Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Jdagba soke ninu Kristi

    Iyipada ọkan ti o sọ wa di ọmọ Ọlọrun li a sọrọ nipa ninu Bibeli gẹgẹbi ìbí. A si tun fiwe idagba soke irugbin rere ti àgbe gbin. Li ona kanna pẹlu li awọn ti a s̩es̩ẹ yi lọkan pada si Kristi fi dabi “ọmọ ọwọ titun,” lati “dagba soke” (I Peteru 2:2; Efesu 4:15,) bi ọkunrin ati obinrin ninu Kristi Jesu. Tabi gẹgẹbi irugbin rere ti a gbìn sinu oko, nwọn nilati dagba soke ki nwọn si mu eso wá. Isaiah wipe a o mã “pè wọn ni ìgi ododo, ọ̀gbin Oluwa, ki a le yìn I logo.” Isaiah 61:3. A fà apē̩rẹ yọ lati inu ohun ẹ̀dá, ki otitọ ijinlẹ igbe aiye ti ẹ̀mí le yé wa.IOK 49.1

    Enia pẹlu gbogbo ọgbọn rẹ̀ ko le fi ẹ̀mí fun ohun ti o kere julọ ninu ẹ̀da. Nipasẹ ẹ̀mi ti Ọlọrun ba fifun igi tabi ẹ̀da-alãye nikàn s̩os̩o ni nwọn fi le wà lãyè. Nitorina nipasẹ iye lati ọdọ Ọlọrun li awọn enia fi le ni iye ti ẹmi ninu ọkan wọn. Afi bi a ba “tun enia bi lati oke wá.” (Johannu 3:3.) on kò le ni ipin ninu íye ti Kristi wa lati fifun aiye.IOK 49.2

    Bi ẹmi wa ti ri, bē̩ na ni o ri pẹlu idagbasoke. Ọlọrun “Ẹniti o nmu ki ẹka yọ ododo ti o si nmu ki itanna nã di eso, Nipa agbara Rẹ̀ li ohun ọ̀gbin fi ndagba, “ekini ẽhù, lẹhinnã ipẹ, lẹhinna ikunmọ ọka ninu ipẹ.” Marku 4:28.IOK 49.3

    Woli Hosea si sọ nipa lsraeli pe, “On o dagba bi eweko lili.” Nwọn o sọji bi ọkà, nwọn o si dàgba bi ajara.” Hosea 14:5, 7. Jesu si pas̩ẹ fun wa pe ki a “kiyesi awọn lili bi nwọn ti ndàgba.” Awọn igi ati itanna ki idagbà nipa ãjò tabi iyanju ara wọn, bikos̩e nipa gbigba ohun ti Ọlọrun ti pese silẹ fun itọju ẹ̀mi wọn. Ọmọde ko le fikun giga rẹ̀ nipa ãjõ tabi agbara rẹ̀. Bē̩ gẹgẹ li ẹnyin ná kò le ni iagbasoke nipa ti ẹ̀mi nipa ãjo tabi iyanju ara nyin. Igi ati ọmọde a mã dagba nipa gbigba onjẹ fun ẹ̀mi lọdọ awọn ohun ti o yi wọn ká, biafẹfẹ, õrùn ati onjẹ. Ohun ti awọn ẹbun ti èda wọnyi jasi fun eranko ati igi, ni Kristi jasi fun awọn ti o gbẹkẹle E. On ni “imole ainipẹkun” wọn, “õrùn ati asà wọn. Isa 60:19 ; Orin Dafidi 84:11. On yio dabi “ìri si Israeli.” “On o rọ̀ si ilẹ̀ bi òjo si ori koriko ìrẹmọlẹ.” Hosea 14:5: Orin 72:6. On li omi ìve, “ònjẹ Olọrun . . . . ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi iye fun araiye.” Johannu 6:33. Ninu ẹ̀bun Ọmọ Rẹ̀ ti kò lẹgbẹ, Ọlọrun fi õre-ọfẹ Rẹ̀ yi gbogbo aiye ká, gẹgẹbi o s̩e fi afẹfẹ ti a nmi yi aiye ka. Gbogbo awọn ti nwọn ba yan ati mí afẹfẹ õre-ọfẹ yi yio yè, nwọn o si di agba ọkunrin ati obinrin nmu Kristi.IOK 49.4

