Go to full page →

Ẹ̀mí Ogun Ń ru Ayé Sókè IIO 54

Aráyé ń gbé dìde sókè pẹ̀lú ẹ̀mí ogun, Àsọtẹ́lẹ̀ orí kọkànlá ti ìwe Dáníẹ̀lì ti fẹ́rẹ̀ wá sí ìmúsẹ. Láìpẹ́ ni ìran ti wàhálà tí a fẹnubà nínú àsọtẹ́lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.- Testimonies, vol.9, p.14. IIO 54.5

A fihàn mí àwọn olùgbé inú ayé nínú ìpẹ̀kun rúdurùdu, ogun ìtàjẹ̀ sílẹ̀, àìní, òsì, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn wà lóde ilè náà....A pe àkíyèsí ì mi sí i láti ìran náà, ó dàbí i pé àsìkò díẹ̀ jẹ́ ti àlàáfíà. Lẹ́ẹ̀kan sí i,àwọn olùgbé inú ayé ni wọ́n gbé wá síwájú ù mi, ẹ̀wẹ̀ gbogbo n ǹkan wà ní ìpẹ̀kun rúdurùdu. Ìjà, ogun àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lu ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn, ìbínú wà níbi gbogbo.Orílẹ̀- èdè mìíràn ń lọ́wọ́ sí ogun àti rúdurùdu. Ogun ń fa ìyàn, àìní àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ ń fa àjàkálẹ̀ àrùn. Àti bákan náà ọkàn àwọn ènìyàn ń bàkù fún ìbẹ̀rù “àti nípa mímójútó àwọn n ǹkan tí ó ń bọ̀ wá sórí ayé.”-Testimonies,vol.1,p.268. IIO 55.1