Go to full page →

Ìlànà Ìkọ́ni Fún Ajíhìnrere IIO 59

Ọ̀pọ̀ ni ìbá fẹ́ láti ṣiṣẹ́ tí ó bá jẹ́ pé wọ́n kọ́ wọn bí wọn yóò ṣe bẹ̀rẹ̀. Wọ́n ní láti fún wọn ní ẹ̀kọ́ àti ìgbani níyànjú. Olúkúlùkù ìjọ gbọdọ̀ jẹ́ ilé-ìwé tí a ti ń kọ́ àwọn òṣìṣẹ́ onígbàgbọ́. Ọmọ ìjọ ni a gbọdọ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe ń ka Bíbélì, bí wọ́n ṣe le è lò ó láti kọ́ ilé- ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi, báwo ni wọ́n ṣe lè ran àwọn aláìní lọ́wọ́ àti láti ṣe ìtọ́jú fún aláìsàn lọ́nà tí ó dára, bí wọ́n ṣe lè ṣiṣẹ́ fún ọkàn tí kò tí ì yípadà. Àwọn ilé-ì wé gbọdọ̀ wà fún ẹ̀kọ́ ìlera, oúnjẹ sísè àti onírúurú ní ilé-ìwe ní ọ̀nà tí onígbàgbọ́ lè ṣè rànwọ́ iṣẹ́. Ìkọ́ni nìkan kò gbọdọ̀ wà ṣùgbọ́n iṣẹ́ pàtó ní abẹ́ àwọn olùkọ́ni tí ó lóye. Jẹ́ kí àwọn olùkọ darí ọ̀nà nínú ṣíṣiṣẹ́ láarin àwọn ènìyàn, àti àwọn yókù, ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú u wọn yóò lè kọ́ láti ara àpẹẹrẹ wọn. Àpẹẹrẹ kan sì níye lórí ju àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ lọ.- The Ministry of Healing, p.149. IIO 59.3