Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ifẹ Ọlọrun si Enia

    Awọn ohun ti a da, ati Bibeli ti is̩e Ọ̀rọ Ọlọrun, awọn mejeji li o nsọ nipa titobi Ifẹ Ọlọrun. Baba wa ọrún ni orisun ìyè, ọgbọ́n, ati ayọ̀. Wo awọn ohun ti a da bi nwọn ti jẹ iyanu to, ati bi nwọn si ti lẹwà to. Ronu bi nwọn ti ba aini ati ayọ enia mu to ni ọna iyanu, ki is̩e ti enia nikan, s̩ugbọn ti ohun gbogbo ti o ni ẹ̀mi pẹlu. ltans̩an Õrun, ati òjò ti nmu ayọ̀ wa, ti o si nsọ oju ilẹ aiye di ọ̀tun, awọn oke, okun, ati pẹ̀tẹlẹ̀, gbogbo wọn lo nsọ fun wa nipa ti ifẹ Ẹlẹda. Ọlọrun ni Ẹniti o npese fun aini awọn ẹ̀da Rẹ̀ lojõjumọ. Olorin didun lsraeli ninu ọ̀rọ̀ didara rẹ̀ sọ wipe,IOK 7.1

    “Oju gbogbo enia nwò Ọ;
    Iwọ si fun wọn li onjẹ wọn li àkokò rẹ.
    Iwọ ẹi ọwọ Rẹ,
    Iwọ si tẹ ifẹ gbògbò ohun alãyè lọrun.” (Orin 145:15, 16.)
    IOK 7.2

    Li atetekọs̩e Ọlọrun da enia ni pipe, mimọ ati pẹlu ayọ aiye ti o lẹwa bi o ti ti ọwọ Ẹlẹda jade wá ko ni ami ibajẹ tabi òjíji ẹ̀gún—irú ofin Ọlọrun—ti is̩e ofin ifẹ—li o mu ègbé ati iku wá bã enia. Ani sibẹ nã ninu ijiya eyiti is̩e amuwa ẹs̩ẹ, a fi ifẹ Ọlọrun han si wa. A kọ ọ bayi pe, “Ọlọrun fi ilẹ bu nitori enia, (Genesisi 3:17.)IOK 7.3

    Ẹgun on os̩us̩u—is̩oro ati oris̩iris̩i idanwo ti o sọ igbeaiye enia di ti wahala ati ti aniyan li a ti yàn tẹlẹ fun rere rẹ̀, gẹgẹbi apakan ẹ̀kọ́ ti o yẹ fun u ninu ilana Ọlọrun fun igbesoke rẹ̀ kuro ninu iparun ati egbe ti ẹs̩ẹ mu wa. Bi o tilẹ jẹpe aiye ti subu nitotọ, sibẹ ki is̩e kiki ibanujẹ ati os̩i lo wà ninu rè. Ninu awọn ohun ti a da pãpã li a nri awọn is̩ẹ irans̩ẹ ti ireti ati itunu. Awọn òdòdó mbẹ lori awọn ẹgun os̩us̩u na, a si fi awọn itanna ẹlewà bo ẹgun nã mọlẹ.IOK 7.4

    “Ifẹ ni Ọlọrun” ni a ko sara awọn ewe ati ododo, ati awọn koriko tutu gbogbo. Awọn eiyẹ daradara ti nkorin ni oju orun awọn itanna ẹlẹwà ti o nfi õrun didun wọn kun inu afẹfẹ, awọn igi giga ninu igbo dudu pelu ewe ori wọn ti o tutu nini—gbogbo nkan wonyi li o njẹri nipa itọju Baba wa ọrun, ati bi On ti nfẹ lati fi ayọ kun ọkan awọn ọmọ Rẹ̀.IOK 7.5

