Go to full page →

Àwòkọ́ṣe Fún Ètò ṣíṣe ìjọ IIO 73

Ṣíṣe ètò ìjọ ní Jérúsálẹ́mù jẹ́ bí àwòkọ́ṣe fun eto àwọn ìjọ níbò míràn níbi tí àwọn òjíṣẹ́ ti òtítọ́ gbọdọ̀ jèrè ọkàn sínú ìhìnrere. Níkẹhìn nínú ìtàn ti ìjọ àkọ́kọ́, nígbà tí onírúurú ipa ti àgbáyé ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ onígbàgbọ́ ni wọ́n ti dá sílẹ̀ nínú àwọn ìjọ, kíkójọ ìjọ ni a sọ di pípé níwájú, kí a ba à lè mú ètò àti ìwà ní pípé rẹ̀ dúró. Ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan ni a gbà níyànjú láti ṣapá a rẹ̀ dáadáa, ẹnì kọ̀ọ̀kan ni ó sì ní láti lo àwọn ẹ̀bùn tí a fún un dáadáa. - The Acts of the Apostles, pp.91, 92. IIO 73.5