Go to full page →

Bí Kò Bá Ti Jẹ́ IIO 86

Tí ọ́mọ ogun Krístì kọ̀ọ̀kan bá ṣe ojúṣe e wọn, tí alóre orí odi Síónì kọ̀ọ̀kan bá ti fun ipè, ayé kì bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ yìí ṣáájú. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ náà ti ní ìfàsẹ́hìn fún ọ̀pọ̀ ọdún, nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti sùn, Èṣù ti jà wá lólè àwọn ànfààní.- Testimonies, vol.9, p.29. IIO 86.3

Ẹ jẹ́ kí a gba iṣẹ́ tí wọ́n yàn wá, kí a polongo iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí yóò sọ ọkàn ọkùnrin àti obìnrin jí sí ìmòye ti ewu u wọn. Tí ọ̀kọ̀ọ̀kan onírètí Bíbọ̀ ọ Jésù bá ṣe iṣẹ́ tí a gbé ka iwájú u rẹ̀, iye àwọn onígbàgbọ́ yóò ti pọ̀ju báyìí lọ. Ní gbogbo ìlú u ti Amẹ́ríkà àwọn kan wà tí a ti darí láti gbọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti gbọ́ran sí òfin Ọlọ́run.- Testimonies, vol.9, p.25. IIO 86.4

Kì bá jẹ́ pé àwọn ènìyàn an RẸ̀ ti gba èrò Ọlọ́run láàyè nípa jíjẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti àánú, Krístì ì bá ti padà wá s'áyé, à bá ti kí àwọn mímọ́ káàbọ̀ sí ìlú Ọlọ́run.- Testimonies, vol.6, p.450. IIO 86.5