Go to full page →

Òdiwọ̀n- ọn Ti Ọlọ́run IIO 86

Òṣùwọ̀n ti ìwà a wa ni ó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́. Àwọn ańgẹ́lì ọ̀run ń díyelé iye tí ìwà à rẹ tó, wọ́n sì wádì í àwọn àìní ì rẹ, wọ́n sì ń gbé ẹjọ́ ọ̀ rẹ sí ọ̀dọ̀ Ọlọrun.- Review and Herald,April 2,1889. IIO 86.1

A yóò dúró ní ẹnìkọ̀ọ̀kan fún ṣíṣe kín-kin-ní ju ohun tí a lágbára láti ṣe.Oluwa ń wọn ìṣe dééédé ànfààní kánfààní fún iṣẹ́ ìsìn. Àwọn agbára tí a kò lò ni a ti gbé gbe sórí ìṣirò bí àwọn tí a túnṣe. Fún gbogbo ohun tí a lè dà nípa lílo àwọn tálẹ́ńtì lọ́nà tó dára,Ọlọrun yóò bí wá léèrè. A yóò dá wa lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó yẹ kí a ṣe, ṣùgbọ́n tí a kò ṣe láṣepé nítorí pé a kò lo agbára wa láti yin Ọlọrun lógo. Bí a kò tilẹ̀ sọ ẹ̀mí i wa nù, a máa mọ̀ ní ayérayé àyọrísí àwọn tálẹ́ńtì i wa tí a kò lò. Nítorí gbogbo ìmọ̀ àti agbára tí ó yẹ kí a jèrè tí a kò sì jèrè, ni yóò jẹ́ òfò ayérayé.- Christ’s Object Lessons, p.303. IIO 86.2