    Bibeli li o nfi iwà Ọlọrun han. Ontikalãrá rẹ̀ si ti sọ nipa ifẹ ati ánu Rẹ̀ ainipẹkun. Nìgbati Mòse gbadúra pe, “Fi ogo Rẹ̀ han mi,” Oluwa dahún pe, “Emi o mu gbogbo õre Mi kọja niwaju rẹ,” Ekisodu 33:18, 19. Eyiyi ni ogo Rẹ̀. Oluwa rekọja niwaju Mose, On si ke pe, “Oluwa, Oluwa Ọlọrun, alánu ati Olõre-ọfẹ onipamọra ati ẹniti o pọ̀ li õre ati otitọ; ẹniti o npa ãnu mọ́ fun ẹgbẹgbē̩run, ti o ndari ais̩edẽde, ati ìrekọja ati ẹs̩ẹ ji.” Ekisodu 34:6, 7. O lọra ati binu, o si s̩eun pupo (Jona 4:2) Nitori on ni inudidun si ãnu. Mika 7:18.IOK 8.1

    Ọlọrun ti so ọkan wa pọ̀ mọ ara Rẹ̀, nipa awọn àmi ti ko niye l’aiye ati ọrun. Nipa awọn ohun ti a da, ninu isopọ ati ide ifẹ nipa ohun ti aiye yi ti ọkan enia lè mọ̀, li Ọlọrun ti wa ãye lati fi ara Rẹ̀ han fun wa. Sibẹsibẹ awọn nkan wọnyi kò lẽ fi ifẹ Rẹ̀ han ni kikun to. Bi o tilẹ jẹpe a ti fi gbogbo ẹri nwọnyi fun wa, Es̩u ti bu ifọju lu ọltan enia, tõbẹgẹ ti nwọn fi ngboju soke wo Ọlorun pẹlu ibẹ̀ru ; nwọn nro nipa Rẹ̀ bi onrorò ati alailèdarijini. Satani mu ki awọn enia mã ro nipa Ọlọrun bi ẹniti pataki iwà Rẹ̀ jẹ idajọ lile, — Onroro onidajọ, Onikanra, ati bi ẹniti a jẹ ni gbese ti ki si igbẹ̀bẹ̀. Satani nfi oju wo Ẹlẹda bi ẹniti nfi ìlara ati owu wa ẹs̩ẹ ati as̩is̩e awọn enia, ki on ba lè fi idajo bẹ wọn wo. Ọna ti a lè gbà latì mu ojiji okunkun buburu yi kuro li ọkàn awọn enia nilati fi ifẹ Ọlọrun ainipẹkun hàn fun araiye pe Jesu Kristi sọ̀kalẹ wa si aiye lati wá gbe lãrin awọn ọmọ enia.IOK 8.2

    Ọmọ Olọrun ti ọ̀run sọ̀kalẹ wa lati fi bi Baba ti ri hàn. “Ko si ẹniti o ri Ọlọrun ri ; Ọmọ bibi kans̩os̩o, ti mbẹ li õkan aya Baba, on na li o fi I hàn” Johannu 1:18. “Bẽni kò si ẹniti o mò Baba, bikose Omo, ati ẹnikẹni ti Ọmọ fẹ fi I hàn fun.” Matteu 11:27. Nigbati ọ̀kan ninu awọn omọ-ẹhin bere pe. “Fi Baba na hàn wa,” Jesu dahun wipe “Bi àkoko ti mo ba nyin gbé ti pẹ to yì. iwọ kò si ti imọ̀ mi sibẹ Filippi? Ẹniti o ba ti ri mi, o ti ri Baba: iwọ ti se wipe, “Fi Baba hàn wa”? Johannu 14:8. 9.IOK 8.3

    Nigbati Jesu nse apejuwe is̩ẹ Rè li aiye. O wipe, Oluwa ti fi àmi ororo yan mi lati wasu Ihinrere fun awọn òtosi; O ti ran mi lati se iwòsan ọkàn awọn oniròbinujẹ, lati wãsu idasile fun awon igbèkun, itunriran fun awọn afoju, ati lati jowọ awon ti a pa lara lọwọ. Luku 4:18. Eyiyi ni is̩ẹ Rè. O nlọ kakiri o si nse rere. o nse dida ara gbogbo awọn ti Es̩u npọn loju. Ọpọlọpọ ileto li o wa ti ko si ẹkun nitori aisan, nitoriti On ti kọja lọdọ wọn, O si ti mu awọn alaisan wọn larada. Is̩ẹ Rẹ̀ fìhàn gbangba pe, Ẹniti a fi àmi òrórò yàn latì ode ọrun wá ni is̩e. Ifẹ, ãnu, ati ibanikẹdun farahàn ninu is̩ẹ aiye Rẹ̀; ọkàn ãnu, ati ti ibanidaro Rẹ̀ hàn gbangba si gbogbo enia; O gbe àwọ enia wọ̀, ki on ba le mọ ami enia. Awọn ti o talaka julọ, ti o si rẹlẹ julọ ko bẹru lati sunmọ ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Pẹlupẹlu awọn ọmọde pãpã fi ayọ fàmọ ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Nwọn fẹràn ati mà gun cri èkun Rè, ati lati mã wo oju Rẹ̀ ti o kun fun ãnu, ti o si ntan ìmọlẹ ati ifẹ.IOK 8.4

    Jesu ko fi ọrọ otitọ Kankan pamọ, s̩ugbọn o nsọ wọn jade ninu ifẹ. O nlo imoye ti o ga julọ, pẹlu aniyan ati ifarabalẹ ti s̩e ti inurere, ninu gbogbo ibalo Rẹ̀ pẹlu awọn enia. Ko fi igbakan jẹ alaimoye, bẹni ko fi igbakan sọrọ lile kan lainidi tabi laiyẹ, bẹni ko mu irora ba ọkàn imoye nigbakan ri. 0n kò ba ailera enia wi. O nsọ otitọ pẹlu ifẹ. O kọ iwa agabagebe, aigbagbọ, ati ti ẹs̩ẹ silẹ; s̩ugbọn o nsọ ọrọ ibaniwi rẹ̀ jade pẹlu omije. O sọkun lori Jerusalẹmu, ilu ti o fẹran, ilu ti o kọ lati gba Ẹniti ise Ọna, ati Otitọ ati Iye. Nwọn ti kọ Ẹniti is̩e Olugbala, s̩ugbọn sibẹ oju ãnu Rẹ̀ wà lara wọn. Igbe aiye Rẹ̀ jẹ igbe aiye isẹra-ẹni ati ti ãjo fun itọju awọn ẹlomiran. Olukuluku ọkan li o jẹ yebiye loju Rẹ̀. Bi o tilẹ jẹpe ọlanla ogo ti ọrun mbẹ lara Rẹ̀, sibẹ O tẹ ara Rẹ̀ ba pelu olukuluku enia ti is̩e ti idile Ọlọrun. O ri ọkàn awọn ọmọ enia ti o ti s̩ubu sinu ẹs̩ẹ, o si ka si is̩ẹ igbeaiye Rẹ̀ lati gba wọn la.IOK 9.1

    Eyi ni iwà Kristi ti o farahàn ninu igbe aiye Rẹ̀. Eyi si ni iwà Ọlọrun. Lati inu ọkàn Baba ni ãnu ti ọ̀run ti s̩an jade bi omi, eyiti o fihàn ninu Kristi, ti o s̩an jade fun gbogbo omọ enia. Jesu Kristi alãnu Olugbala, On na ni Ọlọrun ti a “fihan ninu ara”. 1 Timoteu 3:16.IOK 9.2

