmọ́lè, Ìmọ́lẹ̀ iyebíye tí ń tàn sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run; Ṣùgbọ́n, kò le gbà wọ́n là, àyàfi tí wọ́n bá gbà láti rí ìgbàlà nípa rẹ̀, kí wọn sì gbé ní kíkún lórí i rẹ̀, kí wọn sì tàn án sí àwọn mìíràn tí ó wà lókùnkùn..-Testimonies, vol.2, p.123. IIO 39.2