Go to full page →

Ní Nílò Ìkùnjú u Ti Ọ̀run IIO 39

Àwọn ìjọ nílò láti jẹ́ kí ojú u wọn wà ní yíyàn pẹ̀lú awòojú u ti ọ̀run, kí wọn baà lè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfààní nípa wọn láti jẹ́ aṣojú fún Ọlọ́run, léra léra, Ọlọ́run ti pe àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti lọ sí òpópó’nà, inú ọgbà, kí wọn sì rọ àwọ̀n ènìyàn láti wọlé, kí ilé e Rẹ̀ kí ó lè kún.Síbẹ̀ láarin òjìji àwọn ẹnu ọ̀nà ilé e wa ni àwọn ìdílé e wa tí a kò tí ì fi ànfààní tó tó hàn láti darí i wọn àti láti rò pé a náání tàbí bìkítà fún ọkàn an wọn. Iṣẹ́ tí ó wà ní ìkáwọ́ ọ wa tí Ọlọ́run pe ìjọ sí láti ṣe. A kò ní láti dúró, sọ pé “Tani aládúgbò o wa”?A ní láti rántí pé àwọn aládúgbò o wa ni àwọn tí wọ́n nílò ìkáánú àti ìrànlọ́wọ́ ọ wa. Àwọn àládúgbò ni ọkàn tí ó ti gbọgbẹ́ tí a sì nà nípa ọ̀tá a nì. Àwọn aládúgbò ni ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ ohun ìní Ọlọ́run. Nínú Krístì,àwọn ìyàtọ̀ tí àwọn Júù ṣe nípa tani aládúgbò o wọn ni a tì gbà kúrò. Kò sí ààlà agbègbè, kò sí ìyàtọ̀ atọ́wọ́dá, kò sí àtadànù, kò sí gbajúmọ̀.-Testimonies,vol.6, p.294. IIO 39.3