    Jesu wa si aiye, O jiya, O si ku lati le gba wa la. O di “Ẹni ikãnu,” ki a le je alabapin ninu ayọ ainipẹkun. Ọlọrun fi aye silẹ fun Ọmọ Rẹ̀ ti o fẹran, ti o kun fun õre-ọfẹ ati otitọ lati fi aiye ti o kun fun ogo silẹ wa si aiye ti ẹs̩ẹ ti bajẹ, ti ojiji iku ati ifibu rẹ ti mu ki o s̩õkun O fi ãye fun U lati fi idi ifẹ ati iyin awọn angẹli silẹ, lati gba itiju, afojudi, irẹsile, ikorira ati iku. “Ina alafìa wa wa lara Rẹ̀, ati nipa ina Rẹ̀ li a fi mu wa larada.” Isaiah 53:5. Ẹ wo o ninu aginju, ni Getsemani ati lori agbelebú! Ọmọ Ọlọrun ti ko li abawọn yi gbe ẹru ẹs̩ẹ ru. On ti o ti jẹ ọkan pẹlu Ọlọrun mọ ipinya ti ẹs̩ẹ muwa si arin Ọlorun ati enia. Eyi mu ki iru ọro ikerora yi jade li ẹnu Rè. “Ọlọrun Mi, ẽs̩e ti Iwọ fi kọ Mi silẹ?” Matteu 27:46. Ẹru ẹs̩ẹ, ati riro nipa titobi rẹ̀ ati yiya ọkan kuro lọdọ Ọlọrun — awọn nwọnyi li o ba Ọmọ Ọlọrun li ọkan jẹ.IOK 9.3

    S̩ugbọn a ko s̩e irubọ nla yi lati le fi ifẹ enia si ọkan Baba tabi lati le fi ifẹ igba-ni-la si ọkan Rẹ̀. Bē̩kọ rara! “Ọlọrun fẹ araiye tobẹ gẹ, ti O fi Ọmọ bibi Rẹ̀ kan s̩os̩o funni.” Johannu 3:16. Ọlọrun fẹran wa, ki is̩e nitoripe On nwa ojurere wa, s̩ugbọn O fi ãye silẹ fun wa lati wa ojurere Rẹ̀ nitoriti O fẹ wa. Nipa Kristi nikan li O le tu ifẹ titobi Rẹ̀ sori aiye ti o ti s̩ubu sinu ẹs̩ẹ. “Ọlọrun wa ninu Kristi, O mba araiye laja sọdọ̀ ara Rẹ̀.” II Kọrinti 5:19. Ọlọrun ba Ọmọ Rẹ̀ jiya. Ninu irora ti Getsemane, ati ti iku ori agbelebu ni Kalfari, ọkàn Ọlọrun ti o kun fun ifẹ ti san iye owo iràpada wa.IOK 10.1

    Jesu wipe, “Nitorina ni Baba mi s̩e fẹran mi, nitoriti mo fi ẹmi mi lelẹ, ki emi ki o lè tun gba a.” Johannu 10:17. Itumọ eyi ni pe, “Baba mi fẹran nyin tobē̩gē̩, s̩ugbọn o tun fẹ mi si i, nitori ti mo fi ẹmi mi s̩e irapada fun nyin. Nipa fifi ara mi dipo nyin ati jijẹ onigbọwọ nyin, ni fifi ẹmi mi lelẹ ni gbigba gbese nyin ati ẹs̩ẹ nyin, mo wa di ẹni ayanfẹ julọ fun Baba mi : Nitori nipasẹ irubọ mi ni Ọlọrun Baba fi di alare, ati Oludare gbogbo ẹniti o ba gba Jesu Kristi gbọ.IOK 10.2

    Ọmọ Ọlọrun nikans̩os̩o li o le s̩e as̩epe is̩ẹ irapada wa, nitaripe on nikan ti o ti wà li õkan aiya Baba li o lè fi I hàn bi o ti ri. On nikan ti o mọ̀ giga, ati jinjin ifẹ Ọlọrun li o lè fi I hàn fun araiye. Ko si ohun miran ti o lè sọ asọye ifẹ Ọlọrun si enia ti o ti sọnu, bikos̩e irubọ titobi ti Jesu ti fi ara Rẹ̀ s̩e.IOK 10.3

