Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸTA—ÀKÓKÒ ÒKÙNKÙN TI ẸMÍ

    Apostoli Pọlu, ninu lẹta rẹ keji si awọn ara Tẹsalonika, sọ asọtẹlẹ nipa iyapa nla ti yoo yọri si idasilẹ agbara ijọ paadi. O sọ wipe ọjọ Kristi ki yoo de “ayafi ti iyapa ba kọkọ wá ná, ti a si fi ọkunrin ẹṣẹ ni han, ọmọ ègbé; ẹni ti o tako, ti o si gbe ara rẹ ga ju gbogbo ohun ti a n pe ni Ọlọrun lọ tabi ti a n jọsin; to bẹẹ ti o joko bi Ọlọrun ninu tẹmpili Ọlọrun, ti o n fi ara rẹ han pe Ọlọrun ni oun.” Siwaju si, apostoli naa ki awọn arakunrin rẹ nilọ wipe “ohun ijinlẹ ẹṣẹ naa ti n ṣiṣẹ na.” 2 Tesalonika 2:3, 4, 7. Ani lati igba ibẹrẹ yẹn o ri awọn aṣiṣe ti yoo pese ọna silẹ fun idagbasoke ijọ paadi bi wọn ti n wọ inu ijọ.ANN 19.1

    Diẹdiẹ, ni bonkẹlẹ ati ni idakẹjẹ ni akọkọ, o wa n fi ara rẹ han ni gbangba bi o ti n ni okun si ti o si n gba akoso ọkan awọn eniyan, “ohun ijinlẹ ẹṣẹ” n tẹsiwaju ninu iṣẹ itanjẹ ati isọrọ odi rẹ. Ni aifiyesi, awọn aṣa ibọriṣa wọ inu ijọ Kristẹni. Inunibini nla ti ijọ doju kọ labẹ ẹsin ibọriṣa ká ẹmi ibarẹ ati iwani-iṣọkan pẹlu aye lọwọ kò fun igba diẹ. Ṣugbon bi inunibini ti dawọ duro, ti ẹsin Kristẹni wo inu gbọngan ati aafin awọn ọba, o kọ irẹlẹ Kristi ati awọn apostoli silẹ, o si gbe igberaga ati aṣehan awọn alufa ati alaṣẹ ibọriṣa wọ; o fi ẹkọ ati aṣa eniyan rọpo aṣẹ Ọlọrun. Iyipada afẹnuṣe Constantine, ni ìbẹrẹ ọrundun kẹrin, fa ajọyọ nla; bayi ni aye ti a wọ ni aṣọ ododo, ṣe wọ inu ijọ. Bayi iṣẹ iwa ibajẹ yara dàgbà kánkán. Ẹsin ibọriṣa di aṣẹgun nigba ti o dabi ẹnipe a ṣẹgun rẹ. Ẹmi rẹ ni o n ṣe akoso ijọ. A mu ikọni, aṣa, ati igbagbọ rẹ wọ inu igbagbọ ati ijọsin awọn atẹle Kristi.ANN 19.2

    Ibarẹ yii laarin ẹsin ibọriṣa ati ẹsin Kristẹni ni o yọri si idagbasoke “ọkunrin ẹṣẹ” ti a sọtẹlẹ ninu asọtẹlẹ bi eyi ti o tako, ti o si gbe ara ga ju Ọlọrun lọ. Ilana nla ẹsin eke naa jẹ titayọ agbara Satani—ami agbara rẹ lati joko lori itẹ lati ṣe akoso gẹgẹ bi ifẹ rẹ.ANN 19.3

    Ni igba kan ri, Satani sa ipa lati ba Kristi dọrẹ. O wa si ọdọ Ọmọ Ọlọrun ninu aginju idanwo, o fi gbogbo ijọba aye yii ati ogo wọn han-An, o si ṣe ileri lati fi gbogbo wọn fun Un bi yoo ba gba ọmọ alade okunkun ni ọga. Kristi ba adanniwo yii wi, O si fi ipa le e kuro. Ṣugbọn Satani maa n ṣe aṣeyọri daradara bi o ba gbe iru idanwo kan naa wa si ọdọ eniyan. Ijọ wa ojurere ati atilẹyin awọn ẹni nla aye lati le ri ọla ati èrè aye; nigba ti o ti kọ Kristi silẹ, o rọrun fun lati ṣe igbọran si aṣoju Satani— alufa Romu.ANN 19.4

