Go to full page →

Tẹ̀ Síwájú IIO 110

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ewu ń dóti ìgbé ayé àwọn Kristẹni, iṣẹ́ sì nira fún wọn láti ṣe.Àfọkànrò o wa lè máa rí i pé ìparun tí ó súnmọ́ pẹ́kí pẹ́kí níwájú, àti ikú lẹ́hiǹ. Síbẹ̀ ohùn Ọlọrun ń sọ̀rọ̀ ketekete, tẹ̀ síwájú. Ẹ jẹ́ kí a gbọ́ran sí àṣe náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú u wa kò lujá òkùnkùn. Àwọn ìpenija tí ó n dí ìtẹ̀síwájú u wa lọ́wọ́ ni yóò yẹra fún ọkàn tí ó ń lọ́ tìkọ̀ tàbí ṣiyèméjì. Àwọn tí wọ́n fà sẹ́hìn nínú ìgbọràn títí tí kò ní sí àìní dánilójú kọ̀ọ̀kan yóò ṣe pòórá, tí kò ní sí ewu ìjákulẹ̀ tàbí ìbàkù, kì yóò ṣe ìgbọ́ràn láí láí. Ìgbàgbọ́ ń rí tayọ ìṣòro, ó sì sowọ́pọ̀ mọ́ ẹni àìrí,àní ẹni tí ó lè ṣe ohun gbogbo, nítorí náà kì yóò jogún ofo. Ìgbàgbọ́ ni dídì ọwọ́ ọ Kristi mú ní àsìkò o pàjáwìrì kọ̀ọ̀kan.-Gospel Workers, p.262. IIO 110.1