Go to full page →

Ṣíṣe Àkójọpọ̀ Àwọn Orúkọ IIO 151

Àwọn obìnrin lè ṣiṣẹ́ tí ó níye lorí nípa ṣíṣe àkójọpọ̀ orúkọ àwọn tí ó nífẹ́ ẹ́ sí ìwé àtìgbà- dé- gbà a wa, ní ọ̀nà yii, a le è mú ìmọ́lẹ̀ wá síwájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn.- Review and Herald, June 10, 1880. IIO 151.3

A ní ọ̀pọ̀ n ǹkan ń lá tí o lè rọ̀ wá lọ́rùn nípa títan òtítọ́ ká; ṣùgbọn àwọn ènìyàn-an wa kò dìde sí ànfààní tí a fún wọn. Ní ijọ́ kọ̀ọ̀kan wọn kò rí, wọn kò sì mọ ìdí láti lo agbára a wọn láti gba àwọn ọkàn là. Wọn kò náání iṣẹ́ ẹ wọn ní ṣíṣe àkójọpọ̀ orúkọ àwọn tí ó nífẹ̀ ẹ́ sí àwọn ìwé àtìgbà-dé-gbà a wa, pẹ̀lú awọn ìwé àpilẹ̀kọ ọ wa tí ó ní i ṣe pẹ̀lú ètò ìlera a wa, àti láti fi àwọn ìwé e wa àti àwọn ìwé kékeré e wa hàn.- Testimonies, vol.4, p.391 IIO 151.4