Jẹ́ kí àwọn ìwé di pínpín pẹ̀lú òye nínú àwọn ọkọ̀ ojú irin, ní àwọn òpópónà, nínú àwọn ọkọ̀ ojú omi àti nípasẹ̀ àpò ìwé (Lẹta).- Gospel Workers, p.353. IIO 150.4
Ní àsìkò yìí nínú ìrìn-àjò, àwọn ànfààní wà láti pàdé pẹ̀lú àwọn ọkunrin àti àwọn obinrin ti gbogbo lẹ́gbẹ́lẹ́gbẹ́, àti ọ̀pọ̀ láti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, jẹ́ èyí tí ó tóbi ju ti ìgbà ayé e ísírẹ́lì lọ. Àwọn òpópónà ìrìn-àjò ti wà ní ìlọ́po lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Pẹ̀lú ìyanu ni Ọlọ́run fi fi ṣètò o ọ̀nà. Àwọn aṣojú ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé, pẹ̀lú oníruurú àwọn ohun èlò, ni wọ́n ti wà ní ìkáwọ́ o wa,.Bibeli àti àwọn ìwé àtẹ̀jáde ní onírúurú èdè ni a ti fi lélẹ̀ fún ọ̀títọ́ ọ ti àsìkò yìí, wà ní ọwọ́ ọ wa, ni a le è yára gbé kíákíá lọ sí gbogbo ayé.- Gospel Workers, p.352. IIO 150.5
Jẹ́ kí àwọn ìwé kékeré àti àwọn ìwé ìléwọ́, àwọn tákààdá àti àwọn ìwé lọ sí gbogbo ọ̀nà, gbé pẹ̀lu u rẹ̀, níbikíbi tí o bá ń lọ, ẹrù àwọn àṣàyàn ìwé ìléwọ́, tí ó le fi lé ènìyàn lọ́wọ́ tí o bá ti ní ànfààní. Ta èyí tí o bá lè tà, kí o sì yá tàbí kí o fún wọn láti mú lọ bí ó bá ṣe gbà. Àyọrísí pàtàkì yóò sì tẹ̀lé e.- Review and Herald, June 10, 1880. IIO 151.1
A ti fi hàn mí pé a kò ṣe iṣẹ́ ẹ wa pẹ̀lú fífọ́n ká lọ́fẹ̀ ẹ́ àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa ké-kè-ké. Àwọn ọkàn tí wọ́n jẹ́ olóótọ́ wà tí wọn ì bá mú láti gba òtítọ́ yìí mọ́ra nípa ọ̀nà yìí nìkan…. Àwọn ìwé ìléwọ́ bíi ojú ewé mẹ́rin, mẹ́jọ, tàbí tí ó ní ojú ewé mẹ́rìndínlógún, ni a le è pèsè pẹ̀lú owó tí kò tó n ǹkan, láti ara owó tí a pa nípa ọrẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ní iṣẹ́ yì í lọ́kàn. Nígbà tí o bá kọ lẹ́tà sí ọ̀rẹ́, o le è fi ọ̀kan tàbí méjì sínú u rẹ̀ láì fi kún owó ìfìwé ránṣẹ́. Nígbà tí ó bá ṣe alábàápàdé ènìyàn nínú àwọn ọkọ̀, nínú ọkọ̀ ojú omi, ní orí ìtàgé, ẹni tí ó rò pé òun léti kí ó gbọ́, ó le è fi ìwé ìléwọ́ fún wọn.- Testimonies, vol.1, pp.551, 552. IIO 151.2