Go to full page →

Nígbà Tí Ilé- Ìwé Bá Wà Ní Àkókò Ìsinmi. IIO 65

Nígbà tí ilé-ìwé bá parí, ààyè wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti lọ sí pápá gẹ́gẹ́ bí olùtàwé ajíhìnrere. Àwọn atàwé tí ó jẹ́ olódodo ń rí ara wọn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé níbi tí wọn yóò ti fi ìwé kíkà sílẹ̀ tí ó kún fún òtítọ́ ọ ti àsìkò yìí.Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ wa gbọdọ̀ kọ́ bí a ṣe ń ta àwọn ìwé.A nílò àwọn ènìyàn tí wọ́n jinlẹ̀ nínú ìrírí ìgbàgbọ́, ènìyàn tí ọkàn an rẹ̀ ṣe deédé,lágbára, àwọn eniyan tí ó kẹ́kọ̀ọ́ dáradára láti kópa nínú ẹ̀ka ti iṣẹ́ yìí. Díẹ̀ ló ní ẹ̀bùn, ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ tí yóò lè mú wọn kọ́ àwọn ọ̀dọ́ fún iṣẹ́ ìtàwé ní ọ̀nà tí yóò mú wọn ṣàṣeyọrí ju bí wọ́n ti ń se báyì í. Àwọn tí wọ́n bá ní ìrírí yìí ní iṣẹ́ pàtàkì láti ṣe nínú kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn.- Counsels to Teachers, pp.546,547. IIO 65.5