Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ẹlẹs̩ẹ gbọdọ ni Kristi

    Li àtetekọse a fun ẹ̀da enia ni agbara ti o lọla, ati èro inu ti o yè kõro. O jẹ ẹ̀da ti o pé, o si wà ni irẹpọ̀ pẹlu Ọlọrun. Èro inu rẹ̀ jẹ mimọ, ireti rẹ̀ si jẹ mimọ pẹlu. Sugbọn nipa aigbọràn, agbara rẹ̀ di ibajẹ, imọ-tara-ẹni nikan si wá gba ipo ifẹ ninu ọkàn rẹ̀. Irekọja sọ ẹda rẹ di alailera tòbē̩gē̩ ti ko fi s̩es̩e fun u nipa agbara on fun ra rẹ̀ lati dojukọ agbara ẹni buburu ni. O di ẹrú fun Es̩u, bayi ni iba si wà titi lai bikòs̩epe Ọlọrun ba lọwọ si i. O jẹ ifẹ Es̩u lati ba ilana mimọ Ọlọrun fun ẹda enia jẹ, ki o si sọ aiye di ègbé ati ahoro. Ki o si le mã tọka si ibi yi gẹgẹbi àmuwa is̩ẹ Ọlọrun ni dida enia.IOK 13.1

    Nigbati enia wà ni ipo ailẹs̩ẹ, pẹlu ayọ̀ li o fi nba Ọlọrun lò pọ̀, “Inu ẹniti a ti fi gbogbo is̩ura ọgbọn ati ti imọ̀ pamọ si.” Kolose 2:3. S̩ugbọn lẹhin ti o ti dẹs̩ẹ tan, on kò tun ri ayọ iwà mimọ, o si wá ọna lati fi ara pamọ kuro niwaju Ọlọrun. Iru ipo yi ni ọkan ti a ko iti isọ di titun wà. Iru ọkan bē̩ kò si ni irẹpọ̀ pẹlu Ọlọrun, on kò si ri ayọ̀ ninu lilo pọ pẹlu rẹ̀. Inu ẹlẹsẹ kò le dùn niwaju Ọlọrun; on yio mã yẹra kuro ninu ẹgbẹ atẹle Rẹ̀ mimọ. Bi a tilẹ fun u li ãye lati wọ ọ̀run rere, ibẹ ko lè jẹ ibi ayọ̀ fun u. Ẹmi aimọtara ẹni ti njọba nibẹ, ọkàn ti ngbọ ti Kristi ati ti ifẹ Rẹ̀ ainipẹkun, kò lè fi ọwọ kan ọkàn ẹlẹs̩ẹ. Èro inu rẹ̀, aini rẹ̀, ati ero Rẹ̀ yio se ajeji si ẹniti nmu awọn ẹlẹs̩ẹ ibẹ s̩is̩ẹ. Ohùn tirẹ̀ yio yatọ ninu orin mimọ́ ti ẹ̀da ọrun nkọ. Ọrun yio jẹ ibi idaloro fun u, yio si fẹ ki a pa on mọ kuro li oju Ẹniti is̩e imọlẹ ati Olori ayọ̀ ibẹ. Ki ise ipinnu kan lasan lati ọdọ Ọlọrun li o ya ẹnibuburu nipa kuro ni Ijọba ọrun; aitọ ati aiye awọn tikara wọn ni o ti wọn kuro ninu ẹgbẹ mimọ Rẹ̀. Ogo Ọlọrun yio jẹ ajonirun ina fun wọn. Nwọn o ni ayọ fun iparun lati pa wọn mọ kuro l’ oju Ẹniti o ku lati ra wọn pada.IOK 13.2

    Ko s̩ẽs̩ẽ fun wa, nipa agbara ara wa lati lè yọ jade kuro ninu ọ̀gbun ẹs̩ẹ ti a ti bọ́ si. Ọkàn wa ti buru jayi, a kò si lè yi i pada. “Tani ẹniti o lè mu ohun mimọ jade lati inu aimọ? Ko si ẹnikan.” “Ero ti ara ọta ni si Ọlọrun: nitori ki itẹriba fun ofin Ọlọrun, on kò si lè s̩e e. Jobu 14:4; Romu 8:7. Ẹkọ ilaju, agbara ifẹ ọkàn, igbiyanju ẹda, lõtọ olukuluku wọn lo ni àye tirẹ̀, s̩ugbọn nihinyi nwọn jẹ alailagbara. Nwọn lè fi iwa pipe hàn lode ara ; s̩ugbọn nwọn kò lè yi ọkàn enia pada ; nwọn kò lè sọ orisun igbe aiye enia di mimọ. Agbara kan nilati wà ti ns̩is̩ẹ ninu ọkàn, ẹmi titun lati òké wá, ki a to le yi enia pada kuro ninu ẹs̩ẹ si inu iwà mimọ. Agbara nla yi ni Kristi. Õre-ọfẹ Rẹ̀ nikans̩os̩o li o lè mu ọkan ti ko lagbara sọji ti o si lè fa a si ọdọ Ọlọrun ati sinu ìwà mimọ. Olugbala wipe, “Bikobas̩epe a ba tun enia bi lati òkè wà”, afi bi on ba gba ọkàn titun, ifẹ titun, iwà titun, eyiti nsini lọ sinu igbe aiye titun, “on ko lè ri ijọba Ọlọrun.’ Johannu 3:3. Èro wipe ki a sa jẹki rere ti mbẹ ninu enia ma dagba nipa ẹ̀da rẹ̀ jẹ itanjẹ ti o lewu pupọju. “Enia nipa ti ara kò lè gba ohun ti ẹmi Ọlọrun: nitori wèrè ni nwọn jẹ fun u, bē̩ni on kò si lè mò wọn, nitoripe nipa ẹmi li a lè fi mọ̀ wọn.” “Ki ẹnu ki o mas̩e yà ọ, nitori mo wi fun ọ pe a kò lè s̩e alaitun nyin bi.” I Kọrinti 2:14. Johannu 3:7. Nipa ti Kristi a kọ ọ bayi pe, “Ninu Rẹ̀ ni iye wà; iye na si ni imọlẹ araiye,” Òrukọ kans̩os̩o Na ti a fifun ni labẹ ọrun, nipasẹ eyiti a fi le gba wa la,” Johannu 1:4; Is̩e 4:12.IOK 13.3

    Kiki pe a nrò nipa ifẹ inurere Ọlọrun kò to, lati ri iwà õre Rẹ̀, iwà ãnu ati itọju Rẹ̀ bi Baba, ati pe ki a mã rò nipa iwà Rẹ̀ nikan, gbogbo wọnyi kò to. Kiki pe a mọ̀ nipa ọgbọn, ati ododo ti ofin Rẹ̀, pe a gbe e kalẹ̀ lori ipilẹ ifẹ aiyeraiye, kò to. Paul Aposteli ri gbogbo eyi nitorina ni o se wipe. “Mo gbà pe ofin dara.” Bẹni mimọ li ofin, Mimọ si li as̩ẹ, ati ododo, ati didara.” S̩ugbọn o tun fi kun ninu ikorò ọkan ati aini ireti, wipe “Ẹlẹran ara li emi ti a tà sabẹ ofin.” Romu 7:16; 12:24. Ongbẹ iwà mimọ ati òdodo ngbẹ ẹ, Kò si le de ipò giga yi, nitori on jẹ alailera nipa ẹ̀da, O si kigbe wipe, “Emi eni òs̩i! tani yio gbà mi lọwọ ara iku yi?” Romu. 7:24. Eyi ni igbe ti o ti nti ọkàn wuwo awọn enia goke lọ si ọrun n’ilẹ gbogbo, ati ni gbogbo igbà. Idahùn kans̩os̩o li o si mbẹ fun iru igbe yi, on na si nipe “Wo ọdọ agutan Ọlọrun, Ẹ̀niti o ko es̩ẹ aiye lọ.” Johannu 1:29.IOK 14.1

    Ọ̀pọ̀lọpò àmi ati apẹrẹ li Ẹmi Ọlọrun ti pese silẹ lati s̩e apejuwe otitọ yi, lati mu ki o hàn gbangba fun okàn ti o fé di ominira kuro lọwo ẹrù ẹbi ẹs̩ẹ. Lẹhin igbati Jakọbu ti dẹs̩ẹ tan, nipa titan Esau arakunrin rẹ̀ je. o sa jade kuro ni ile Baba rẹ̀, ẹrù ẹbi ẹs̩ẹ ti wọ̀ l’ ọrun. On nikan bi isansa ti a yà nipa kuro lọdo awon ọrẹ ati ojulumọ rè, ero ti o tobiju ti o si lekè gbogbo èro lọkàn rẹ̀ lakoko yi ni ibẹru pe, ẹs̩ẹ on ti ya on kuro lọdọ Ọlọrun, ati pe on ti di ẹni itanu ni ọrun. Ninu Ibinujẹ li o dubulẹ lori ilẹ̀ lasan kò si ẹnikan pẹlu rẹ̀, afi awọn oke to yi i ka, ati loke rẹ̀ awọsanmọ ti o kún fun awọn irawọ̀ didàn. Bi o ti sun, o ri iran imọlẹ didan kan ti o s̩ajeji, si kiyesi i lori pẹtẹlẹ ti o dubulẹ si ojiji àkàsọ ti o dabi eyiti o ti ilẹ lọ, si ẹnu ibode ọrun, lara akasọ yi ni awọn Angẹli Ọlọrun ngoke ti nwọn si nsọ̀kalẹ: on si gbọ ohùn mimọ kan lati oke wa ti o jẹ is̩ẹ irans̩ẹ iyanu ati ti ireti. Nipa bayi li a fi han fun Jakọbu ohun ti ọkan rẹ̀ ti s̩e alaini—ani Olugbala. Pẹlu ayọ ati ọpẹ́ li o ri ọ̀na nã ti a la silẹ ti ẹlẹs̩ẹ fi le pada si ipò irẹpọ pẹlu Ọlọrun.IOK 14.2

    Àkàsọ ti o ri ninu iran rẹ̀ yi na ni Jesu, Ẹniti is̩e ọna kanẹos̩o ti enia le gba de ọdọ Ọlọrun.IOK 15.1

    Eyi ni apẹrẹ ti Jesu tọka si nigbati o mba Nataniẹli sọ̀rọ nigbati o wipe, “Ẹnyin yio ri ọ̀run s̩i silẹ, awọn Angẹli Ọlọrun yio mã gòke nwọn o si mã sọ̀kalẹ sori Ọmọ enia.” Johannu 1 :51. Nipa ipẹhinda, enia ya ara rẹ kuro lọdọ Ọlọrun ; a ke aiye kuro lara ọrun. Ko si ibasọrọ ti o lè re ọgbun ti mbẹ lãrin aiye ati ọ̀run kọja. Sugbọn nipa Kristi a tun so aiye pọ̀ mọ ọrun. Nipa awọn itoye Rẹ̀ Kristi ti dí ọgbun na ti ẹs̩ẹ ti se, ki awọn Angeli ti ise irans̩ẹ ẹmi tun le mã ba enia sọrọ. Kristi tun so enia alailera ati alailagbara pọ̀ mọ Orisun agbara titobi Rẹ̀ ti ko nipẹkun.IOK 15.2

    Sugbọn lasan ni gbogbo àlá ti enia nlá nipa ilọsiwaju ara rẹ̀, lasan ni gbogbo ipa ti a nsà lati gbe ẹda enia soke, bi nwọn ba kọ Orisun ireti ati iranlọwọ kans̩os̩ ti o wa fun iran ti o ti s̩ubu na silẹ. “Gbogbo ẹbun rere ati ẹbun ti o pe” lati ọdọ Ọlọrun li o ti wá. Jakọbu 1:17. Kò si iwà rère kan lẹhin Rẹ̀. Kristi ni ọna kans̩os̩o na sọdọ Ọlọrun. O wipe, “Emi ni Ọna ati Otito, ati Iye ; kò si si ẹniti o lè wá sọdọ Baba bikos̩e nipasẹ Mi” Johannu 14:6.IOK 15.3

    Ọkan Ọlọrun ns̩e iyọ́nu lori awọn ọmọ Rẹ̀ ti o wà li aiye pẹlu ifẹ ti o lagbara ju iku lọ. Ọlọrun ti tu gbogbo ẹ̀bun ati gbogbo is̩ura ọrun jade fun wa, nipa fifun wa ni Ọmọ Rẹ̀ kans̩os̩o na Igbe aiye ti Olugbala, iku Rẹ̀, ati ẹ̀bẹ̀ Rẹ̀ fun wa, ijọsin ti awọn Angẹli, ẹ̀bẹ̀ ti Ẹmi Mimọ mbẹ fun wa, Baba wa ọ̀run li o ns̩e is̩ẹ wọnyi nipasẹ gbogbo wọn, idunnu ati ayọ ẹ̀da ọ̀run li o ns̩e is̩ẹ wọnyi fun igbala ọmọ araiye.IOK 15.4

    A! ẹ jẹki a ronu ki a si se àsàrò nipa irubọ iyanu ti a ti se fun wa! O yẹ ki a mo riri gbogbo wàhálà, ati ipá ti ọ̀run nsà lati pe as̩ako padà wa si ile Baba wa ọ̀run. Ero ti o lagbara, tabi as̩oju ti o lagbara ju wọnyi lọ ko si ; ère nla ti o wà fun is̩ẹ rere, ayọ̀ ọ̀run, ẹgbẹ awọn Angẹli ainiye, idapọ̀ ifẹ Baba ati ti Ọmọ, igbega ati ilọsiwaju gbogbo agbara wa titi aiye ailopin, ki iha s̩e awọn nkan nwọnyi li ero ati isiri ti nrọ ọkan wa lati fi ọkan ife s̩is̩ẹ fun Ẹlẹda ati Olurapada wa?IOK 15.5

    Li ọ̀na keji, idajọ Ọlọrun lori ẹs̩ẹ, ẹsan ti o daju ati iparun ikẹhin li a fihàn fun wa ninu ọ̀rọ Ọlọrun gẹgẹbi ikilọ ki a ba lè sa kuro ninu isin Satani.IOK 16.1

    Njẹ kò ha yẹ fun wa lati ka ãnu Ọlọrun si? Kilo s̩ẹku ti On iba tun s̩e fun wa? Ẹ jẹki a fi ara wa si ipo ti o tọ pẹlu Rẹ̀, Ẹniti o ti fi ifẹ iyanu fẹ wa. Ẹ jẹki a lakàkà ki èrè ipesesilẹ yi lè jẹ tiwa, ki a ba le pa wa larada si awòran Tirẹ, ki a ba lè tun fi wa sipò ibakẹgbẹ pẹlu awọn Angẹli ti ns̩e iransẹ ẹmi, ati sinu irẹpọ ati idapọ pẹlu Baba ati Ọmọ.IOK 16.2

    “Mo fọwọba Ifẹ Rẹ̀, Ifẹ ti o lagbara julọ
    Ti enia ti fọwọba ri:
    A! bi o ti fa ọkàn mi soke,
    Ti o si mu ọkàn mi ti o le yọ́!
    Mo gbe ẹru mi si ẹsẹ Rẹ̀.
    Mo si mọ ayọ ti ọrun,
    Gẹgebi o ti sọ sinu eti mi
    Ọ̀rọ̀ Ibukun ni, “Dariji!”
    IOK 16.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents