Go to full page →

A Ti San Owó Iṣẹ́ Tí a Ṣe IIO 109

Nígbà tí Oluwa wa bá padà dé yóò wádì í gbogbo tálẹ́ńtì; yóò bèèrè èrè lórí àwọn ohun tí Ó fi sí ìkáwọ́ ọ wa. Nípa ìrẹ̀sílẹ̀ àti ìrora a RẸ̀, nípa ìgbé ayé e làálà á RẸ̀ àti ikú ẹ̀sín-in RẸ̀, Kristi ti san gbèsè iṣẹ́ tí gbogbo ẹni tí ó ti gba orúkọ ọ RẸ̀ tí ó sì jẹ́wọ́ láti jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹ RẸ̀.- Testimonies, vol.9, p.104. IIO 109.1

Ó jẹ́ ọ̀ràn-an-yàn tí ó jinlẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti ṣà ipá pẹ̀lú u gbogbo agbára fún iṣẹ́ ẹ ìjèrè àwọn ọkàn sí ọ̀dọ̀ ọ RẸ̀. “Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara a yín”. Ó wí pé “nítorí a ti rà yín pẹ̀lú iye kan”, nítorí náà ẹ yin Ọlọrun lógo pẹ̀lú ìgbé ayé ìsìn tí yóò jèrè àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ sí òdodo. A ti rà wá níye kan nípa ìgbé ayé e Kristi,-rà pé kí a lè dá ohun ti Ọlọrun padà fún-Un nínú iṣẹ́ ìsìn òdodo o RẸ̀. - Testimonies, vol.9, p.104. IIO 109.2

Ọlọrun ti fún mi ní iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn eniyan-an RẸ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tají, kí wọn tẹ́ àgọ́ ọ wọn kálẹ̀, kí wọn sì mú kí ẹkùn-un wọn gbòòrò. Ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, a ti rà yín ní iye kan, pé gbogbo ohun tí o ní tí o sì jẹ́ ni o ní láti lò láti fi ògo Ọlọrun àti fún rere àwọn ènìyàn-an rẹ. Kristi kú lórí àgbélébù ú láti gba aráyé là kúrò nínú ègbé sí ẹ̀ṣẹ̀. Ó ń bèèrè fún ìfọwọ́- so- wọ́- pọ̀ ọ̀ rẹ nínú iṣẹ́ yìí. O ní láti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ọ RẸ̀, pẹ̀lú ìtara, ìgbìyànjú láì ṣàárẹ̀, o ní láti wá àti láti gba àwọn tí ó sọnù là. Rántí pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ rẹ ló mú kí àgbélébù ú náà ṣe pàtàkì. Testimonies, vol.7, p.9. IIO 109.3

Awọn àtẹ̀lé e Kristi ni a ti rà padà fún iṣẹ́ ìsìn. Ó jẹ́ ìkọ́ni Olúwa a wa pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ jẹ́ àfojúsùn-ùn wa láyé. Kristi fúnrà a RẸ̀ ti jẹ́ òṣìṣẹ́ rí, àti sí gbogbo àwọn àtẹ̀lé e RẸ̀, ó fún wọn ní òfin ti iṣẹ́,- iṣẹ́ sí Ọlọrun àti sí ẹnìkejì i wọn....Òfin iṣẹ́ isin jẹ́ ohun tí ó so wa pọ̀ pẹ̀lú Ọlọrun àti ọmọnìkejì i wa.-Christ’s Object Lessons, p.326. IIO 109.4