    Gẹgẹbi itanna ti má ngbe oju soke si õrùn ki didán imọlẹ rẹ̀ le mu ki o lẹ́wà si i, bē̩ gẹgẹ li awa pẹlu nilati gb’ oju soke si õrùn ododo, ki imọlẹ ọrun le tan si wa lara, ati ki ìwa wa le dabi iwa ti Kristi.IOK 50.1

    Nkan kannã ni Jesu kọ wa nigbati o sọ pe, Ẹ má gbe inu mi, emi o si mã gbe inu nyin. Gẹgẹbi ẹka ko ti le so eso fun ara rẹ, bikos̩epe o bá ngbé inu ajara; bē̩li ẹnyin, bikos̩epe ẹ ba ngbé inu mi. . . . Nitori ni yiya ara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le s̩e ohun kan.” Johannu 15:4, 5. Gẹgẹbi ẹka ti gbẹkẹle igi fun agbara idagbasoke ati lati so, bē̩ nã gãn li ẹ s̩e nilati gbẹkẹle Kristi ki ẹ to le gbe igbe aiye mimọ. Bi ẹ ko ba fi Tìrẹ s̩e, ẹ kò le ni iye rara. Ẹ ko ni agbara lati kọjuja si idanwọ rara tabi lati dagbasoke ninu õre-ọfẹ ati iwa mimọ. Bi ẹ ba ngbe inu Rẹ̀, ẹ le mã dagba. Bi ẹ ba ngba iye lọdọ Rẹ̀, ẹ kò ni gbẹ danu tabi jẹ aláileso. Ẹ o dabi igi ti a gbin si eti ipa odo.IOK 50.2

    Ọpọ enia ni mã nrò pe awọn nilati dá apákan is̩ẹ nã se. Nwọn gbẹkẹ wọn le Kristi fun idariji ẹ̀s̩ẹ, s̩ugbọn nisisiyi, nwọn nlepa nipa agbara wọn lati gbe igbe aiye otitọ, s̩ugbọn gbogbo iru iyanju bē̩ nilati kuna. Jesu sọ pe, “Ni yiya ara nyin kuro lọdọ mi, ẹ kò le s̩e ohun kan.” Idagbasoke wa ninu õre-ọfẹ, ayọ̀ wa, ati iwulo wa duro lori irẹpọ wa pẹlu Kristi. Nipa idapọ pẹlu Rẹ̀ ni ojõjumọ, ati ni wakati de wakati nipa gbigbe inu Rẹ̀ — li a lè fi dagba soke ninu õre-ọfẹ. On ki is̩e kìkì olupilẹs̩ẹ bikos̩e alaẹepe igbagbọ wa. Kristi li ẹni is̩ãju, ẹni ikẹhin ati eni nigbagbogbo. O nilati wà pẹlu wa ni ibẹrẹ, ipari ati ni gbogbo is̩is̩ẹ wa li ọna wa. Dafidi sọ pe, “Emi ti gbe Oluwa ka iwaju mi nigbagbogbo: nitori o wà li ọwọ òtun mi, a ki yio si s̩í mi ni ipò.” Órin Dafidi 16:8.IOK 50.3

    Iwọ ha bere pe, “Bawo ni mo se le mã gbe inu Kristi? Li ọna kannã ti o fi gbà A nis̩ãju ni. “Nitorina bi ẹnyin ti gbà Kristi Jesu Oluwa, bẹni ki ẹ mã rìn ninu Rẹ̀.” “Olododo yio yè nipa igbogbọ.” Kolose 2:6; Heberu 10:38. Iwọ fi ara re fun Ọlọrun, lati jẹ Tirẹ̀ patapata, lati sìn I ati lati gbọ Tirẹ̀, o si gbà Kristi gẹgẹbi Olugbala rẹ. O kò le s̩etutu fun ẹ̀s̩ẹ rẹ tabi ki o yi okàn re pada; s̩ugbọn lẹhin ti o ti fi ara rẹ fun U, Iwo gbagbọ pe O ti s̩e gbogbo nkan wonyi fun ọ nitori Kristi. Ò di ti Kristi nipa igbagbọ, nipa igbagbọ li o si nilati mã dagba ninu Rẹ̀ — nipa ifisilẹ ati gbigbà. O nilati fi gbogbo rẹ̀ silẹ-okan rẹ, ifẹ rẹ, is̩ẹ rẹ, si fi ara rẹ silẹ fun U lati pa gbogbo ofin Rẹ mọ́. O si nilati gbà gbogbo rẹ̀ — Kristi, ti is̩e ẹ̀kún ibukun gbogbo, lati mã gbé inu ọkán rẹ, lati jẹ agbara rẹ, ododo rẹ, oluranlọwọ rẹ ainipẹkun — lati fun ọ l’ agbara lati gbọran.IOK 50.4

    Yà ara rẹ si mimọ fun Ọlọrun lãrọ̀; fi eyi s̩e is̩ẹ rẹ akọkọ. Jẹki adura rẹ jẹ eyi pe, “Gbà mi s̩e Tirẹ̀ patapata, Oluwa. Mo gbé gbògbò awọn ilana mi kalẹ lẹsẹ Rẹ. Lò mi fun iẹẹ Rẹ lòni. Wa ba mi gbé ki o si jẹkinẹe gbògbò iẹẹ mi oni ninú Rẹ. Ọran òjõjúmọ li eyi. Má ya ara rẹ si mímọ fun Ọlọrún li árọ ọjọ kọkan. Fi gbògbò éro rẹ le E lọwọ lati muẹẹ tabi latikò silẹ gẹgẹbi O ba tifihan wa. Bayi ni iwọ lè má fi igbe aiye rẹ le Ọlọrún lọwọ lòjọjúmọ, bayi ni igbesi aíye rẹ yio si túbọ má dabi ti Kristi si i.IOK 51.1

    Igbe aiye ninu Kristi jẹ igbe aiye ifọkanbalẹ. Ó le má si ayọ̀-àyọ̀jù ninu ero wa, s̩ugbọn igbẹkẹle ti o kún fun alafia pipé nilati wà. Ireti kò si fun ọ ninu ara rẹ bikos̩e ninu Kristi. A so ailera tirẹ pọ̀ mọ agbara Rẹ̀, ailoye tirẹ pọ̀ mọ ọgbọ́n Tirẹ̀, ati agbara kukuru tirẹ pọ̀ mọ ipá Tirẹ ailopin. Nitorina iwọ ko nilati gbojule ara rẹ, tabi ki o jẹki ọkàn rẹ duro le ara, s̩ugbọn gboju soke si Kristi. Jẹki ọkàn rẹ mã rò nipa ifẹ́ Rẹ̀, ẹwà Rẹ̀, atu pipé ìwa Rẹ̀. Kristi ninu isẹ-ara-ẹni Rẹ̀, irẹsilẹ Rẹ̀, ninu iwa mimọ ati ododo Rẹ, ninu ifẹ Rẹ̀ ti kò lẹgbẹ—eyi nilati mã jẹ asaro ọkan wa. Nipa fifẹran Rẹ̀, s̩is̩e afarawe Rẹ̀, ati gbigbekele e patapata, ni a fi le s̩e ọ gẹgẹbi Rẹ̀.IOK 52.1

    Jesu wipe, “Mã gbé inu mi.” Awọn ọ̀rọ wọnyi fi èro isimi, iduro s̩ins̩in, ati igbẹkẹle hàn. Èwẹ, o si tun pe wa pe, “Ẹ wá sọdọ mi, . . . emi o si fun nyin ni isimi.” Matteu 11:28, 29. Awọn ọ̀rọ Olorin nã tun fi nkan kannã hàn: “Simi ninu Oluwa, ki o si fi sùru duro de.” Isaiah si funni ni idaniloju na pe, “Ninu dida-kẹjē̩ ati gbigbẹkẹlē̩ li agbara nyiri wà.” Orin Dafidi 37:7; Isa. 30:15. A ko le ri isimi yi nipa s̩is̩e imẹ́lẹ́; nitoripe ninu ipe Olugbala, O da ileri isimi pọ̀ mọ́ ìpè si is̩ẹ ni: “Ẹ gba ajaga mi si ọrun nyin, . . . ẹnyin o si ri isimi.” Matteu 11:29. Ọkàn ti o ba simi le Kristi patapata ni yio kun fun itara julọ ti yio si s̩is̩ẹ fun U julọ.IOK 52.2

    Nigbati ọkan enia ba gbojule ara rẹ̀, a mã yipada kuro lọdọ Kristi ti is̩e orisun ìye ati agbara. Nitorinã iyanju Satani igbagbogbo nilati dari èrọ enia kuro lọdọ Olugbala, a si dí ọkàn lọwọ lati dapọ pẹlu Kristi ati lati ba A gbe. Igbadun aiye, aniyan aiye, idãmu ati ibanujẹ, ẹ̀bi awọn ẹlomiran tabi ẹbi ati abuku ti ara rẹ̀—gbogbo iwọnyi ni Satani yio mã dari ọkan si. Mas̩e jẹki o fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ tàn ọ jẹ. On o mã mu ki ọpọlọpọ awọn ti nwọn fẹ se ti Ọlọrun nitõtọ ki o mã ro nipa ẹ̀bi ati ailera wọn, a si mã nireti ati s̩ẹgun nipa yiyà wọn kuro lọdọ Kristi. A kò nilati gbẹkẹle ara wa nikan ki a si mã bẹru pe bọya li ao fi gba wa là. Iru nkan wọnyi ni mà nyà ọkàn kuro lọdọ Orisun agbara wa. Fi ipamọ́ ọkan rẹ le Ọlọrun lọwọ, ki o si gbẹkẹle E. Mà sọ ki o si mã rò nipa Jesu. Jẹki ifẹ Rẹ̀ bori ifẹ tirẹ. Mu iyemeji kuro, ki o si le gbogbo ẹ̀ru rẹ lọ. Wi pẹlu Aposteli Paulu pe, “Mo wà lãyè; sibẹ ki is̩e emi mọ́, s̩ugbọn Kristi wà lãyè ninu mi: wíwà ti mo si wà lãyè ninu ara, mo wà lãyè ninu igbagbọ Ọmọ Ọlọrun, ẹniti o fẹ mi ti o si fi Òntikararẹ fun mi.” Galatia 2:20. Simi le Ọlọrun. On le s̩ọ́ ohun ti o ba fifun U. Bi iwọ ba fi ara rẹ le E lọwọ, On yio si mu ọ jade ani ju as̩ẹgun lọ nipasẹ Ẹniti o ti fẹran rẹ.IOK 52.3

    Nigbati Kristi gbe àwò ati iwà enia wọ̀ ara Rẹ̀, On fi okùn ifẹ so ara Rẹ̀ mọ́ enia, okùn ti agbara kan kò le já bikos̩e nipa ifẹ́ enia tikararẹ̀. Nigba pupọ ni Satani mã lo afẹ́ as̩eju lati mu wa já okun yi—ki a le yan lati yapa kuro lọdọ Kristi A nilati má s̩ọra nihin, ki a mà làkàkà, ki a si mã gbadura, ki o má bã si ohun ti yio tàn wa lati yan ọgá miràn. S̩ugbọn ẹ jẹki a gbe oju wa soke si Kristi, On yio si pa wa mọ́. Bi a ba nwo Jesu, a bọ́ lọwọ ewu. Ko si ohun ti o le já wa gbà kuro lọwọ Rẹ̀. Nipa titẹjumọ nigbagbogbo “a npawada si aworan kannã lati ogo dé ogo, ani bi lati ọdọ Oluwa ti is̩e Ẹmi.” 2 Kọrinti 3:18.IOK 53.1

    Bayi ni awọn ọmọ-ẹhin is̩ãju se mu aworan Olugbala wa ọwọn. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin wọnni gbọ́ ọrọ Jesu, nwọn mọ̀ pe awọn nilati ni I pẹlu wọn. Nwọn wa, nwọn ri I, nwọrt si tẹle E. Nwọn wà pẹlu Rẹ̀ ninu ile, nibi onjẹ, nibi ikọ̀kọ̀ adura, ati ninu pápá. Nwọn wà pẹlu Rẹ̀ gẹgẹbi awọn ọmọ ile-ẹkọ pẹlu olukọ wọn, nwọn ngbọ́ ọrọ otitọ mimọ li ẹnu Rẹ̀ lojojumọ. Nwọn a si mã wo oju Rẹ̀ gẹgẹbi awọn irans̩ẹ ti mã nwo oju ọga wọn, lati kọ is̩ẹ wọn. Awọn ọmọ-ẹhin wọnni jẹ “enia oniru iwa bi awa.” Jakọbu 5:17. Nwọn ni iru ogun kanna bi tiwa lati ba ẹs̩ẹ ja. Iru õre-ọfẹ ti awa nã si s̩e alaini ni awọn nã s̩e alaini, lati le gbe igbe aiye mimọ́.IOK 53.2

    Johannu pãpã, ti is̩e olufẹ ọmọ-ẹhin, ẹniti o tan imọlẹ irisi Olugbala ni kikun, kò ti ipa ẹ̀da ni ìwa rere. Ki is̩e kìkì pe o jẹ alátẹnumọ ati onilara ipo ọlá nikan, bikos̩e oninu fufu ati onibinu enia pẹlu. S̩ugbọn nigbati a fi iwa Ẹni Mimọ́ ni hàn a, o ri aìpé ti ara rẹ̀, ìmọ̀ eyi li o si sọ ọ di onirẹlẹ. Ipa ati sũru, agbara ati iwa pẹlẹ, ọlá-nla ati iwa tutu ti o ri ni igbe aiye Ọmọ Ọlọrun, fi ijọniloju ati ifẹ kun ọkàn rẹ̀. Li ojojumọ li ọkàn rẹ̀ nfà si Kristi si i, titi o fi gbagbe ero ti ara nitori ifẹ fun Óluwa rẹ̀. O fi iwa inu fùfu ati ilara pẹlu ibinu rẹ̀ fun Kristi lati tun u s̩e. Agbara atuns̩e ti Ẹmi Mimọ sọ ọkan rẹ di ọ̀tun. Agbara ifẹ ti Kristi li o yi iwa rẹ̀ pada. Ámuwa ti o daju ti irẹ́pọ pẹlu Jesu li eyi. Nigbati Kristi ba ngbé inu okàn, gbogbo iwa-abinibi ni imã yipada. Ifẹ Kristi ati Ẹmi Kristi a mà mu ọkàn rọ, a si mã s̩ẹgun rẹ̀, a si mã gbe ero ati ifẹ soke si Ọlọrun ati si orun.IOK 53.3

    Nigbati Kristi goke lọ si orun, loju awọn atẹle Rẹ̀ o dabi ẹnipe O si wà larin wọn. Wiwa larin wọn yi jẹ eyiti o kun fun ifẹ, Jesu, Olugbala, ti O ti ba wọn rin pọ̀, ti O ba wọn sọrọ pọ̀, ti O si ba wọn gbadura pọ̀, Ẹniti O ti sọrọ ireti ati itunu si ọkàn wọn, li a si ti gbà lọ si ọrun kuro lọwọ wọn, nigbati is̩ẹ irans̩ẹ alafia si wà li ete Rẹ̀ ti awọsanma si ti gbà A lọ, ohun Rẹ̀ tun pada tọ̀ wọn wa pe, “Ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye.” Matteu 28:20. Li awọ̀ enia li o goke lọ si ọrun. Nwọn mọ̀ pe O wà niwaju itẹ Ọlọrun, gẹgẹbi Ọ̀rẹ́, ati Òlugbala wọn sibẹ; pe iwa ibakẹdun Rẹ̀ ko yipada ; pe a si kã kun enia ti o njiya. O nfi itoye ẹjẹ Rẹ̀ iyebiye bẹ̀bẹ̀ niwaju Ọlọrun, o nfi ọgbẹ́ ọwọ́ ati ti ẹsẹ Rẹ̀ hàn, ni iranti iye ti O ti san fun awọn ẹni ìràpada Rẹ̀. Nwọn mọ̀ pe O ti goke lọ si ọrun lati lọ ipese ãye silẹ fun wọn, ati pe On yio si tun pada wa, lati wa mu wọn lọ si ọdọ Ontikararẹ̀.IOK 53.4

    Nigbati nwọn kojọpọ̀ lẹhin igoke re ọrun Rẹ̀, itara ni nwọn fi mu ẹ̀bẹ wọn lọ sọdọ Baba li orukọ Jesu. Ni ibẹru on iparọ́rọ́ ni nwọn fi tẹriba ninu adura, ti nwọn si ntun òrọ idaniloju ni sọ pe, “Ohunkohun ti ẹnyin ba bere lọwọ Baba li orukọ mi, On o fifun nyin. Titi di isisiyi ẹ ko ti ibere ohunkohun li orukọ mi: ẹ bere, ẹ o si rigbà, ki ayọ̀ nyin ki o le kun.” Johannu 16:23, 24. Nwọn gbe ọwọ igbagbọ soke loke pẹlu ílàye yi pe, “Kristi ti o ku, ki a sa kuku wipe ti a ti ji dide kuro ninu oku, Ẹniti o si wà li ọwọ ọtun Ọlọrun, ti o si nbẹbẹ fun wa.” Romu 8:34. Li ọjọ Pẹntikọsti ni Olutunu nã wa de, Ẹniti Kristi ti sọ nipa Rẹ̀ pe, On “yio si wà ninu nyin.” O si tun sọ siwaju pe, “Anfãni ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ; nitori bi emi ko bá lọ, 01utunu ki yio tọ nyin wá; s̩ugbọn bi emi ba lọ, emi o ran A si nyin.” Johannu 14:17; 16:7. Lati igbana lo, nipasẹ Ẹmi ni Kristi yio fi mã gbe inu ọkàn awon omo Rè nigbagbogbo. Irẹ́pọ̀ wọn pẹlu Rẹ̀ sunmọra nisisiyi ju ti igba ti O wà lọdọ wọn ninu ara lo. Imọ́lẹ̀ ati ifẹ. ati agbara ti Kristi ti ngbe inu wọn tàn jade ninu wọn, tobē̩ ti ẹnu yà awọn enia “ẹnu yà wọn ; nwon si woye wọn pe, nwọn a ti mã ba Jesu gbe.” Ise Apostelì 4:13.IOK 54.1

    Gbogbo ohun ti Jesu jẹ fun awọn omo-ehin is̩ãju, na li O si nfẹ lati je fun awọn ọmọ Rẹ̀ loni ; nitori ninu adura ti O gbà kẹhin pẹlu agbo awọn ọmọ-ẹhin kekere ti o yi I ká, O wipe, “Ki si ise kìkì awọn wonyi ni mo ngbadura fun. sigbọn fun awọn pẹlu ti yio gba mi gbọ́ nipa ọ̀rọ wọn.” Johannu 17:20.IOK 54.2

    Jesu gbadura fun wa, O si bẹ̀be pe ki a le jẹ okan pẹlu On, ani gẹgẹbi On pẹlu Baba ti jẹ ọkan. Isọkan nla ni eyi! Olugbala ti sọ nipa ara Rẹ̀ pe, “Ọmọ kõ le ẹe ohunkohun fun ara Rẹ̀.” “s̩ugbọn Baba ti ngbe inu mi, On ni ns̩e is̩ẹ́ Rẹ̀.” Johannu 5:19; 14:10. Njẹ bi Kristi ba ngbe inu ọkàn wa nigbana, On yio s̩is̩ẹ ninu wa “lati fẹ ati lati s̩is̩ẹ fun ifẹ́ inurere Rẹ̀.” Filipi 2:13. A o s̩is̩ẹ gẹgẹbi On s̩e s̩is̩ẹ ; a o si fi iru ẹ̀mi kannã hàn. ati nipa fifẹran Rẹ̀ ati gbigbe inu Rẹ̀ bayi, awa o “dagba soke ninu Rẹ̀ li ohun gbogbo, ẹniti ie ori, ani Kristi.” Efesu 4:15.IOK 54.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents