Go to full page →

Láì sojúsáájú IIO 241

Bí Olùgbàlà wa se gbé láarin àwon ènìyàn ó, ní ó sì bá àwon òtòsì pín nínú ìpín won. Ó mò pèlú ìrírí ìjìyà won. Gbogbo àwon tí ó níse pèlú ìrèlè ni ó dùn nínú, tí ó sì gbìyànjú. Gbogbo àwon tí ó mo ìtumò ìjìnlè èkó Rè kì yóò fìgbà kan lérò pé ìyapa tàbí ìpínyà gbọdò wà láarin olówó àti otòsì, pé a gbọdò bòwò fún olówó ju tálákà lo.-The Desire of Ages, p. 73. IIO 241.4

Nígbà tí ó bá kòyìn sí àwon tí ó dà bí enipé won kò ní ìlérí, tí wón sì fà móra, sé o mò pé ò ń se ìgbàgbé àwon okàn tí Olórun ń wá? Ní àkókò náà, tí o bá kòyìn, ó lè jé pé ìgbà náà ni won nílò àánú re. Ní gbogbo ìpéjo ìsìn, okàn pò tí ó ń wá ìsinmi àti àlàáfíà. Wón lè má gbé ìgbé ayé àìbìkítà, sùgbón won kò se aláìmò nípa Èmí Mímó. Òpòlopò won ni a lè gbà fún Kristi.- Christ’s Object Lesson. Ìpè sí ìhìnrere kìí se ohun tí ó fifún àwon ènìyàn díè tí a yàn, àwon tí a rò pé wón se wá lógo tí wón bá gba òrò nàá. — Christ’s Object Lessons, 191. IIO 241.5

A gbọdò fi òrò náà ránsé sí gbogbo ènìyàn. Níbikíbi tí okàn bá sí sílè láti gba òtító, Olúwa setán láti kó won. —The Desire of Ages, p. 194. IIO 242.1