    Ọkan lara awọn ẹkọ ti o gbajugbaja ninu ẹsin Romu ni wipe popu ni olori ti a le fi oju ri ninu ijọ Kristi, ti a fun ni agbara lori awọn bisọbu ati alufa ni gbogbo aye. Siwaju si, a fun popu ni orukọ Ọlọrun gan. A n pe e ni “Oluwa Ọlọrun Popu”, a si sọ wipe ko le ṣe aṣiṣe. O n beere fun ijọsin gbogbo eniyan. Ohun kan naa ti Satani beere fun ni aginju idanwo naa ni o si n beere fun nipasẹ Ijọ Romu, ti ọpọ eniyan si ṣetan lati jọsin rẹ.ANN 19.5

    Ṣugbọn awọn ti wọn beru ti wọn si bu ọla fun Ọlọrun fọ esi si ìpe ọrun nija yii bi Kristi ṣe fesi fun ọta alarekereke naa: “Oluwa Ọlọrun rẹ nikan ni ki iwọ o fi ori balẹ fun, Oun nikan ṣoṣo si ni ki iwọ o sin.” Luku 4:8. Ọlọrun ko sọ ohun ti o jọ ọ ninu ọrọ Rẹ wipe Oun yan eniyan kankan lati jẹ olori ijọ. Ikoni wipe popu jẹ ọga patapata tako awọn ikọni Iwe Mimọ. Popu ko le ni agbara kankan lori ijọ Kristi ayafi eyi ti o ba fi ipa gbà.ANN 19.6

    Awọn ẹlẹsin Romu n tẹsiwaju lati fi ẹsun ẹkọ odi ati mimọọmọ yapa kuro ninu ijọ tootọ kan awọn Protestant. Ṣugbọn awọn gan an ni ẹsun yii ba mu. Awọn ni wọn gbe asia Kristi silẹ ti wọn yago kuro ninu “igbagbọ ti a fi lelẹ fun awọn eniyan mimọ ni igba kan ṣoṣo.” Juda 3.ANN 19.7

    Satani mọ daradara wipe Iwe Mimọ yoo ran awọn eniyan lọwọ lati da itanjẹ oun mọ yoo si jẹ ki wọn kọ oju ija si agbara oun. Ani ọrọ naa ni Olugbala araye lo lati doju kọ atako rẹ. Kristi lo apata otitọ ayeraye fun gbogbo ikọlu rẹ, ni wíwípé, “A ti kọwe rẹ.” O lo ọgbọn ati agbara ọrọ naa lati tako gbogbo imọran Satani. Ki Satani to le ni akoso lori eniyan, ki o si fi idi aṣẹ ijọ paadi ti ó fi ipa gba agbara mulẹ, o nilati jẹ ki wọn jẹ ope ninu Iwe Mimọ. Bibeli yoo gbe Ọlọrun ga, yoo si fi eniyan ẹlẹran ara si ipo rẹ; nitori idi eyi a nilati fi awọn otitọ mimọ inu rẹ pamọ ki a si tẹ wọn rì. Ijọ Romu lo iru iṣọwọronu yii. Fun ọpọlọpọ ọdun o jẹ ohun ti ko ba ofin mu lati pin Bibeli kaakiri. A kan an nipa fun awọn eniyan lati maṣe ka Bibeli tabi ni i ninu ile wọn, awọn alufa ati olori ijọ oniwakiwa si n tumọ awọn ikọni rẹ lati gbe èké wọn lẹsẹ. Bayi ni gbogbo eniyan ṣe fẹrẹ gba popu tan gẹgẹ bi aṣoju Ọlọrun lori ilẹ aye, ti a fun ni agbara lori ijọ ati ilu.ANN 19.8

    Nigba ti a ti mu ohun ti o n da irọ mọ kuro, Satani n ṣiṣẹ gẹgẹ bi ifẹ rẹ. Asọtẹlẹ kede wipe aṣẹ ijọ paadi yoo “rò lati yi akoko ati ofin pada.” Daniẹli 7:25. Ko lọra lati ṣe iṣẹ yii. Lati le jẹ ki awọn ti a jere lati inu ẹsin ibọriṣa o ri arọpo fun ijọsin ère, ati lati le jẹ ki ọpọ eniyan o gba ẹsin Kristẹni ni afẹnujẹ, a mu ijọsin ère ati ohun iranti wọ inu ẹsin Kristẹni ni diẹdiẹ. Lẹyin-ọrẹyin, aṣẹ ajọ gbogboogbo fi idi ilana ibọriṣa mulẹ. Lati le pari iṣẹ ailọwọ yii, Romu gbero lati yọ aṣẹ keji, eyi ti o ka ijọsin ere leewọ, kuro ninu ofin Ọlọrun, o si pin ofin kẹwa si meji lati le jẹ ki iye rẹ ó pé.ANN 20.1

    Ẹmi ifohunṣọkan pẹlu ẹsin ibọriṣa ṣi ọna silẹ siwaju si lati kọ aṣẹ Ọrun silẹ. Satani, nipa lilo awọn adari ijọ ti ko ni ifọkansin, fọwọ ba ofin kẹrin pẹlu, wọn si gbiyanju lati kọ ọjọ Isinmi igba atijọ ni silẹ, ọjọ ti Ọlọrun bukun ti O si ya si mimọ (Jẹnẹsisi 2:2, 3), o wa gbe ọjọ ti awọn abọriṣa n pamọ gẹgẹ bi “ọjọ mimọ oòrùn” dipo rẹ. A ko bẹrẹ iyipada yii ni gbangba. Ni ọgọrun ọdun akọkọ, gbogbo Kristẹni ni wọn n pa ọjọ Isinmi tootọ mọ. Wọn jowu fun ọla Ọlọrun, pẹlu igbagbọ wipe ofin Rẹ ko ṣe e parẹ, wọn fi itara pa ilana mimọ rẹ mọ. Ṣugbọn pẹlu ọgbọn àrékérekè nla Satani ṣiṣẹ lati mu erongba rẹ ṣẹ nipasẹ awọn aṣoju rẹ. Ki a baa le pe akiyesi awọn eniyan si ọjọ Sunde, a pe e ni ọjọ ajọyọ ni àyajọ ajinde Kristi. A ṣe eto isin ni ọjọ naa; sibẹ a si n wo o gẹgẹ bi ọjọ igbafẹ, ti awọn eniyan si n ya ọjọ Isinmi si mimọ.ANN 20.2

    Lati pese ọna silẹ fun iṣẹ ti o fẹ ṣe, saaju wiwa Kristi, Satani mu ki awọn Ju o di ẹru wuwo le ori ọjọ Isinmi pẹlu awọn ofin inira wọn, wọn jẹ ki o nira lati pa a mọ. Ni isinsinyii, o ko ẹgan ba a gẹgẹ bi aṣa awọn Ju nipa lilo anfani ọna ti o fi jẹ ki a fi han ni ọna ti ko tọ. Nigba ti awọn Kristẹni n pa ọjọ Sunde mọ gẹgẹ bi ọjọ ajọdun, o dari wọn lati yan ọjọ Isinmi gẹgẹ bi ọjọ awẹ, ọjọ ibanujẹ ati ọjọ ìkorò, lati le fi ikorira wọn si ẹsin awọn Ju han.ANN 20.3

    Ni ibẹẹrẹ ọrundun kẹrin, ọba Constantine pa aṣẹ ti o sọ ọjọ Sunde di ọjọ ajọyọ kaakiri ilẹ ijọba Romu. Awọn abọriṣa ninu ijọba rẹ n bọwọ fun ọjọ oorun, awọn Kristẹni si n bọwọ fun pẹlu; erongba ọba naa ni lati so awọn ohun ti wọn tako ara wọn ninu ẹsin ibọriṣa ati ẹsin Kristẹni pọ ṣe ọkan. Awọn biṣọbu ti wọn jẹ ọlọkanjuwa, ti wọn si n wa agbara ni wọn rọ ọ lati ṣe eyi, wọn rò ó wipe bi awọn Kristẹni ati awọn abọriṣa ba n pa ọjọ kan naa mọ, yoo mu ki awọn abọriṣa o gba ẹsin Kristẹni yoo si jẹ ki ogo ati agbara ijọ o pọ si. Ṣugbọn nigba ti a n jẹ ki awọn Kristẹni ti wọn bẹru Ọlọrun o ri ọjọ Sunde gẹgẹ bi ọjọ mimọ, wọn si n ri ọjọ Isinmi tootọ bi eyi ti o mọ si Oluwa, wọn si n ya a si mimọ ni igbọran si ofin kẹrin.ANN 20.4

    Atannijẹ nla naa koi tii pari iṣẹ rẹ. O pinu lati ko gbogbo Kristẹni si abẹ akoso rẹ, ki o lo agbara rẹ lori wọn nipasẹ aṣoju rẹ, alufa onigberaga ni, ti o n pe ara rẹ ni aṣoju Kristi. O ṣe aṣeyọri ninu ete rẹ nipasẹ awọn abọriṣa ti ko ni iyipada ọkan tan, awọn alufa ọlọkanjuwa, ati awọn ọmọ ijọ ti wọn fẹran aye. A pe awọn ipade igbimọ lati igba de igba nibi ti awọn ijoye ijọ lati gbogbo aye ti pejọ pọ. Ninu awọn ipade wọn, a n tẹ ọjọ Isinmi ti Ọlọrun funra Rẹ dá rì, nigba ti a si n gbe ọjọ Sunde ga. Bayi ni ọjọ ajọyọ awọn abọriṣa ṣe wa di ọjọ ti a n bu ọla fun gẹgẹ bi agbekalẹ Ọlọrun, a n pe ọjọ Isinmi ti inu Bibeli ni ami ẹsin Ju, a si n fi awọn ti wọn pa a mọ gegun.ANN 20.5

    Oluyapa nla naa ṣe aṣeyọri ni gbigbe ara rẹ ga “kọja gbogbo ohun ti a n pe ni Ọlọrun tabi ti a n jọsin.” 2 Tẹsalonika 2:4. O ni igboya lati yi ilana kan ṣoṣo ninu ofin Ọlọrun eyi ti o fi Ọlọrun otitọ ati alaaye han gbogbo eniyan ni kedere pada. A fi Ọlọrun han ninu ofin kẹrin gẹgẹ bi Ẹlẹda ọrun ati aye, eyi si ni o ya A sọtọ laarin awọn ọlọrun èké. A ya ọjọ keje sọtọ gẹgẹ bi ọjọ Isinmi fun eniyan ni ayajọ iṣẹ dida. A pète rẹ lati le jẹ ki Ọlọrun o wà ninu iyè eniyan nigba gbogbo gẹgẹ bi orisun ẹmi ati ohun ti o yẹ ki a bọwọ fun ti o si yẹ ki a maa jọsin. Satani n ṣe akitiyan lati yi eniyan pada kuro ninu igbọran wọn si Ọlọrun ati si ofin Rẹ; nitori naa o lo agbara rẹ ni ọna pataki lati tako ofin naa, eyi ti o tọka si Ọlọrun gẹgẹ bi Ẹlẹda.ANN 20.6

    Ni akoko yii awọn Protestant n sọ wipe ajinde Kristi ni ọjọ Sunde ni o sọ ọ di ọjọ Isinmi awọn Kristẹni. Ṣugbọn ko si ẹri lati inu Bibeli. Kristi tabi awọn apostoli Rẹ ko bu iru ọla yii fun ọjọ naa. Lilo ọjọ Sunde gẹgẹ bi aṣa Kristẹni ní ipilẹsẹ rẹ ninu “ohun ijinlẹ ẹṣẹ” ni (2 Tẹsalonika 2:7), eyi ti o ti bẹrẹ iṣẹ rẹ ani ni akoko Pọlu. Nibo ati nigbawo ni Oluwa sọ ijọ paadi yii di ọmọ? Iru alaye ti o munadoko wo ni a le ṣe fun iyipada ti Iwe Mimọ ko fi ọwọ si? Ni ọrundun kẹfa ijọ paadi ti fi ẹsẹ mulẹ daradara. Ibukojo agbara rẹ wa ninu ilu alaṣẹ ni, a si sọ wipe biṣọbu ni olori fun gbogbo ijọ patapata. Ẹsin ibọriṣa fi àyè silẹ fun ijọ paadi. Dragoni naa fun ẹranko naa ni “agbara rẹ, ati ibujoko rẹ, ati aṣẹ nla.” Ifihan 13:2. Bayi ni ifiyajẹni fun ọtalelẹgbẹfa (1260) ọdun lati ọwọ ijọ paadi ti a sọtẹlẹ ninu iwe Daniẹli ati Ifihan ṣe bẹrẹ. Daniẹli 7:25; Ifihan 13:5—7. A wa fi ipa mu awọn Kristẹni lati yan, boya lati kọ iṣotitọ wọn silẹ ki wọn si gba aṣa ati ijọsin ijọ paadi, tabi ki wọn lo igbesi aye wọn ninu ẹwọn tabi ki wọn padanu ẹmi wọn ninu ohun ìdánilóró, ninu ina, tabi pelu aaké abẹnilori. Ọrọ Jesu wa wa si imuṣẹ wipe: “Awọn obi, ati arakunrin, ati ará ati ọrẹ yoo si fi yin han; wọn o si mu ki wọn ṣe iku pa diẹ ninu yin. Gbogbo eniyan yoo si korira yin nitori orukọ Mi.” Luku 21:16, 17. Inunibini wa si ori awọn olootọ pẹlu ibinu gbigbona ti o ju ti tẹlẹ lọ, gbogbo aye si di oju ija nla. Fun ọpọlọpọ ọdun awọn ijọ Kristi ri aabo ninu ibi ìfarasin ati ibi ìhamọ. Woli naa wipe: “Obinrin naa salọ sinu aginju, nibi ti Ọlọrun ti pese aye silẹ fun, ki a le bọ ọ nibẹ fun ọtalelẹgbẹfa (1260) ọjọ.” Ifihan 12: 6.ANN 21.1

    Igoke Ijọ Romu si ipo agbara jẹ ibẹrẹ Àkókò Òkùnkùn. Bi agbara rẹ ti n pọ si, bẹẹ ni okunkun naa ṣe n dudu si. A gbe igbagbọ kuro ni ọdọ Kristi, ipilẹ tooto, si ọdọ popu ti Romu. Dipo ki wọn gbẹkẹle Ọmọ Ọlọrun fun idariji ẹṣẹ ati fun iye ainipẹkun, awọn eniyan n wo popu ati awọn alufa ati awọn aṣoju ti o fi aṣẹ fun. A kọ wọn wipe popu ni olubalaja wọn ni aye ati pe ko si ẹni ti o le de ọdọ Ọlọrun ayafi nipasẹ rẹ; ati wipe o duro ni ipo Ọlọrun si wọn, nitori naa, ki wọn ṣe igbọran si laiṣeyemeji. Iyapa kuro ninu agbekalẹ rẹ to ki a fi iya ti o lagbara julọ jẹ ara ati ọkan awọn ti wọn ba ṣẹ. Nipasẹ eyi ọkan awọn eniyan yi kuro ni ọdọ Ọlọrun wa si ọdọ awọn ika eniyan ti wọn ti ṣubu ti wọn si baku, ani si ọdọ ọmọ alade okunkun funra rẹ, ti o n lo agbara rẹ nipasẹ wọn. A fi ẹṣẹ han pẹlu aṣọ iwamimọ. Nigba ti a ba tẹ Iwe Mimọ rì, ti eniyan si n ri ara rẹ bi ẹni ti o ga julọ, ẹtan, itanjẹ, ati ẹṣẹ ti o buru julọ ni a o ri. Nipa gbigbe ofin ati aṣa eniyan soke, a ri iwa ibajẹ ti o saba maa n tẹle kikọ ofin Ọlọrun silẹ.ANN 21.2

    Akoko naa jẹ akoko ewu fun ijọ Kristi. Awọn olootọ ti n gbe ọpagun soke kere niye nitootọ. Bi o tilẹ jẹ wipe a ko fi otitọ silẹ laini olujẹri, sibẹ ni igba miran, a dabi ẹni pe èké ati ìgba asán gbọ yoo bori patapata, ati pe a o gba isin otitọ kuro ninu aye. Awọn eniyan gbagbe iyinrere, ṣugbọn a sọ afarawe ẹsin di pupọ, a wa di ẹru wuwo le awọn eniyan lori.ANN 21.3

    A kò kọ wọn lati wo popu gẹgẹ bi alagbawi nikan, ṣugbọn lati tun gbẹkẹle iṣẹ ara wọn fun imukuro ẹṣẹ. Irin ajo ẹsin, iṣẹ ironupiwada, ijọsin awọn ère, kíkọ ile ijọsin, ojúbọ, ati pẹpẹ, sisan owo nla si inu ijọ—awọn wọnyi ati ọpọlọpọ awọn ohun miran bẹẹ ni a fi n kọni lati ṣe lati lè tu ibinu Ọlọrun loju tabi lati le ri aanu Rẹ; a fi bi ẹnipe Ọlọrun dabi eniyan, ti n binu si ohun ti ko nilari, tabi ti a le fi ẹbun tabi iṣẹ ironupiwada tù lójú!ANN 21.4

    Laika iwa ẹṣẹ ti n gbilẹ kan si, ani laarin awọn adari Ijọ Romu, agbara rẹ n pọ si. Nigba ti ọrundun kẹjọ fẹrẹ ẹ pari, awọn atẹle popu sọ wipe lati akoko ibẹrẹ pẹpẹ ijọ ni awọn biṣọbu Romu ti ni agbara ẹmi ti wọn n lo nisinsinyii. Lati fi idi ọrọ yii mulẹ, a ni lati wa ọna ti yoo fi ni aṣẹ; baba irọ si fun wọn ni èyi kánkán. Awọn ajẹjẹ ẹsin ṣe ayederu iwe atijọ kan. A ri awọn aṣẹ igbimọ kan ti a ko gbọ ri, ti wọn fi aṣẹ popu lori gbogbo aye mulẹ lati ibẹrẹ wa. Ijọ ti o ti kọ otitọ silẹ si yára kánkán lati gba itanjẹ yii.ANN 21.5

    Ọkan awọn olootọ perete ti wọn n kọle le ori ipilẹ tootọ (1 Korinti 3:10, 11) poruuru, wọn si ri idiwọ bi pàǹtí ẹkọ èké ṣe di iṣẹ naa lọwọ. Bii awọn onkọle lori odi Jerusalẹmu ni àkókò Nehemaya, awọn miran ṣetan lati sọ wipe: “Agbara awọn ti n ru ẹrù dínkù, àlààa pupọ ni o wa, to bẹẹ ti awa ko fi le mọ odi naa.” Nehemaya 4:10. Agara dá wọn nitori ijakadi àtìgbàdégbà pẹlu inunibini, itanjẹ, ẹṣẹ, ati oniruuru idena ti Satani le pète lati fi di itẹsiwaju wọn lọwọ, ọkàn diẹ lara awọn onkọle ti wọn jẹ olootọ kaarẹ; wọn si yi pada kuro nibi ipilẹ tootọ nitori alaafia ati aabo fun dukia ati ẹmi wọn. Awọn miran kò rẹwẹsi nitori atako awọn ọta wọn, laiberu, wọn sọ pe: “Ẹ maṣe bẹru wọn: ẹ ranti Oluwa ti o tobi ti o si lẹru” (ẹsẹ 14); wọn si tẹsiwaju pẹlu iṣẹ naa, olukuluku pẹlu ida rẹ lẹgbẹẹ rẹ. Efesu 6:17.ANN 22.1

    Iru ẹmi ikorira ati atako si otitọ kan naa ni o n mi si awọn ọta Ọlọrun ni gbogbo igba, iru iṣọra ati iṣotitọ kan naa ni a n reti lati ọdọ awọn iranṣẹ Rẹ. Awọn ọrọ Kristi si awọn ọmọlẹyin Rẹ akoko si ni itumọ fun awọn atẹle Rẹ titi dé opin akoko: “Ohun ti Mo sọ fun yin ni Mo sọ fun gbogbo eniyan, Ẹ maa ṣọna.” Maku 13:37.ANN 22.2

    O dabi ẹnipe okunkun naa n gbilẹ si. Ijọsin ere tubọ n di gbajúgbajà si. A n tan abẹẹla niwaju awọn ère a si n gbadura si wọn. Awọn àṣà asán ti ko tọ gbilẹ kan. Igbagbọ ninu ohun asan n dari ọkan awọn eniyan to bẹẹ gẹẹ ti o fi dabi ẹnipe ko si aaye fun ironu mọ. Niwọn ìgbà tí awọn alufa ati biṣọbu funra wọn jẹ olufẹ faaji, onifẹkufẹ ara, ati oniwaibajẹ, o ni lati daniloju wipe awọn eniyan ti n wo wọn fun itọsọna yoo tẹri sinu aimọkan ati iwa ibajẹ.ANN 22.3

    Ijọ paadi tun gbe igbesẹ miran ninu iwa igberaga ni ọrundun kọkanla nigba ti Popu Gregory VII kede wipe Ijọ Romu wa ni ailabuku. Lara awọn ọrọ ti o sọ ni wipe ijọ ko ṣe aṣiṣe rí bẹẹni ko si le ṣe aṣiṣe, bi Iwe Mimọ ti sọ. Ṣugbọn ẹri Iwe Mimọ ko ba ọrọ yii mu. Alufa agberaga naa sọ wipe ohun ni agbara lati yọ awọn ọba loye, o tun sọ wipe ko si ẹnikẹni ti o le yi ọrọ ti oun ba sọ pada, ṣugbọn ẹtọ oun ni lati yi ipinu gbogbo awọn iyoku pada.ANN 22.4

    A ri apejuwe iwa ika ẹni ti o n sọ wipe oun ko le baku yii ni bi o ti ṣe si Henry IV, ọba Germany. A kede wipe a lé ọba yii kuro ninu ijọ ati pe a tun rọ ọ loye nitori ti o gbero lati ṣe aigbọran si aṣẹ popu. Ẹru ba a nigba ti awọn ijoye rẹ, awọn ti aṣẹ popu n ti lẹyin lati ṣọtẹ si, kọ ọ silẹ wọn si n dun kukulaja mọ; Henry ri wipe o ṣe pataki ki oun ba Romu laja. Pẹlu iyawo ati iranṣẹ rẹ kan ti o jẹ olootọ, o la oke Alps kọja ni akoko yinyin, ki o baa le rẹ ara rẹ silẹ niwaju popu. Nigba ti o de ile iṣọ, Gregory ti kuro nibẹ, o lọ si gbọngan ti o wa ni ita, laisi eṣọ rẹ nibẹ, ninu otutu yinyin, laibo ori ati laiwọ bata, pẹlu aṣọ kan lasan, o duro de aṣẹ lati pe e wá siwaju rẹ. À fi igba ti o duro nibẹ, pẹlu awẹ ti o n jẹwọ ẹṣẹ fun ọjọ mẹta, ni alufa naa tó gbà lati fun ni idariji. Pẹlupẹlu, o ṣe eyi lori wipe ọba naa a duro de aṣẹ popu ki o to le wọ aṣọ igunwa rẹ tabi lati lo aṣẹ ọba. Gregory ti inu rẹ dun pẹlu iṣẹgun yii, fọnnu wipe ojuṣe oun ni lati ṣe igberaga awọn ọba rọ.ANN 22.5

    Iyatọ ti pọ to laarin igberaga nla alufa yii ati iwapẹlẹ ati ọkan tutu Kristi ti O fi ara Rẹ han bi ẹni ti n bẹbẹ ni ẹnu ilẹkun ọkan eniyan lati wọle, ki Oun lè wọle lati mu ayọ ati alaafia wa, ti O tun kọ awọn ọmọ ẹyin Rẹ pe: “Ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu yin, ẹ jẹ ki o maa ṣe ọmọ ọdọ yin.” Matiu 20:27.ANN 22.6

    Awọn ọdun tí n yí lọ n ri bi aṣiṣe ti n pọ si loorekoore ninu awọn ikọni ti Romu n gbe sita. Ani ṣaaju ki a to fi idi ijọ paadi mulẹ a n fiyesi ikọni awọn alarojinlẹ ti wọn jẹ abọriṣa wọn sì n ni ipa ninu ijọ. Ọpọlọpọ ti wọn sọ wipe wọn ti yipada ni wọn si dirọ mọ igbagbọ ero abọriṣa wọn, kìí si i ṣe wipe wọn n tẹsiwaju lati kẹkọ rẹ nikan, ṣugbọn wọn tun n fi n kọ awọn miran gẹgẹ bi ọna lati fikun ipa wọn laarin awọn abọriṣa. Bayi ni awọn aṣiṣe nla ṣe wọ inu igbagbọ Kristẹni. Eyi ti o gbajugbaja ninu wọn ni igbagbọ wipe a bi eniyan pẹlu aiku ati wipe o mọ ohun ti o n ṣẹlẹ ninu ipo oku. Ikọni yii ni o jẹ ipilẹ lori eyi ti Romu gbe gbigbadura nipasẹ awọn eniyan mimọ ati ijọsin Maria Wundia le lori. Nibi ni ẹkọ èké nipa ijiya ayeraye fun awọn ti ko ronupiwada, eyi ti a tete mu wọ inu ikọni igbagbọ ijọ paadi ti jade wa.ANN 22.7

    Eyi pèsè ọna silẹ lati mu agbekalẹ ibọriṣa miran, eyi ti Romu pè ní ibi idaloro wọle, o si n lo o lati dẹruba ọgọọrọ awọn eniyan ti wọn jẹ alaimọkan ti wọn ṣetan lati gba ohunkohun gbọ. Ẹkọ eke yii kọni wipe ibi idaniloro kan wa, nibi ti awọn ọkan ti ko yẹ fun ijiya ainipẹkun ti n jiya fun ẹṣẹ wọn, nibẹ si ni a o ti gbà wọn si ọrun nigba ti a ba ti fọ wọn mọ kuro ninu àbawọn wọn.ANN 23.1

    Romu tun nilo irọ miran lati le jẹ ere lati ara ibẹru ati iwa ẹṣẹ awọn atẹle rẹ. Ikọni nipa ìgba ẹṣẹ laaye ni o ṣe iṣẹ eyi. A ṣe ileri imukuro ẹṣẹ patapata fun awọn ẹṣẹ atẹyinwa, ti isisinyii, ati ti ọjọ iwaju, pẹlu idasilẹ kuro ninu irora ati ijiya ti wọn mu wa fun gbogbo awọn ti yoo kopa ninu ogun alufa naa lati fikún ilẹ ijọba rẹ, lati fiya jẹ awọn ọta rẹ, tabi lati pa awọn ti wọn ba kọ aṣẹ ẹmi rẹ silẹ run. A tun kọ awọn eniyan wipe nipa sísan owó sinu ijọ wọn le gba ara wọn kuro lọwọ ẹṣẹ, ki wọn tun gba ọkan awọn ọrẹ wọn ti wọn ti kú ti wọn wà ninu ina idaniloro silẹ. Nipasẹ ọna yii ni Romu gba lati fi ọrọ kun inu ile iṣura rẹ ti o si ri ọna lati jẹ ki awọn ti wọn pe ara wọn ni aṣoju Ẹni ti ko ri ibi ti yoo gbe ori Rẹ le o gbe igbe aye ọrọ, ọla, ati ẹṣẹ.ANN 23.2

    Ilana Ounjẹ Alẹ Oluwa ti Iwe Mimọ gbekalẹ ni a fi irubọ mass ti ibọriṣa rọpo. Awọn alufa ijọ paadi n ro pe pẹlu ìkùnsínú wọn ti ko nitumọ, wọn le yi akara ati waini lasan pada di “ara ati ẹjẹ Kristi.” Pẹlu isọrọ odi agberaga wọn n sọ ọ nigbangba wipe wọn ni agbara lati da Ọlọrun, Ẹlẹda ohun gbogbo. Lori ijiya iku, a fẹ ki awọn Kristẹni o jẹwọ igbagbọ wọn ninu ẹkọ èké buburu ti n ri Ọrun fín yii. Ọpọlọpọ awọn ti wọn kọ ni a dáná sun.ANN 23.3

    Ni ọrundun kẹtala, a da ẹka ti o buru julọ ninu ijọ paadi silẹ—Àjọ ti n wàdí ohun ti eniyan gbagbọ. Ọmọ alade okunkun ṣiṣẹ pẹlu awọn olori ijọ paadi. Satani ati awọn angẹli rẹ dari ọkan awọn eniyan buburu ninu ipade ikọkọ wọn, nigbati angẹli Ọlọrun ti a ko ri duro laarin wọn, o n ṣe akọsilẹ ti o banilẹru nipa òfin ìkà wọn ti o si n kọ itan awọn iṣẹlẹ ti wọn buru ju ohun ti oju eniyan le ri lọ silẹ. “Babiloni nla naa mu ẹjẹ awọn eniyan mimọ yó.” Ara ẹgbẹẹgbeje awọn ajẹriku ti a pa n kigbe si Ọlọrun fun igbẹsan lori agbara apẹyinda yii.ANN 23.4

    Ijọba popu di abaṣẹwaa ninu aye, olotu ijọba ati awọn ọba n tẹriba fun aṣẹ alufa Romu. O dabi ẹnipe atubọtan eniyan fun aye yii aye ti n bọ wà labẹ àkóso rẹ. Fun ọpọlọpọ ọdun ọgọọrọ awọn eniyan n tẹwọ gba awọn ikoni rẹ laironu, wọn n fi tọwọtọwọ tẹle awọn ilana rẹ, gbogbo eniyan si n jumọ n bọwọ fun awọn ọjọ ajọyọ rẹ. A bu ọla fun awọn alufa rẹ a si n fun wọn ni ẹbun ni àkóyawọ. Lati igba yẹn ijọ Romu ko de ipò iyi, ọla, ati agbara yii mọ.ANN 23.5

    Ṣugbọn “ọsan ijọ paadi ni òru araye.” Iwe Mimọ di ohun ajeji, ki i ṣe si awọn eniyan nikan, ṣugbọn si awọn alufa pẹlu. Bii ti awọn Farisi ti ìgbàa nì, awọn olori ijọ paadi korira imọlẹ ti yoo fi ẹṣẹ wọn han. Nigba ti a ti mu ofin Ọlọrun, odiwọn ododo kuro, wọn n lo agbara laisi idaduro, wọn n dẹṣẹ laisi ikalọwọko. Ẹtan, ojukokoro, ati inakuna gba ilẹ kan. Awọn eniyan ko bẹru lati da ẹṣẹ eyi ti yoo fun wọn ni ọrọ tabi ipo. Aafin popu ati awọn alufa da ibi ti a ti n ṣe iṣekuṣe ti o buru jai. Diẹ lara awọn popu jẹbi awọn iwa ọdaran ti wọn bíninínú débi wipe awọn adari ilu ṣe akitiyan lati rọ awọn ijoye ijọ wọnyi loye gẹgẹ bi oniwa ibajẹ ti a ko le fi ara da. Fun ọpọlọpọ ọdun Europe ko ni idagbasoke ninu ẹkọ, iṣẹ ọnà, tabi ọlaju. Arun ẹgbà iwa ati ti ọpọlọ dé ba ẹsin Kristẹni.ANN 23.6

    Ipo ti aye wa labẹ agbara Romu jẹ imuṣẹ ti o lẹru ti o si peye fun awọn ọrọ woli Hosea: “Awọn eniyan Mi n ṣegbe nitori ti wọn ko ni imọ: nitori ti iwọ kọ imọ silẹ, Emi yoo kọ ọ silẹ pẹlu: . . . nitori ti iwọ ti gbagbe ofin Ọlọrun rẹ, Emi yoo gbagbe awọn ọmọ rẹ pẹlu.” “Ko si otitọ, tabi aanu, tabi imọ Ọlọrun ninu ilẹ naa. Nipa ibura, ati irọ, ati ipaniyan, ati olè jija, ati agbere ṣiṣe, wọn fọn sita, ti ẹjẹ si n kan ẹjẹ.” Hosea 4:6,1, 2. Eyi ni o maa n jẹ atubọtan kikọ ọrọ Ọlọrun silẹ.ANN 23.7

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents