Go to full page →

Fojúsí Adé Tí ó Lóòrìn IIO 108

A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí agara dá wa tàbi kí ọkàn-an wa dákú. Yóò jẹ́ àdánu ń lá ní ṣíṣé ẹ pàsí pààrọ̀ ògo tí ó ní ìfaradà fún ìdẹ̀ra, ìrọ̀rùn, àti ìgbádùn tàbí fún àwọn ìkẹ́bàjẹ́ ẹ ti ara. Ẹ̀bùn láti ọwọ́ Ọlọrun ń dúró de aṣẹ́gun. Kò sí ẹnìkan nínú u wa tí ó tọ́ sí; ó jẹ́ ohun tí a gbà pẹ̀lú ọpẹ́ láti ọ̀dọ̀ ọ RẸ̀. Ìyanu àti ológo ni ẹ̀bùn yìí yóò jẹ́, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a rántí pé “ìràwọ̀ kan yàtọ̀ sí ìràwọ́ nínú ògo”. Ṣùgbọ́n bí a ṣe rọ̀ wá láti gbìyànjú fún ìṣẹ́gun, ẹ jẹ́ kí áfojúsùn-un wa wà nínú agbára ti Jesu, fún adé tí ó lóòrìn pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀. “Àwọn tí ó mòye yóò má a tàn bí òfúrufú, àti àwọn tí wọ́n bá jèrè ọ̀pọ̀ sí òdodo bí àwọn ìràwọ̀ títí láí àti láí”.Review and Herald, Oct.25, 1881. IIO 108.4