Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Jgbagbọ ati Jtẹwọgba

    Bi Ẹmi Mimọ Ọlọrun ti mu ki ẹri ọkan rẹ sọji, iwọ ri ibi ti o wa ninu agbara ẹs̩ẹ, idalẹbi ẹs̩ẹ ati ègbé ti o wà ninu rẹ; iwọ si wõ pẹlu ẹmi ikorira. A si dabi ẹnipe, ẹs̩ẹ ti yà ọ nipa kuro ni ọdọ Ọlọrun, ati bi ẹnipe iwọ wà ninu ide agbara Satani. Bi iwọ si ti ngbiyanju lati jà àjàbọ́ lọwọ rẹ̀ to, bē̩ni iwọ nmọ rírì ailera rẹ to. Awọn ero rẹ jẹ alaimọ́, ọkàn rẹ pãpã si jẹ alaimọ́. Iwọ si ri wipe igbe aiye rẹ ti kun fun iwa imọtara ẹni-nikan ati ẹs̩ẹ pẹlu. Iwọ nfẹ iwẹnumọ, iwọ si nfẹ idande. Kini iwọ ha le s̩e ti iwọ fi le ni idapọ pẹlu Ọlọrun, ki iwọ si dabi Rẹ̀?IOK 37.1

    Alafia ni iwọ ẹe alaini, — Alafia ati idariji Ọlọrun ati ifẹ ninu ọkan. Owo ko le rà a, imọ ko si le wã ri, bē̩ni ọgbọn ko le ni i; mas̩e lero pe o le ti ipa agbara rẹ ni i. S̩ugbọn Ọlọrun fifun ọ gẹgẹbi ẹbun “laini owo ati lai-diyele. Isaiah 55:1. S̩ugbọn tirẹ ni bi iwọ yio ba na ọwọ rẹ ki o si dii mu. Oluwa wipe,” . . . . bi ẹs̩ẹ nyin ba ri bi òdòdó, wọn o si fun bi ojo didi; bi nwọn pọn bi Àlãrí, nwọn o dabi irun agutan. Isaiah 1:18. “Emi o fi ọkan titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi yio si fi sinu nyin .... Esekieli 36:26.IOK 37.2

    Iwọ ti jẹwọ ẹs̩ẹ rẹ, si mu wọn kuro ninu ọkan rẹ. Iwọ ti pinu lati fi ara rẹ fun Ọlọrun. Nitorinã, tọ̀ Ọ lọ nisisiyi, ki o bere lọwọ Rẹ̀ pe ki O wẹ ẹs̩ẹ rẹ nù ki o si fun ọ ni ọkan titun. Lẹhinna, gbagbọ tọkantọkan wipe Ọlọrun ti s̩e nkan wọnyi fun ọ nitoripe o ti s̩e ileri. Eyi ni ẹkọ ti Jesu kọni nigbati o wa ninu aiye, pe ẹbun ti Ọlọrun s̩e ileri fun wa, a nilati gbagbọ pe a ti ri wọn gba, nwọn o si jẹ tiwa. Jesu mu awọn enia larada kuro ninu aisan wọn nigbati nwọn ba gbagbọ ninu agbara Rẹ̀ ; O ran wọn lọwọ ninu ohun ti nwọn le ri, bē̩ni o si nfun wọn ni agbara igbẹkẹle ninu on tikararẹ̀ nipa ohun ti nwọn ko le ri — eyiti o nmu wọn gbagbọ pe Jesu ni agbara lati dari ẹs̩ẹ jini. Eyiyi li o fihan gbangba nipa mimu ọkunrin alarun ẹgba larada ; “S̩ugbọn ki enyin ki o le mọ pe, Ọmọ enia ni agbara li aiye lati dari ẹs̩ẹ jini (o wifun alarun egbà na pe”) “Dide, si gbe akete rẹ, ki o si ma lọ ile rẹ.” Matteu 9:6. Bē̩ gẹgẹ pẹlu ni Johannu onihinrere sọrọ nipa awọn is̩ẹ iyanu Jesu pe “Sugbọn iwọnyi li a kọ ki ẹnyin ki o le gbagbọ pe, Jesu ni is̩e Kristi na, Ọmọ Ọlọrun ; ati ni gbigbagbọ, ki ẹnyin ki o le ni iye li orukọ Rẹ̀.” Johannu 20:31.IOK 37.3

    Gẹgẹbi apẹrẹ ọna ti Jesu gba mu awọn alaisan larada, a le ri ẹkọ kọ nipa gbigbagbọ ninu rẹ lati dari ẹs̩ẹ jinni. Wo itan alarun nì ni eti adagun Bethesda. Ko ni agbara, o di ọdun mejidinlogoji ti o ti lo ẹsẹ rẹ mọ. Sibẹ Jesu wifun pe “Dide, ki o si gbe akete rẹ ki o si ma rin.” Bọya ọkunrin alaisan na iba wipe “Oluwa, bi Iwọ ba le mu mi larada, emi yio gba ọrọ Rẹ gbọ.” S̩ugbọn bē̩kọ, o gba ọrọ Kristi gbọ, o gbagbọ pe a ti mu on larada, o si gbiyanju lẹsẹkanna, o fẹ lati rin, o si rin. O huwa gẹgẹbi ọrọ Kristi, Ọlọrun si fun ni agbara ti o yẹ fũn. A si mu larada.IOK 38.1

    Gẹgẹbi ti ọkunrin yi, iwọ jẹ ẹlẹs̩ẹ. Iwọ ko le ẹe àwòtán ẹs̩ẹ rẹ, iwọ ko le yi ọkan ara rẹ pada, bē̩ni iwọ ko le sọ ara rẹ di mimọ. S̩ugbọn Ọlọrun s̩e ileri lati s̩e eyi nipasẹ ẹjẹ Jesu Kristi. Iwọ gba ileri yi gbọ. Jẹwọ ẹs̩ẹ. rẹ, ki o si fi ara rẹ fun Ọlọrun. Iwọ ni ifẹ lati sin Ọlọrun. Bi iwọ ba s̩e eleyi, Ọlọrun yio mu ileri tirẹ na s̩ẹ fun ọ. Bi iwọ ba gba ileri na gbọ — ti iwọ ba gbagbọ pe a ti dariji ọ ati pe a si ti wẹ ọ mọ — Ọlọrun fi otitọ na han pe, a mu ọ larada, gẹgẹbi Jesu se mu ọkunrin alaisan nì ni agbara lati rin lẹhin ti o ti gbagbọ pe a mu on larada. Bē̩na ni yio ri fun ọ bi iwọ ba gbagbọ.IOK 38.2

    Iwo maẹe duro di igbati iwọ ro, s̩ugbọn wipe, Emi gbagbọ; otitọ ni, ki s̩e nitoripe mo mọ̀ ninu ara mi, s̩ugbọn nitoripe Ọlọrun ti s̩e ileri.IOK 38.3

    Jesu wipe, .... “Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ pe ẹ ti ri wọn gba ná, yio si ri bē̩ fun nyin.” Marku 11:24. - - _ Afi bi a ba gbadura gẹgẹbi ifẹ Olọrun. S̩ugbọn ifẹ Ọlọrun ni lati wẹ ẹ̀s̩ẹ wa nù, lati sọ wa di ọmọ Rẹ̀, ati lati mu wa gbé ìgbé aiye mimọ. Nitorina a le bere awọn ibukun wọnyi, ki a si gbagbọ pe a ti ri wọn gba, ki a si dupẹ lọwọ Ọlorun pe a ti ri wọn gbà. Anfáni wa ni nigbana lati to Jesu lo fun iwẹnumo ki a ba le duro niwaju ofin laini àbãwón tabi itiju ati ègàn. “Njẹ ẹbi ko si nsisiyi fun awọn ti o wa ninu Kristi Jesu, awọn ti ko rin nipa ti ara, bikose nipa ti ẹmi.” Romu 8:1.IOK 38.4

    Lati isisiyi lọ enyin ki s̩e ti ara nyin nitoripe a ti ra nvin ni iye kan. Niwòn bi ẹnyin ti mo pe, “a ko fi ohun ti idibajẹ rà nyin pada, bi fadaka tabi wura, kuro ninu iwa asan nyin, ti ẹnyin ti jogún lati ọdọ awọn Baba nyin. Bi kos̩e ẹjẹ iyebiye ti ọdọ-agutan ti ko li àbukù, ti ko si li àbãwọ́n, ani ẹjẹ Kristi.” I Peteru 1:18, 19. Nipa igbagbọ ninu Ọlọrun, Ẹmi Mimọ ti fi ọkan titun sinu nyin. Ẹnyin si dabi ọmọ ti a bi sinu idile Ọlọrun, On si fẹran nyin gẹgẹbi o ti fẹ Ọmọ Rẹ̀ kans̩os̩o.IOK 38.5

    Njẹ nisisiyi bi ẹyin ti fi ara nyin fun Jesu, ẹ mas̩e fa sẹhin mọ, ẹ maẹe ja ara nyin gba kuro lọwọ Rẹ̀, s̩ugbọn ki ẹ ma wi ni ojõjumọ pe “Ti Kristi ni emi is̩e, mo ti fi ara mi fũn.” Ki ẹnyin ko si bere lọwọ Rẹ̀ lati fun nyin ni Ẹmi Mimọ Rẹ̀, ki O si fi õre-ọfẹ Rẹ̀ pa nyin mọ. Bi o ti jẹ pe nipa fifi ara rẹ fun Ọlọrun, ati nipa gbigbã gbọ ni o fi le di Ọmọ Rẹ̀, bẹ gẹgẹ ni o nilati mã gbe inu Rẹ̀ pẹlu. Paulu Aposteli wipe, “Nitorina bi ẹnyin ti gba Kristi Jesu Oluwa, bē̩ni ki ẹ mã rin ninu Rẹ̀. Kolose 2:6.IOK 39.1

    Awọn ẹlomiran a ma ro wipe awọn nilati wà fun igbakan ná ninu idanwo ati pe nwọn nilati fihan fun Ọlọrun pe a ti yi wọn pada, ki nwọn to le gba ibukun Rẹ̀. S̩ugbọn nwọn tilẹ le gba ibukun nã nisisiyi. Nwọn nilati ni õre-ọfẹ Ọlọrun ati Ẹmi Mimọ Kristi lati le ran awọn ati ailera wọn lọwọ, bi bē̩kọ nwọn ko ni le kọju ija si ibi. Jesu ni ifẹ lati gba wa gẹgẹbi awa ti ri, tawa ti ailera wa, ailagbara wa ati ẹs̩ẹ wa. Awa le wa si iwaju Rẹ̀ pẹlu ẹs̩ẹ wa, iwa were wa ati ailera wa, ki a si s̩ubu si ẹs̩ẹ Rẹ̀ pẹlu emi ironupiwada ni ọkàn wa. O jẹ ogo fun u lati fi apa ife Rẹ̀ yi wa po, ati lati di ọgbẹ́ wa, ki o si wẹ wa mọ́ kuro ninu aimọ wa gbogbo.IOK 39.2

    Nihin yi ni ọpọlọpọ gbe nbàkù; nwọn ko gbagbọ pe Jesu ndariji awọn tikarawọn lẹnikõkan. Nwọn ko gba Ọlọrun gbọ gẹgẹbi ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Anfáni nla ni fun olukuluku awọn ti won ns̩e nkan wonni lati mọ wipe idariji wa lọfẹ fun olukuluku ẹs̩ẹ ti enia ba da.IOK 39.3

    Mu ero buburu ni kuro ni okan rẹ pe iwọ ko ni ipin ninu ileri Ọlọrun. Nwọn wà fun olukuluku elẹsẹ ti o ba ronupiwada. Kristi ti pese agbara ati õre-ọfe ti awọn angẹli Rẹ̀ Mimọ yio fifun olukuluku ọkan to ba gbagbọ. Ko si ẹniti es̩ẹ rẹ pọ tobē̩ ti ko le ri agbara, iwa mimo ati ododo ninu Jesu, ẹniti o ku fun wọn. Jesu ti s̩etan lati bo as̩ọ ẽri ẹs̩ẹ nì kuro, ki o si wọ̀ wọn ni as̩ọ ododo. On ko fẹ iku wọn bikos̩e iye.IOK 39.4

    Olorun ki huwa si wa gẹgẹbi awa enia ti nhuwa si ara wa. Ero ãnu, ero ifẹ ati ero ibanikedun ni ero Rẹ̀. O wipe, “Jẹki enia buburu kọ ona rẹ̀ silẹ, ki ẹlẹs̩ẹ ki o kọ ironu rẹ̀ silẹ, si jẹki o yipada si Oluwa, On o si s̩ãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi ji lọpọlọpọ.”IOK 39.5

    “Mo ti pa irekọja rẹ rẹ bi awọsanmọ s̩is̩u dudu, ati ẹs̩ẹ re bi ikũkũ ; yipada sọdọ mi, nitori mo ti ra o pada.” Isaiah 55:7; 44:22.IOK 40.1

    “Nitori emi ko ni inudidun si iku ẹniti o ku, ni Oluwa Ọlọrun wi, nitorina ẹ yi ara nyin pada ki ẹ si ye.” Esekiẹli 18:32. Es̩u setan nigbagbogbo lati gba igbẹkẹle idaniloju ileri Ọlọrun kuro ni ọkan nyin. Ifẹ rẹ̀ ni lati mu gbogbo ireti ati imọlẹ Ọlọrun kuro ni ọkan nyin, s̩ugbọn ẹnyin ko gbọdọ fun ni ãye lati s̩e eyi. Mas̩e fi eti si ohun Oludanwo nni, s̩ugbọn wipe, “Jesu ti ku ki emi ki o ba le ye. Jesu fẹran mi, ko si fẹ ki emi ki o s̩egbe. Emi ni Baba ti o kun fun ãnu ni ọrun ; bo ti jẹ wipe mo ti ba ifẹ Rẹ̀ jẹ, ti mo si ti gbe ibukun ti o fun mi danu, sibẹ, emi yio dide, emi yio si tọ Baba mi lọ, emi yio si wipe: “Baba emi ti dẹs̩ẹ si ọrun ati si iwaju rẹ, emi ko si yẹ ni ẹniti a ba ma pe ni ọmọ rẹ mọ, nitorina fi mi se gẹgẹbi ọkan ninu awọn alagbas̩e rẹ.” Itan na kọ nyin gẹgẹbi ao se gba awọn ti o s̩ako lọ pada. “S̩ugbọn nigbati o si wa ni okere, baba rẹ̀ ri, ãnu s̩é, o rọ mọ li ọrùn, o si fi ẹnu kõ li ẹnu.” Luku 15:18-20.IOK 40.2

    S̩ugbọn gẹgẹbi itan yi ti s̩eni ni ãnu to yi, ko le fihan ni kikun, iru iyọ́nú ti Baba wa ti mbẹ ni ọrun ni. Ọlọrun sọ lati ẹnu Woli Rẹ̀ wipe “Emi ti fi ifẹni aiyeraiye fẹ ọ, nitorina li emi ti s̩e pa ore-ọfe mọ fun ọ.” Jeremiah 31:3. Nigbati ẹlẹs̩ẹ na wa ni ọna jijin rere si ilu Baba rẹ, ti o nfi ohun ini rẹ̀ sòfò ni ilu ajeji, sibẹ ọkan Baba rẹ ko kuro ni ara rẹ̀; Ẹmi Ọlọrun si bẹrẹ si rọ ọ, o nfá lati pada wa sinu ife Baba rẹ̀.IOK 40.3

    Pẹlu gbogbo ileri iyebiye ti o wa ninu Bibeli fun nyin, iwọ ha le fi ãye silẹ fun iyemeji bi? Njẹ ẹ le gbagbọ wipe nigbati ẹlẹs̩ẹ kan ba fẹ ronupiwada, ti o fẹ kọ ẹs̩ẹ rẹ̀ silẹ, Ọlọrun a ma di ẹlẹs̩ẹ lọwọ lati wa si ẹsẹ Rẹ̀ pẹlu ọkan ironupiwada ?IOK 40.4

    Ẹ jẹki iru ero bē̩ kuro ni ọkan nyin. Ko si nkan ti o le pa okan lara ju wipe ki enia ma ro ero buburu bayi si Baba wa ti mbẹ li ọrun. Lõto o korira esẹ, sugbọn o fẹran ẹlẹs̩ẹ, o si fi ara rẹ fun nipa Jesu Kristi ki olukuluku ẹniti o ba fe, ba le ni iyẹ ati ijọba ti Ọlọrun ti o ni ibukun. Ko si ede ti o yẹ ti on iba lo lati fi s̩e apejuwe iru ifẹ nla ti Ọlọrun ni si wa. Nitori o sọ bayi pe, “Òbinrin ha le gbagbe ọmọ omu rẹ̀ bi, ti ki yio fi s̩e iyọnu si ọmọ inu rẹ̀? Lõtọ́ nwọn le gba- gbe, s̩ugbọn emi ki yio gbagbe rẹ.” Isaiah 49:15.IOK 40.5

    Ẹ gbe oju nyin soke, ẹnyin oniyemeji ti ẹru ki ye ba ; nitoripe Jesu wa lati bẹbẹ fun wa. Ẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ẹbun Ọmọ Rẹ̀ ọwọn, ki ẹ si mã bẹ̀bẹ̀ ki iku Rẹ ma bã ja si asan lori nyin. Ẹmi Ọlọrun nrọ nyin loni. Ẹ wa tọkantọkan si ọdọ Jesu, ki ẹ si sọ ibukun Rẹ̀ di ti nyin.IOK 41.1

    Gẹgẹbi ẹnyin ba ti nka awọn ileri wọnni, ki ẹnyin ki o ranti pe ifẹ ati ãnu Ọlọrun ti a ko le fi ẹnu sọ ni o nfihan fun nyin. Ọkan ifẹ Ọlorun alãye a mã fa si ẹlẹsẹ ninu ifẹ ati ãnu ti ko lopin. “Ninu ẹniti awa ni irapada nipa ẹjẹ Rẹ̀, idariji ẹs̩ẹ wa, gẹgẹbi ọrọ õre-ọfẹ Rẹ̀.” Efesu 1:7. Bē̩ni, ẹ sã gbagbọ pe Ọlọrun ni oluranlọwọ nyin. Ọlọrun fẹ ki aworan iwà Rẹ̀ wa ninu enia. Bi ẹnyin ba ti sunmọ ọdọ Rẹ̀ pẹlu ijẹwọ ati ironupiwada ẹs̩ẹ nyin, On yio si sunmọ nyin pẹlu ãnu ati idariji.IOK 41.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents