Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ISE ISIN ONIGBAGBO - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ṣíṣe Àtúnṣe Ìwà

    Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà wí pé wọ́n ní ìwọ̀n-tún-wọ̀n-sí, ó yẹ kí Ìjọ Onírètí Bíbọ̀ Jésù ó wà níwájú.—Gospel Workers, p. 384.IIO 218.4

    Lórí ọ̀rọ̀ ìwọ̀n-tún-wọ̀n-sí, ẹ dúró lórí ipò yín láì ṣiyèméjì. Kí ẹ sì dàbí àpata tí a kò leè ṣí nídìí.—Gospel Workers, p. 394.IIO 219.1

    Yàtọ̀ sí ti sísọ̀rọ̀ ní ìta gbangba, a ní iṣẹ́ láti ṣe lórí ìwọ̀n-tun-wọ̀n-sí. Ẹ jẹ́ kí a kọ àwọn ìpinlẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ wa sínú ìwé kékeré alaidilù kí a sì lò ó láti ta àwọn ènìyàn wa jí láti darapọ̀ mọ́ àwọn tí kò tíì mọ òtítọ́. Ìwọ̀nba àṣeyọrí tí a ní ninu iṣe iranṣẹ dá lórí ṣiṣé iṣẹ́ takuntakun pẹ̀lú sísé ara ẹni àti láti fi ara ẹni jìn. Olúwa nìkan mọ̀ wí pé a ò bá ti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ ìbá ṣe wí pé gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́, a rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Rẹ̀ tí a sì polongo òtítọ́ ti ìwọ̀n-tún-wọ́n-sí ní ọ̀nà tààrà.—Gospel Workers, p. 385. IIO 219.2

    Ọ̀rọ̀ ìwọ̀n-tún-wọ̀n-sí yìí ni ó yẹ kí gbogbo wa ó tìlẹ́hìn. Ìwà àìní ìwọ̀n-tún-wọ̀n-sí ń dàgbà, ìwà ìbàjẹ́ náà kò gbẹ́hìn, bẹ́ẹ̀ sì ni a nílò àwọn ìwé tí ó sọ̀rọ̀ nípa ètò ìlera. Ṣíṣe àmúlò àwọn ìwé wa wọ̀nyìí jẹ́ onígbọ̀wọ́ fún iṣẹ́ ìhìnrere èyí tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn láti lèè máa ka Bíbélì láti ní òye òtítọ́ náà. Ó yẹ kí a ṣe ìkìlọ̀ ewu ńlá tí ó wà nínú ìwà àìní ìwọ̀n-tún-wọ̀n-sí, gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi keje mọ́ ni ó gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀kọ́ kí wọ́n sì máa fi àwọn ìlànà ètò ìlera tí ó wà nínú àwọn ìwé wa wọ̀nyìí ṣe ìwà hù. Ju eléyìí lọ, ó yẹ kí wọ́n ó pín àwọn ìwé wọ̀nyìí ni gbogbo àdúgbò wọn.—The Southern Watchman, Nov. 20, 1902.IIO 219.3

    Ẹ jẹ́ kí wọ́n ó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti máa lo àwọn owó tí wọ́n fi ń mutí , mu sìgá, fún ìtura àwọn aláìsàn, àwọn aláìní àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́ kí wọn baà lè wúlò lẹ́hìn wá ọ̀la nínú ayé.—The Ministry of Healing, p. 211.IIO 219.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents