Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Jdanwo jijẹ Ọmọ Ẹhin Jotọ

    “Nitorina bi ẹninkẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹ̀dá titun : ohun atijọ ti kọja lo; kiyesi i, nwọn si di titun. II Kọrinti 5:17.IOK 42.1

    Enia lè má le sọ akoko gãn, tabi ibẹ gãn, tabi le sọ awọn ọna ti on gbà ni iyipada; sibẹ eyi ko fihàn pe a kò yi i pada. Kristi sofun Nikodemu pe, “Afẹfẹ nfẹ si ibiti o gbé wù u, iwọ si ngbọ́ iro rẹ̀, s̩ugbọn iwọ kò mọ̀ ibiti o gbe ti wa, ati ibiti o gbé nlọ: gẹgẹ bē̩ni olukuluku ẹniti a bi nipa ti Ẹmi.” Johannu 3:8. Gẹgẹbi afẹfẹ, ti a ko lè ri, s̩ugbọn ti a ri ti a si mọ̀ is̩ẹ rẹ kedere, li Ẹmi Ọlọrun jẹ ninu is̩ẹ rẹ lori ọkan enia. Agbara isọdọtun nã, ti oju enia kò lé ri, li o nmu igbe aiye titun wá sinu ọkan: o nda enia ni ọ̀tun gẹgẹbi iri Ọlọrun. Bi o tilẹ ti jẹpe is̩ẹ Ẹmi Mimọ jẹ is̩ẹ idakẹjẹ ti a ko si le ri, sibẹ a nri ayọrisi rẹ̀. Bi a ba ti tun sọ ọkan wa di mimọ nipa Ẹmi Mimọ Ọlọrun, igbesi aiye wa yio jẹri si otitọ yi. Bi a ko tilẹ le s̩e ohunkohun lati yi ọkan wa pada, tabi ki a mu ara wa wa ni idapọ pẹlu Ọlọrun ; bi a ko tilẹ le gbẹkẹle ara wa rárá tabi gbẹkẹle is̩ẹ rere wa, igbe aiye wa yio fihan bi ore-ọrẹ Ọlọrun ba ngbe inu wa. Iyipada yio wa ninu iwa, às̩a ati awọn ohun ti a nlepa. Iyatọ larin iwa wa atijọ ati ti isisiyi yio han kedere. Ki is̩e iwa rere diẹ ati iwa ibi diẹ li o nfi iwa ẹni han bikos̩e nipa ọrọ ati is̩e wa nigbagbogbo.IOK 42.2

    õtọ ni pe ihuwasi enia lode ara le dara laisi agbara isọni-dọtun ti Kristi. ifẹ fun agbara lori ẹlomiran ati ifẹ gbigbona fun igbega ti awọn ẹlomiran le mu igbe aiye ti o leto daradara wa. Ibu-ọla fun ra ẹni le mu ki a yago fun ohun ti o jọ ibi. Ẹniti imọ̀-ti-ara-ẹni nikan kun ọkan rẹ̀ nã le ma s̩e is̩ẹ ore pẹlu. Ọna wo ni ale fi mọ ẹgbẹ ti a wa nigbana?IOK 42.3

    Tali o ni ọkan? Ọdọ tali a dari awọn èro wa si? Tali a fẹran ati mã sọrọ nipa? Tali a fi ifẹ wa ti o gbona julọ fun, tali a si lo agbara wa ti o tobi julọ fun? Bi a ba jẹ ti Kristi ọdọ Rẹ̀ li èro wa yio dari si, awọn ero wa ti o si dun julọ yio jẹ nipa Rẹ̀. Ohun gbogbo ti a ni tabi je li ão si yá si mimọ fun U. A fẹ dabi Rẹ, ki a ni Ẹmi Rẹ̀, ki a s̩e ifẹ Rẹ, ki a si tẹ Ẹ lọrun ninu ohun gbogbo.IOK 42.4

    Awọn wọnni ti nwọn ba di ẹda titun ninu Kristi Jesu yio ma so eso ti Ẹmi, “Ifẹ, ayọ alafia, ipamọra, iwa pẹlẹ is̩õre, igbagbọ, iwa tutu, ikora-ẹni-nijanu.” Galatia 5:22, 23. Nwọn ko tun ni mã lo ara wọn gẹgẹbi ifẹkufẹ is̩ãju, s̩ugbọn nipa igbagbọ ọmọ Ọlọrun, nwọn o ma hu iwa Rẹ, nwọn o si ma ya ara wọn si mimọ, ani gẹgẹbi On ti mọ́. Awọn ohun tí nwọn ti korira tẹlẹ ri ni nwọn o si pada wa fẹran, ati ohun ti nwọn ti fẹran tẹlẹ ni nwọn yio korira. Awọn ti o ti jẹ onigberaga ati a-mọ-ti-ara-ẹni pada di oninututu ati onirẹlẹ ọkan. Were ati enia lasan si pada di onironu ati alailãpọn. Ọmuti pada di onis̩ọra, awọn alaimọ enia di ẹni mimọ́. Awọn às̩a ati íwa asan ti aiye si parapọ si apakan. Awọn onigbagbọ ko si ni wa “ọs̩ọ́ ode,” bikos̩e “ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọ̀s̩ọ́ aidibajẹ, ti ẹ̀mí irẹ̀lẹ ati ẹ̀mí tutu.” I Peteru 3:3, 4.IOK 43.1

    Koi ti si ẹ̀rí ironupiwada tõtọ́ titi yio fi mu iyipada wa. Bi ẹlẹ́s̩ẹ̀ ba dà ògò rẹ̀ pada, ti o da ohun na ti o ji pada, ti o jẹwọ awọn ẹs̩ẹ rẹ̀, ti o si fẹran Ọlọrun ati ọmọnikeji rẹ̀, o le wá ni idaniloju pe on ti ré iku kọja bọ sinu ìye.IOK 43.2

    Nigbati a ba tọ Kristi wa bi ẹlẹs̩e ti o ti s̩ako lọ, ti a si di alabapin õrẹ-ọfẹ idariji Rẹ̀, ifẹ yio dide ninu ọkan wa. Olukuluku ẹrù a si fuyẹ; nitoripe ajaga ti Kristi rọrùn. Is̩ẹ s̩is̩e di ayo, ifi ara rubọ si di igbadun. Ọna ti o ti dabi ẹnipe okunkun bò mọle pada di didan pẹlu imọlẹ õrùn ododo.IOK 43.3

    Didara iwa ti Kristi yio han ninu iwa ti awọn atẹle Rẹ̀. Ayọ̀ Rẹ̀ ni lati mã s̩ẹ ifẹ ti Ọlọrun. Ife si Ọlọrun fun itara ogo. Rẹ̀ jẹ ohun ti o gbe igbe-aiye Re duro. Ife li o fun awọn is̩ẹ Rẹ̀ li ẹwà ti o si mu wọn lọla. Ifẹ jẹ ti Ọlọrun. Ọkàn ti a ko ya si mimọ́ kò le ni i. Inu okàn ti Jesu ba gbe jọba nikan li a ti le ri i. “Awa fẹran Rẹ̀, nitori on li o kọ fẹran wa.” I Johannu 4:19, (Bibeli titun.) Ninúu ọkan ti Ọlọrun ba sọ di ọtun, ifẹ ni yio jẹ agbara rẹ̀. A mã tun iwa s̩e, a mã s̩e akoso èro, ati ifẹ gbigbona, a mã bori ikorira, a si mã ran wa lọwọ lati feran rere sise. Bi ifẹ yi ba wa li ọkan, yio mu igbe aiye dùn, yio si fi agbara rere fun awọn ti o wà yika.IOK 43.4

    As̩is̩e meji li awọn ọmọ Ọlọrun nilati s̩ọra fun ni pataki — pãpã awọn ti nwọn s̩ẽs̩ẹ̀ bere si ni igbẹkẹle ninu õre-ọfe Rẹ̀. Ekini ti nwon nse, ni igbekẹle is̩e ara wọn, to nwọn si ngbojule ohunkohun ti nwon le se lati mu ara wọn wà ni irẹpọ pẹlu Ọlọrun. Enikeni ti o ba ngbiyanyu lati di mimọ́ọ nipa is̩ẹ ara rẹ̀ ni pipa ofin Ọlọrun mọ́, o ngbiyanju lati s̩e ohun ti ko le s̩ẽs̩ẽ. Kìkì ohun ti enia le se laisi Kristi ni iwa imọ-ti-ara-ẹni ati ẹ̀s̩ẹ̀. õre-ọfẹ Kristi nikans̩os̩o li o le sọ wa di mimọ́ nipa igbagbọ.IOK 43.5

    Ekeji ti o si lewu bi as̩is̩e ti akọkọ ni pe igbẹ-kẹle igbagbọ ninu Kristi fun enia lãye lati mu oju kuro lara ofin Ọlọrun ni pipamọ; pe bi o ti jẹ pe nipa igbagbọ nikan li a fi di alabapin õre-ọfẹ Kristi, is̩ẹ wa ko ni ohun kan is̩ẹ pẹlu irapada wa.IOK 44.1

    Sugbọn ki ẹ s̩e akiyesi nihin pe igbọran ki iẹe kìkì pe ki a se is̩ẹ as̩e-han, s̩ugbọn is̩ẹ ifẹ. Ofin Ọlọrun jẹ apẹrẹ iwa Ré. Iwa Rẹ̀ si ni ifẹ, nitorina ifẹ ni ipilẹ ijọba Rẹ̀ 1’ ọrun ati I', a-iye. Bi a ba yi ọkan wa padà ti a si s̩e e li aworan Ọlọrun, ti a ba si gbin ifẹ ti ọrun sinu ọkan wa, a ki yio ha mu ofin Ọlọrun s̩ẹ ninu igbe aiye wa? Nigbati ifẹ ba gba ọkàn, nigbati a ba sọ enia di ọtun ti a si s̩e e gẹgẹbi Ẹniti o dá a, a o mu ileri yi s̩ẹ pe, “Emi o fi ofin mi si wọn li ọkàn, inu wọn li emi o si kọ wọn si.” Heberu 10:16.IOK 44.2

    Bi a ba si kọ ofin si ọkan, ki yio ha s̩e igbe aiye daradara? Igbọran — ti is̩e isin ifẹ on pẹlu ni is̩e àmi ìjẹ́-ọmọehin tõtọ. Iwe Mimọ sọ bayi pe, “Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin Rẹ̀ mọ.” Ẹniti o ba wipe, emi mọ Ọ, ti ko si pa ofin Rẹ̀ mọ, eke ni, otitọ ko si si ninu rẹ.” I Jọhannu 5:3; 2:4. Dípò ki o fa wa kuro lọna igbọran, igbagbọ, ani igbagbọ nikanẹs̩os̩o li o sọ wa di alabapin ninu ogo Kristi, eyiti o nmu wa s̩e igbọran.IOK 45.1

    A kò le ri igbala nipa igbọran wa ; nitoripe igbala jẹ ẹbun ọfẹ Ọlọrun ti a o fi igbagbọ gbà. S̩ugbọn igbọran jẹ eso igbagbọ. “Ẹnyin si mọ̀ pe On farahan lati mu ẹ̀s̩ẹ kuro ; ẹ̀s̩ẹ ko si si ninu Rẹ̀. Ẹnikẹni ti o ba ngbe inu Rẹ̀ ki idẹs̩ẹ̀: ẹnikẹni ti o ba ndẹ́s̩ẹ̀ kò ri I, bē̩ni kò si mọ̀ Ọ.” I Johannu 3:5, 6. Nihin ni idanwo tõtọ̀ gbe wà. Bi a ba ngbe inu Kristi, ti ifẹ. Ọlọrun si ngbe inu wa, ìmọ wa, ero wa ati awọn is̩e wa, yio wa ni idapọ pẹlu ifẹ Ọlọrun gẹgẹbi a ti fihan ninu ọrọ ofin Rẹ̀ mimọ. “Ẹnyin ọmọ mi, ẹ mas̩e jẹki ẹnikẹni ki o tan nyin: ẹniti o ba ns̩e ododo, o jasi olododo, gẹgẹbi On ti is̩e olododo.” I Johannu 3:7 Ofin mimọ mẹwa ti Ọlọrun ti a fifunni lori Oke Sinai ii o sọ ohun ti ododo jẹ.IOK 45.2

    Igbagbọ bē̩bē̩ ninu Kristi ti kò jẹki enia gbọran si Ọlọrun, ki is̩e igbagbọ bikos̩e ọ̀tẹ̀. “õre-ọfẹ li a fi gba nyin la nipa igbagbọ. S̩ugbọn “igbagbọ, bi ko ba ni is̩ẹ́, òkú ni ” Efesu 2:8; Jakọbu 2:17. Jesu sọ nipa Ontikararẹ̀ ki a to wa si aiye pe, “Inu mi dun lati s̩e ifẹ Rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ́ ofin Rẹ mbẹ li aiya mi.” Orin Dafidi 40:8. S̩ãju ki o to goke lọ si ọrun O tun sọ bayi pe, “Emi ti pa ofin Baba mi mọ́, mo si duro ninu ifẹ Rẹ̀.” Iwe Mimọ sọ pe, “Nipa eyi li a si mọ pe awa mọ̀ Ọ bi awa ba npa ofin Rẹ̀ mọ́ .... Ẹniti oba wipe on ngbe inu Rẹ̀, on nã pẹlu si yẹ lati mã rìn gẹgẹbi On ti rìn. I Johannu 2:3-6. “Nitori Kristi pẹlu jiya fun wa, O si fi apē̩rẹ silẹ fun wa, ki ẹnyin ki o le mã tọ ipasẹ Rẹ̀.” 1 Peteru 2:21.IOK 45.3

    Ipò ti iye ainipẹkun wà nisisiyi nã li o ti wà ri—ohun ti o ti jẹ ni Paradise s̩aju is̩ubu awọn obi wa àkọ́kọ́,—igbọran pipé si ofin Ọlọrun, ati ododo pipé. Bi o ba jẹ pe a gbe ìye ailopin ka ori ohun miran ti o rẹlẹ̀ ju eyi lọ, ayọ̀ gbogbo ẹ̀dá ni ìbá wà ninu ewu. Ọna ìbá s̩i silẹ fun ẹ̀s̩ẹ, ègbé ati òs̩i ti ntọ ọ lẹhin iba si mã wa titi lai.IOK 45.4

    O s̩ẽs̩e fun Adamu ki o to s̩ubu, lati kọ́ íwa ododo nipa igbọran si ofin Ọlọrun. S̩ugbọn o kùnà lati s̩e eyi, nitori ẹ̀s̩ẹ rẹ̀ yi ni is̩ẹda wa si fi bajẹ, ti a ko si le s̩e ara wa li olododo mọ. Bi a si ti jẹ ẹlẹs̩ẹ ati alaimọ́, a kò le gbọran si ofin mimọ nà ni pipé mọ́. Awa kò ni ododo ara wa ti a fi le s̩e ohun ti ofin Ọlọrun bẽre. S̩ugbọn Kristi ti s̩e ọna igbala silẹ fun wa. O gbe ãrin oris̩iris̩i is̩oro ati idanwo bi iru eyiti awa nã ni lati ba pade li aiye. O gbé igbe aiye ailẹ́s̩ẹ̀. O ku fun wa, O si nfẹ lati gba awọn ẹ̀s̩ẹ̀ wa nisisiyi ki o si fun wa ni ododo Tirẹ̀. Bi o ba fi ara rẹ fun U, ti o si gba a gẹgẹbi Olugbala nigbana bi o ti wù ki igbe aiye rẹ kun fun ẹ̀s̩ẹ to tẹlẹ, ao kà ọ si olododo nitori Rẹ̀. Iwa ti Kristi ni yio dopò ìwa rẹ, Ọlọrun yio si gbà ọ bi ẹniti kò dẹs̩ẹ.IOK 46.1

    Ju eyi lọ, Kristi a mã yi ọkàn padà. On ngbe inu ọkan rẹ nipa igbagbọ. O nilati pa isopọ pẹlu Kristi yi mọ nipa igbagbọ ati nipa jijọwọ ifẹ rẹ fun U nigbagbogbo ; niwọn igba ti o ba ns̩e eyi, On yio mã s̩is̩ẹ ninu rẹ lati fẹ ati lati s̩is̩ẹ fun ifẹ inu rere Rẹ̀. Nitorina o lé sọ bayi pe, “Wíwà ti mo si wà lãyè ninu ara, mo wà lãyè ninu igbagbọ Ọmọ Ọlọrun, Ẹniti o fẹ mi, ti o si fi ontikararẹ̀ fun mi.” Galatia 2:20. Nitorina ni Jesu s̩e wifun awọn ọmọ ẹhn Rẹ̀ pe, “Ki is̩e ẹnyin li o nsọ, s̩ugbọn Ẹmi Baba nyin ni nsọ ninu nyin.” Matteu 10:20. Nigbana, pẹlu Kristi ti ns̩is̩ẹ ninu nyin, ẹ o lè fi ẹmi Rẹ̀ kanna hàn, ẹ o si s̩e is̩ẹ Rẹ̀ — is̩ẹ ododo ati igbọran.IOK 46.2

    Nitorina ko si nkankan ti a le mã fọnnu le lori ninu awa tikarawa. Ko si ọna igbera-ẹni-ga kankan fun wa. Ọna ireti wa kans̩os̩o mbẹ ninu ododo Kristi ti a fifun wa, ati ninu eyi ti Ẹmi Rẹ̀ ti ns̩is̩ẹ ninu wa ati nipasẹ wa ba s̩e.IOK 46.3

    Nigbati a ba nsọrọ nipa igbagbọ, a nilati ranti pe iyatọ kan nbe ninu igbagbọ. Iru igbagbọ kan wa ti o yatọ si igbẹkẹle. Fun apẹrẹ, wiwà ati agbara, ati otitọ Ọrọ Rẹ̀ jẹ nkan ti Satani ati ogun rẹ̀ ko le jàníyàn li ọkan wọn pãpã. Bibeli wipe “awọn ẹmi es̩u nã gbagbọ, nwọn si wárìrì.” (Jakobu 2:19); s̩ugbọn eyi ki is̩e igbagbọ tõtọ́. Nibiti a ko ti ni kìkì igbẹkẹle ninu ọrọ Ọlọrun nikan s̩ugbọn ti a tun fi ifẹ wa fun U; nibiti a ba gbe fi ọkan ati ife ọkan nã fun U, nibe ni igbagbọ tõtọ́ wa—igbagbọ ti nfi ifẹ s̩is̩ẹ, ti o si nwe ọkan mọ́. Nipa igbagbọ yi, okàn a mã di mimọ ni aworan Ọlọrun. Okan ti ko ti le tẹriba fun ofin Olọrun tele ri, a si wa ni inu didun si ọ̀rọ rẹ̀, a si sọ pẹlu Olorin pe, “Emi ti fe ofin Rẹ̀ to. is̩àro mi ni li ọjọ gbogbo.” Orin Dafidi 119:97. A si mu ododo ti ofin s̩ẹ ninu wa “awọn ti ko rìn nipa ti ara, bikos̩e nipa ti Ẹmi.” Romu 8:1.IOK 46.4

    Awọn miran si wà ti nwọn ti mọ ifẹ idariji ti Kristi, ti nwọn si fẹ gãn lati jẹ ọmọ Ọlọrun, sibẹ nwọn mọ pe iwa wọn ko pe, igbe aiye wọn si kun fun ẹs̩ẹ, nwọn si ns̩iyemeji pe bọya Ẹmi Mimọ́ koi ti sọ ọkan wọn di ọ̀tun. Si iru awọn bē̩ ni mba sọ pe, Ẹ mas̩e fa sẹhin nitori ainireti : A nilati mã lo itẹriba ki a si mã sọkun lẹsẹ Jesu nigbagbogbo nitori ìkùna wa ati as̩is̩e wa ; s̩ugbọn a ko nilati sọ ireti nu tabi fòiyà. Ani bi ọta tilẹ bori wa, Ọlọrun kò ta wa nù, bē̩ni ko si gbagbe wa tabi kọ̀ wa silẹ. O tì o : Kristi wà li ọwọ ọtun Ọlọrun Ẹniti o si mbẹbẹ fun wa. Johanu olufẹ sọ pe, “Iwe nkan wọnyi ni mo kọ si nyin, ki ẹ má ba dẹ́s̩ẹ̀. Bi ẹnikẹni ba si dẹ́s̩ẹ̀, awa ni alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi olododo.” 1 Johannu 2:1. Ẹ má si se gbagbe ọrọ Kristi, “Baba tikararẹ fẹràn nyin.” Johannu 16:27. O nifẹ ati rà yin pada sọdọ Ontikararẹ̀, ki O le ri didan ìwa mimọ Rẹ̀ ninu nyin. Bi ẹnyin o ba si fi ara nyin fun U, On ti o ti bẹrẹ is̩e rere ninu nyin yio si s̩e e titi di ọjọ Jesu Kristi. Fi itara gbadura si i ; gbã gbọ ni kíkún si i. Bi a ko ba ti gbẹkẹle agbara ara wa, ẹ jẹki a gbẹkẹle agbara ti Olurapada wa, ao si mã yin “Ẹniti is̩e ilera oju wa.”IOK 47.1

    Gẹgẹbi ẹ ba ti nsunmọ Jesu to, bē̩ni ẹ o mã ro pe ẹ nhuwa aitọ li oju ara nyin to ; nitori oju nyin yio riran si i, ẹ o si ri i pe iwa tiyin yatọ lọpọlọpọ si iwa pipé Rẹ̀. Eyi jasi ẹri pe awọn itanjẹ Ès̩u ti sọ agbara wọn nù; ati pẹlu pe agbara Ẹmi Ọlọrun ti isọni di áyè li o nji nyin.IOK 47.2

    Ijinlẹ ifẹ fun Jesu ko le gbè inu ọkan ti ko ba mọ̀ ẹ̀s̩ẹ ara rẹ̀. Ọkan ti õre-ọfẹ Kristi ba ti yipada yio mã bu iyin fun iwa mimọ Rẹ̀ s̩ugbọn bi a kò ba ri iwa buburu ara wa, laisi ani-ani o jẹ ẹri pe a koi ti ri ẹwà ati tobi ti Kristi.IOK 47.3

    Bi a ba ti ns̩ai-s̩ogo ninu ara wa to, bē̩ni ao si mã gbe agbara mimọ nla ati Ifẹni Kristi ga to. Riri bi ẹs̩ẹ wa ti pọ̀ tó ni mã lé wa lọ sọdọ Ẹnikan nã ti O le darijini ; nigbati ọkan ti o mọ̀ ipo aini iranlowọ rẹ̀, ba si sa tọ Kristi lọ. On a si fi agbara ara Rẹ̀ han. Bi aini wa ba ti nle wa tọ̀ On ati ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lọ tó, bē̩li ao si mã fi oju giga wò ìwa Rẹ̀ to, bē̩ li ao si mã fi aworan Rẹ̀ hàn ni kikun tó.IOK 47.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents