Go to full page →

Òkùnkùn-un Ti Ẹ̀mi IIO 55

Àsìkò ti ìṣókùnkùn ti ẹ̀mí nìyí nínú ìjọ ti àgbáyé. Àìlóye ohun ti ọ̀run ti fi Ọlọ́run pamọ́ àti òtítọ́ láti fojú wò. Àwọn ikọ̀ ogun ti ẹni búburú i ń kójọ ní agbára. Èṣù ń tan àwọn alábá ṣiṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé òun yóò ṣiṣẹ́ tí yóò di aráyé nígbèkùn. Nígbà tí ìjọ kawọ gbera pẹlu ilọwọọwọ,Sátánì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ń jà fita fita.Àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ kò yí ayé padà; nítorí pé àwọn fúnra a wọn bàjẹ́ pẹ̀lú ìmọ-tara-ẹni- nìkan àti ìgbéraga àti nínílò láti mọ̀ lára ti agbára tí í yíni padà ti Ọlọ́run láarin wọn kí wọn tó lè darí àwọn mìíràn sí jíjẹ́ mímọ́ tàbí òṣùwọ̀n gíga.- Testimonies,vol.9, p.65. IIO 55.2

Ní ayé e wa, bí i ti àtijọ́, àwọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ìmọ̀ àti àwọn àkíyèsí ènìyàn. Àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní òjíṣẹ́ ìhìnrere kò gba gbogbo Bíbélì gbọ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó ní ìmísí. Ọkùnrin olóye kan kọ abala kan; ẹlòmíràn ń ṣe ìbéèrè nípa abala mìíràn. Wọ́n gbé ìdájọ́ ọ wọn kalẹ̀ ga jù sí ọ̀rọ̀ náà; àti pé Ìwé mímọ èyi tí wọn ń kọ dúró lórí àṣẹ ẹ wọn. Àṣẹ àtòkèwá a rẹ̀ ni a sọ dasán. Báyì í àwọn èso àìgbàgbọ́ ni wọ́n gbìn káàkiri; nítorí pé wọ́n ti dabarú àwọn ènìyàn, wọn kò sì mọ ohun tí ó yẹ kí wọn gbàgbọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́ ló wà tí kò yẹ kí ọkàn gbà láàyè.- Christ’s Object Lessons,p.39. IIO 55.3

Ìwà búburú ti ń dé ibi gíga tí kò dé rí tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n ń kígbe “àlàáfíà àti ìgbàlà.” Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ ní láti lọ pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ láti tẹ̀ iṣẹ̀ ẹ wọn sìwàjù, kì a wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun ti ọ̀run, wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀síwájú láì bẹ̀rù pẹ̀lú ìṣẹ́gun, láì lè dúró ìjagun wọn t´ití tí gbogbo ọkàn tí ó wà ní ṣàkání i wọn yóò fi gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti òtítọ́ ti àsìkò yìí.- The Acts of the Apostles, p.220. IIO 56.1

Ó yẹ kí ipò tí ẹ̀sìn wà láyé lónìí bani lẹ́rù. Àánu Ọlọ́run ti di ti ṣiré ṣiré. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó sì ti sọ òfin Jèófà di asán, “fífi òfin ènìyàn kọ́ni ní ẹ̀kọ́”. Iwa èérí gbilẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ ìjọ ní ilẹ̀ ẹ wa; Kì í ṣe irú ìwà èérí tí à ń rò,- ṣíṣẹ́ ọ̀rọ̀ ọ Bíbélì ní gbangba,- ṣùgbọ́n,iwa eeri tí a wọ̀ tàbi wé ní aṣọ ti onígbàgbọ́; nígbà tí wọ́n ń jin ìgbàgbọ́ inú Bíbélì lẹ́sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìfihàn ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àdúrà tí kò lé è tàsé àti ìfaraji tó loorin ati ifọkansin to rinlẹ ti yẹra fun iwa asan. Nítorí èyí, ìyípadà kúro nínú ẹ̀kọ́ tí a ti gbà pẹ̀lú ìfẹ́kúfẹ̀ ẹ́ ti ara ń borí. Ọlọ́run sọ pé “Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nígbà ayé e Lọ́ọ̀tì,... bẹ́ẹ̀ náà ni yóò wà nígbà tí ọmọ ènìyàn yóò farahàn.” Àkọsílẹ̀ ojoojúmọ́ ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti kọjá ń jẹ́rì í sí ìmúṣẹ ti ọ̀rọ̀ ọ Rẹ̀. Ilé ayé ti dé ibi pípọ́n fún ìparun. Láìpẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run ni áò dà jáde àti pé ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ni áò jẹrun.- Patriachs and Prophets, p.166. IIO 56.2