    “Ọlọrun fẹ araiye tobē̩gẹ, ti o fi ọmọ bibi Rẹ̀ kans̩os̩o funni.” O fi I funni ki is̩e lati gbe lãrin ọmọ enia nikan, lati ru ẹs̩ẹ wọn, ati lati ku iku irubọ wọn, s̩ugbọn Ọlọrun fi I silẹ patapata fun iran ti o ti s̩ubu. Kristi nilati mọ anfani ati aini enia. Ẹniti o ti jẹ ọkans̩os̩o pẹlu Ọlọrun, si ti so ara Rẹ̀ pọ̀ mọ awọn ọmọ enia nipa isopọ ifẹ ti kò lè já lailai. Jesu ko tiju lati pe wọn ni “arakunrin.” Heb. 2:11. On ni Ẹbọ wa ati Alagbawi wa, Arakunrin wa, to gbe ẹran ara wa wọ̀ niwaju itẹ Baba Rẹ̀, ati titi aiye ainipẹkun O di ara kan pẹlu iran ti O ti rapada, — Ọmọ enia. Gbogbo eyi li a s̩e, ki a ba le gbe enia soke kuro ninu iparun ati ipò ibajẹ ẹs̩ẹ, ki on ba lè tan imọlẹ ifẹ Ọlọrun, ki o si lè di alabapin ayọ mimo.IOK 10.4

    Iye owo irapada wa ti a san, irubọ titobi ti Baba wa ọrun s̩e, nipa fifi ọmọ Rẹ̀ silẹ lati ku fun wa, ni lati fun wa ni ero ti o ga nipa nkan ti a le dà ninu Jesu Kristi. Gẹgẹbi Aposteli Johannu ẹniti o kun fun Ẹmi Mimọ ti fi oju ẹmi wo giga, jinjin, ati gbigboro ifẹ Ọlọrun si ẹ̀da ti ns̩egbe, o kun fun ẹmi iyin ati ti ibọlafun ; ati bi on kò ti ni èdè ti o yẹ to lati fi s̩e apejuwe titobi ati ãnu ifẹ Ọlọrun. O kigbe si aiye lati wo o. “Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa, ti a fi npè wa ni ọmọ Ọlọrun,” I Johannu 3:1. A! “Iru ipo iyì wo ni eyi ti a gbe enia si”! Nipa ẹs̩ẹ, awọn ọmọ enia ti sọ ara wọn di irans̩ẹ Satani. Nipa igbagbọ ninu Is̩etutu irubọ ti Kristi, awọn ọmọ Adamu tun le pada di ọmọ Ọlọrun. Nipa gbigbe àwọ̀ enia wọ̀ ni Kristi fi gbe enia soke. A gbe awọn enia ti o ti s̩ubu si ipo ti o pe, nipa dida ara pọ mọ Kristi, nwọn le yẹ fun orukọ na — “Ọmọ Ọlọrun”.IOK 10.5

    Iru ifẹ yi jẹ alailẹgbẹ. Ọmọ ọba ọrun! A! Ileri iyebiye! Kóko ọrọ as̩aro ti o jinlẹ! Ifẹ Ọlọrun ti kò lẹgbẹ lori aiye ti kò fẹràn Rẹ̀! Èrò yi ni agbara is̩ẹgun lori ọkan enia, a si di ero inu wa ni igbekun wá sinu ifẹ ti Ọlọrun. Bi a ba ti nkọ́ tó nipa iwà ọrun ninu imọlẹ agbelebu, bē̩ ni ao mã ri ãnu gba to, ati iyọ́nu, ati idariji ẹs̩ẹ ti o kun fun ẹtọ ati ododo, bẹli ao si ma ri awọn ẹri ifẹ ti o tobi ju ãnu ti iya ni fun alagbọran ọmọ lọ.IOK 12.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents