Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORI KẸFA—HUSS ATI JEROME

  A ti gbin iyinrere si Bohemia lati ibẹrẹ ọrundun kẹsan. A ṣe itumọ Bibeli, a si n ṣe isin apapọ ni ede abinibi awọn eniyan. Ṣugbon bi agbara popu ti n pọ si, bẹẹ naa ni ọrọ Ọlọrun ṣe n fi ara sin. Gregory VII ti o ri bi ojuṣe rẹ lati sẹ igberaga awọn ọba rọ, tun ni erongba lati ko awọn eniyan ni igbekun pẹlu; nitori naa, a pa aṣẹ ti o sọ ọ di eewọ lati ṣe isin apapọ ni ede Bohemia. Popu sọ wipe “o tẹ Alagbara giga lọrun wipe ki a maa ṣe isin òun ni ede àìmọ, ati wipe ọpọlọpọ iwa buburu ati ẹkọ eke ni wọn ti jẹ jade nitori pe a ko ṣe igbọran si ofin yii.” Bayi ni Romu ṣe paṣẹ pe ki a pa ina ọrọ Ọlọrun ki a si ti awọn eniyan mọ inu okunkun. Ṣugbọn Ọrun ti pese awọn ọna miran silẹ lati pa ijọ mọ. Ọpọlọpọ awọn Waldenses ati Albigenses ti inunibini ni France ati Italy lé kuro ninu ile wọn wa si Bohemia. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn ko le waasu ni gbangba, wọn fi itara ṣiṣẹ labẹlẹ. Bayi ni a ṣe pa igbagbọ tootọ mọ lati ọdun de ọdun.ANN 41.1

  Ṣaaju akoko Huss, awọn kan wa ni Bohemia ti wọn ṣe atako si awọn iwa ibajẹ inu ijọ ati iwa aibikita awọn eniyan ni gbangba. Ọpọ awọn eniyan ni wọn fiye si iṣẹ wọn. Eyi ru ibẹru awọn oloye ijọ soke, a si bẹrẹ inunibini si awọn ọmọlẹyin iyinrere. A le wọn lati jọsin ninu igbo ati awọn oke, awọn ẹgbẹgun dọdẹ wọn kaakiri, ọpọlọpọ ni wọn padanu ẹmi wọn. Lẹyin akoko diẹ, a paṣẹ wipe ki a dana sun gbogbo awọn ti wọn ba yapa kuro ninu ilana ẹsin Romu. Ṣugbọn nigba ti awọn Kristẹni n fi ẹmi wọn lelẹ, wọn n wọna fun iṣẹgun igbagbọ wọn. Ọkan lara awọn ti wọn n “kọni wipe nipa igbagbọ ninu Olugbala ti a kan mọgi nikan ni a file ri igbala,” sọ nigba ti o n ku wipe: “Ni akoko yii, ibinu awọn ọta otitọ n bori wa, ṣugbọn ki yoo ri bẹẹ titi lae; ẹnikan yoo dide lara awọn eniyan lasan, laini ida tabi aṣẹ, wọn ki yoo si le bori rẹ.” Akoko Luther si jina réré ni ọjọ iwaju; ṣugbọn ẹnikan ti n dide ná, ẹni ti ẹri rẹ si Romu yoo mi awọn orilẹ ede.ANN 41.2

  John Huss wa lati ile talaka, iku baba rẹ si tètè sọ ọ di alaini baba. Iya rẹ ti o jẹ olufọkansin, ri ẹkọ ati ibẹru Ọlọrun bi ohun ti o niyelori julọ ninu awọn ohun ini, o si wọna lati fun ọmọ rẹ ni ogún ini yii. Huss lọ si ile ẹkọ ti o wa ni ileto wọn, lẹyin eyi o lọ si ile ẹkọ giga ni Prague, o wọle gẹgẹ bi akẹkọ ti a ṣe itọrẹ aanu fun. Iya rẹ sin in lọ si Prague; opó ti o tun jẹ otoṣi, ko ni ọrọ aye kankan lati fifun ọmọ rẹ gẹgẹ bi ẹbun, ṣugbọn bi wọn ti n wọ inu ilu nla naa, o kunlẹ lẹgbẹ ọmọ alaini-baba naa o si gba adura ibukun Baba wọn ti n bẹ ni ọrun le lori. Iya rẹ ko ni imọ kikun nipa bi a yoo ti dahun adura rẹ.ANN 41.3

  Ninu ile ẹkọ giga, Huss ya ara rẹ sọtọ nipa ifọkansi laikaarẹ ati idagbasoke rẹ, nigba ti igbesi aye ailabawọn ati iwa tutu rẹ, pẹlu iwa ikonimọra rẹ mu ki gbogbo eniyan o bọwọ fun. O fi tọkantọkan gbagbọ ninu Ijọ Romu, o si n fi itara wa awọn ibukun ẹmi ti o n sọ wipe oun n fifun ni. Ni ọjọ ajọdun, o lọ lati ṣe ijẹwọ ẹṣẹ, o san awọn owo ẹyọ ti wọn ku ni ọwọ rẹ, o si tẹle awọn eniyan ti n to lọwọọwọ ki o baa le pin ninu idariji ti a ṣe ileri. Lẹyin ti o pari ẹkọ rẹ ni ile ẹkọ giga, o dara pọ mọ ẹgbẹ alufa, o si tete goke agba, laipẹ a gbe lọ si aafin ọba. A tun sọ ọ di ọjọgbọn, lẹyin eyi o di olori ile ẹkọ ti o ti kẹkọ jade. Laarin ọdun diẹ akẹkọ otoṣi ti a n ṣe itọrẹ aanu fun di ohun amuyangan fun orilẹ ede rẹ, ti oruko rẹ si di ilumọ-ọn ka ni ilẹ Europe.ANN 41.4

  Ṣugbọn ni abala miran ni Huss ti bẹrẹ iṣẹ atunṣe. Ni ọdun diẹ lẹyin ti o wọ inu ẹgbẹ alufa, a yan-an lati jẹ oniwaasu ninu ile ijọsin ti Bethlẹhẹmu. Ẹni ti o da ile ijọsin yii silẹ sọ ọ gẹgẹ bi ohun ti o ṣe pataki lati ṣe iwaasu Iwe Mimọ ni ede awọn eniyan.ANN 41.5

  Bi o tilẹ jẹ wipe Romu ṣe atako si, a ko dawọ rẹ duro patapata ni Bohemia. Ṣugbọn awọn eniyan jẹ òpè ninu Bibeli pupọpupọ, awọn iwa ibajẹ ti wọn buru julọ si gbilẹ laarin gbogbo eniyan. Huss ṣe ibawi awọn iwa buburu yii laipẹ ọrọ sọ, o si n tọka si ọrọ Ọlọrun lati fi idi ẹkọ otitọ ati iwa mimọ ti o n fi kọni mulẹ. Jerome, ọmọ ilu Prague, ti o jẹ ọrẹ pẹkipẹki fun Huss kó awọn iwe Wycliffe dani nigba ti o n ti England bọ. Ọbabinrin Engalnd, ẹni ti o gbagbọ ninu awọn ikọni Wycliffe, jẹ ọmọ ọba ni Bohemia, nipasẹ rẹ, iṣẹ Alatunṣe naa tan kalẹ ni ilẹ abinibi rẹ. Huss ka awọn iwe wọnyi pẹlu ifẹ ọkan; o gbagbọ wipe Kristẹni tootọ ni ẹni ti o kọ wọn o si fi oju rere wo awọn atunṣe ti o n waasu rẹ. Laimọ, Huss gbẹsẹ le ọna ti yoo dari rẹ jinna réré si Romu.ANN 41.6

  Laarin akoko yii, awọn alejo kan wa si Prague lati England, wọn jẹ ọmọwe to ti gba imọlẹ, wọn si wa lati tan-an kalẹ ni ilẹ jijina réré. Wọn bẹrẹ nipa titako aṣẹ Romu ni gbangba, laipẹ awọn alaṣẹ pa wọn lẹnu mọ; ṣugbọn nitori pe wọn ko fẹ fi erongba wọn silẹ, wọn lo ọna miran. Wọn jẹ ayaworan bi wọn ti jẹ oniwaasu pẹlu, wọn tẹsiwaju lati lo imọ wọn. Ni ibi ojutaye kan, wọn ya aworan meji sibẹ. Ọkan ṣe afihan bi Kristi ti wọ Jerusalẹmu, “ni ọlọkan tutu ti o joko lori kẹtẹkẹtẹ” (Matiu 21:5), ti awọn ọmọ ẹyin rẹ tẹle laiwọ bata, pẹlu aṣọ ti o ti gbó nitori ìrìn àjò ni ọrun wọn. Aworan keji fi itolọwọọwọ popu han—popu wọ aṣọ olowo iyebiye ati ade onipele mẹta, o gun ẹṣin ti a ṣe lọṣọ gidigidi, awọn kadina ati awọn alufa rẹ tẹle lẹyin pẹlu aṣọ ti n dan.ANN 42.1

  Eyi jẹ iwaasu ti gbogbo awọn eniyan fiye si. Ọgọọrọ awọn eniyan n wa lati wo awọn aworan wọnyi. Ko si ẹni ti ko mọ itumọ rẹ, ọpọlọpọ ni wọn si ni imọlọkan ti o jinlẹ nipa iyatọ ti o wa ni aarin irẹlẹ ati ọkan tutu Kristi Oluwa ati igberaga ati ìrera popu ti o pe ara rẹ ni atẹle Rẹ. Idarudapọ nla deba Prague, lẹyin igba diẹ, awọn alejo yii ri wipe o ṣe pataki fun wọn lati fi ilu naa silẹ nitori aabo ara wọn. Ṣugbọn a ko le gbagbe ẹkọ ti wọn ti kọni. Awọn aworan naa mu Huss lọkan pupọpupọ, o si mu ki o tubọ kọ ẹkọ Bibeli ati awọn iwe Wycliffe si. Bi o tilẹ jẹ wipe titi di akoko yii, koi tii mura silẹ lati gba gbogbo atunṣe ti Wycliffe waasu rẹ, o ri ilana ijọ paadi ni bi o ti ri gan-an, o si fi itara ti o gbona si ṣe ibawi si igberaga, oju kokoro ati iwa ibajẹ awọn olori ijọ.ANN 42.2

  Imọlẹ naa tan de Germany lati Bohemia, nitori rukerudo ti o ṣẹlẹ ni ile ẹkọ giga ni Prague mu ki ọpọlọpọ awọn ọmọ Germany o pada sile. Ọpọlọpọ ni wọn ni imọ wọn akọkọ nipa Bibeli lati ọdọ Huss, nigba ti wọn si n pada si ilẹ baba wọn, wọn tan iyinrere naa kalẹ.ANN 42.3

  Iroyin iṣẹ ti n lọ ni Prague de Romu, laipẹ, a pe Huss lati wa fi ara han ni Romu. Lati jẹ ipe yii tumọ si wipe o fi ara rẹ si ọwọ iku ti o daju. Ọba ati ayaba Bohemia, ile ẹkọ giga, awọn ijoye, ati awọn alaṣẹ ijọba wa parapọ lati ṣipẹ si popu pe ki o gba Huss laaye lati duro ni Prague ki o si ran aṣoju lati fi ara han ni Romu. Dipo ki o gba ipẹ yii, popu tẹsiwaju lati ṣe igbẹjọ Huss, o si da a lẹbi, o wa yọ gbogbo ilu Prague kuro ninu ijọ.ANN 42.4

  Ni akoko naa, ibikibi ti a ba ṣe iru idajọ yii fun, o maa n fa ibẹrubojo. Awọn isin ti a maa n fi n gbe e lẹsẹ jẹ eyi ti a maa n ṣe ni ọna ti yoo ko ipaya ba awọn ti n wo popu gẹgẹ bi aṣoju Ọlọrun funra Rẹ, ti o ni kọkọrọ ọrun ati ipo oku, ti o si ni agbara lati ṣe idajọ ti ara ati ti ẹmi. Awọn eniyan gbagbọ wipe a ti ilẹkun ọrun mọ agbegbe ti a ba ṣe idajọ yii le lori; ati pe titi fi di igba ti o ba tẹ popu lọrun lati mu aṣẹ yii kuro, a yoo ti ilẹkun ibi igbadun mọ awọn ti wọn bá kú. Ni idaniloju fun ajalu nla yii, a dawọ gbogbo eto ẹsin duro ni agbègbè naa. A ti awọn ile ijọsin pa. A n ṣe eto igbeyawo ni agbala ile ijọsin. A ko jẹ ki a sin awọn oku sori ilẹ ti a ya si mimọ, ṣugbọn a sin wọn sinu koto tabi sinu oko laisi eto isinku. Romu wa n ṣe akoso ọkan awọn eniyan nipasẹ awọn ohun ti wọn bu mọ eniyan lọkan wọnyi. Ilu Prague kun fun rogbodiyan. Ọpọ awọn eniyan da Huss lẹbi gẹgẹ bi okunfa gbogbo ajalu wọn, wọn si sọ wipe ki a jọwọ rẹ lọwọ fun igbẹsan Romu. Ki ìjì naa baa le dawọ duro, Alatunṣe naa pada si ileto abinibi rẹ fun igba diẹ. O kọ iwe si awọn ọrẹ rẹ ti o fi silẹ ni Prague wipe: “Bi mo ba kuro laarin yin, nitori ati lè tẹle ilana ati apẹẹrẹ Jesu Kristi ni, lati maṣe gba awọn ti ọkan wọn n ṣojo laaye lati fa idalẹbi ayeraye si ori ara wọn, ati lati maṣe jẹ okunfa ijiya ati inunibini fun awọn olufọkansin. Mo tun kuro nitori ibẹru pe awọn alufa aliwabiọlọrun le ma gba iwaasu ọrọ Ọlọrun laaye laarin yin; ṣugbọn emi kò kuro lọdọ yin lati sẹ otitọ mimọ, eyi ti mo ṣetan lati ku nitori rẹ, pẹlu iranlọwọ Ọlọrun.” Huss ko dawọ iṣẹ rẹ duro, ṣugbọn o n rinrin ajo lọ si awọn ileto ti wọn wa ni ayika, o n waasu fun awọn èrò ti wọn ṣetan lati gbọ ọ. O wa ṣẹlẹ wipe ọna ti Romu lo lati tẹ iyinrere rì wa jẹ ọna ti o fi tàn kalẹ si daradara. “A ko le ṣe ohunkohun lati tako otitọ, ayafi lati gbè ti i.” 2 Korintin 13:8.ANN 42.5

  “Ninu ipele yii ninu iṣẹ rẹ, o dabi ẹnipe ọkan Huss kun fun ijakadi kikoro. Bi o tilẹ jẹ wipe ijọ n wa ọna lati fi agbara rẹ da a lágara, koi tii kọ aṣẹ rẹ silẹ. O si gba wipe Ijọ Romu ni aya Kristi, popu si ni aṣoju Ọlọrun. Ki i ṣe ipilẹ ẹkọ funra rẹ ni Huss kọ oju ija si, bikoṣe ìlòkulò agbara. Eyi da ijakadi kikan silẹ laarin ohun ti o mọ ati ẹri ọkan rẹ. Bi aṣẹ naa bá pé, ti ko sile baku, gẹgẹ bi o ti gbagbọ wipe o ri, kilo de ti ọkan rẹ n fẹ lati ṣe aigbọran si? O ri wipe ṣiṣe igbọran si jasi ẹṣẹ; ṣugbọn kilo de ti igbọran si aṣẹ ijọ ti ko le baku ṣe di ọran nla bayii? Eyi jẹ isoro ti ko ri idahun si; eyi jẹ ohun ti o n da a lamu nigba gbogbo. Ohun ti o ri ti o sunmọ idahun julọ ni wipe o ti tun ṣẹlẹ, gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ ṣaaju ni akoko Olugbala, ti awọn alufa ijọ di eniyan buburu, ti wọn si n lo aṣẹ wọn ti o tọna fun ohun ti ko tọ. Eyi dari rẹ lati gba ikọni wipe ẹkọ Iwe Mimọ ti eniyan ba ni oye rẹ ni o yẹ ki o ṣe akoso ọkan; o gba eyi fun itọsọna ara rẹ, o si n waasu rẹ lati jẹ itọsọna fun awọn miran; ni ọna miran ẹwẹ, ki i ṣe ijọ ti n sọrọ nipasẹ awọn alufa, bikoṣe Ọlọrun ti o n sọrọ ninu Bibeli, ni itọsọna ti ko le baku.”ANN 43.1

  Lẹyin ti rukerudo ilu Prague sẹrọ, Huss pada si ile ijọsin rẹ ni Prague lati waasu ọrọ Ọlọrun pẹlu itara ati igboya ti o pọ si. Awọn ọta rẹ ni agbara, wọn si n ṣiṣẹ, ṣugbọn ayaba ati ọpọ ninu awọn ijoye jẹ ọrẹ rẹ, ọpọ awọn eniyan ni wọn si ti i lẹyin. Ni fifi ikọni rẹ ti ko labawọn ti o si buyì kunni, ati igbe aye iwa mimọ rẹ wé awọn ikọni ti wọn n rẹnisilẹ ti awọn atẹle Romu n waasu rẹ, ati iwa ifẹ owó ati iwa aikora-ẹni-nijanu wọn wé ara wọn, ọpọ ri wipe ohun ti o buyi kunni ni lati gbe ti i lẹyin.ANN 43.2

  Titi di akoko yii, Huss nikan ni o n da ṣe iṣẹ rẹ; ṣugbọn ni akoko yii Jerome, ẹni ti o gba awọn ikọni Wycliffe nigba ti o wa ni England, wa dara pọ mọ iṣẹ atunṣe. Lati akoko yii lọ, awọn mejeeji jijọ wa ni iṣọkan ninu igbesi aye wọn, wọn ko si pinya ninu iku. Òye ti o já fáfá, ẹbun ọrọ sisọ, ati ẹkọ—awọn ẹbun ti wọn n jẹ ki a fẹran ẹni—ni Jerome ní ní àrà ọtọ; ṣugbọn Huss ní awọn ẹbun ti wọn fi okun ìwà hàn ju u lọ. Isọwọronu ní pẹlẹkutu rẹ ká ẹmi wiwuwa laironu Jerome lọwọ kò, oun naa mọ ìwúlò rẹ, o si n fi irẹlẹ gba awọn imọran rẹ. Atunṣe naa tubọ tan kalẹ si labẹ ajumọ ṣiṣẹ pọ wọn.ANN 43.3

  Ọlọrun fi aaye gba imọle nla lati tan si ọkan awọn eniyan pataki yii, O fi ọpọlọpọ awọn aṣiṣe Romu han wọn; ṣugbọn wọn ko gba gbogbo imọlẹ ti o yẹ ki a fun araye. Nipasẹ awọn iranṣẹ Rẹ wọnyi, Ọlọrun n dari awọn eniyan Rẹ kuro ninu okunkun ẹsin Romu; ṣugbọn ọpọlọpọ idena nla ni wọn yoo ba pade, O si n dari wọn ni sisẹ ntẹle, bi wọn ti le fi ara da a. Wọn ko ṣetan lati gba gbogbo imọlẹ naa ni ẹẹkan ṣoṣo. Bi a ba fifun wọn, yoo mu ki wọn yipada bi ogo oorun ọsan gangan ti n ṣe si awọn ti wọn ti wa ninu okunkun fun igba pipẹ. Nitori naa O fi han awọn adari naa diẹdiẹ, bi awọn eniyan a ti ṣe le gba a. Lati ọdun de ọdun, awọn oṣiṣẹ olootọ miran yoo tẹle wọn lati dari awọn eniyan siwaju si sí oju ọna atunṣe.ANN 43.4

  Iyapa inu ijọ si n tẹsiwaju. Awọn popu mẹta ni wọn wa n ja fun ipo, ijakadi wọn si fi rudurudu ati iwa ọdaran kun inu ẹsin Kristẹni. Nigbati fifi ara ẹni gegun ko tẹ wọn lọrun, wọn bẹrẹ si ni lo ohun ija oloro. Olukuluku wọn ni o n wa ọna lati ra ohun ija ati lati ri awọn ọmọ ogun. Wọn nilo owo; lati le ri eyi, wọn sọ awọn ẹbun, ipo ati ibukun ijọ di tita. Awọn alufa pẹlu tẹle apẹẹrẹ awọn ọga wọn, wọn n ta awọn ohun to ni i ṣe pẹlu ijọ, wọn n ja ogun lati le fi idi ẹni ti o n ba wọn figagbaga rẹmi, ati lati le fi idi agbara wọn mulẹ. Pẹlu igboya ti n pọ si lojoojumọ Huss waasu tako awọn iwa eeri ti a fi aaye gba ni orukọ ẹsin; awọn eniyan si fi ẹsun kan awọn adari ijọ Romu ni gbangba gẹgẹ bi okunfa awọn idamu ti wọn bo ẹsin Kristẹni kikankikan.ANN 43.5

  O tun dabi ẹnipe ilu Prague n sunmọ bèbè ijakadi ti o le fa itajẹsilẹ. Bi o ti ṣẹlẹ latẹyin wa, a fi ẹsun kan iranṣẹ Ọlọrun gẹgẹ bi “ẹni ti n yọ Israeli lẹnu.” 1 Awọn Ọba 18:17. A tun yọ gbogbo ilu naa kuro ninu ijọ, Huss tun pada si abule rẹ. Ijẹri ti o fi ootọ inu ṣe ninu ile ijọsin rẹ ni Bẹthlẹhẹmu ti pari. Yoo sọrọ si gbogbo awọn Kristẹni lati ibi ti o fẹ si, ki o to fi ẹmi rẹ lelẹ gẹgẹ bi ẹri fun otitọ.ANN 43.6

  Lati le dawọ iwa ibi ti o n da Europe laamu duro, a pe ajọ gbogboogbo kan si ilu Constance. Ọba Sigismund ni o pa a laṣẹ ki ọkan lara awọn popu ti wọn n ja fun ipo, John XXIII, o pe ipade naa. Ipe fun ipade naa ko tẹ Popu John lọrun rara, nitori iwa ati iṣesi rẹ ko le yege bi a ba ṣe iwadi wọn, ani bi o ba tilẹ jẹ wipe awọn alufa ti iwa wọn ko mọ bi ti awọn ọmọ ijọ ni akoko naa ni wọn ṣe e. Ṣugbọn ko tobẹ ki o tako ifẹ Sigismund.ANN 44.1

  Awọn ohun pataki ti ipade naa yoo ṣe ni lati wa ojutu si iyapa ti o wa ninu ijọ ati lati fa ekọ odi tu. Nitori naa a pe awọn popu mejeeji ti wọn n tako ara wọn lati wa fi ara han niwaju rẹ, a tun pe aṣiwaju awọn ti wọn n kọ ẹkọ tuntun, John Huss pẹlu. Awọn popu mejeeji ko wa nitori ti wọn fẹ daabo bo ẹmi ara wọn, ṣugbọn wọn ran aṣoju wa. Popu John, ẹni ti a mọ wipe oun ni o pe ipade naa, wá pẹlu awọn iyemeji, o n ro boya erongba inu ọba ni lati yọ oun nipo, o si n bẹru ki a maṣe ṣe iwadi awọn iwa ọdaran ti o fi ko itiju bá ade ijọ, ati iwa ọdaran ti o fi gba ade naa. Sibẹ pẹlu ọla nla ni o fi wọ inu ilu Constance, ti awọn ijoye nlanla inu ijọ ati awọn iranṣẹ aafin tẹle. Gbogbo awọn alufa ati ijoye inu ilu naa, pẹlu ọgọọrọ awọn ero ni wọn jade lọ pade rẹ. Ìbòrí igunwa oniwura ti awọn alaṣe ilu mẹrin gbe dani ni a fi bo o lori. A gbe akara ti a ya si mimọ dani niwaju rẹ, ti aṣọ olowo iyebiye awọn kadina ati ti awọn ijoye jẹ ki ibẹ o lẹwa gidigidi.ANN 44.2

  Ṣugbọn arinrin ajo kan n sunmọ Constance. Huss mọ awọn ewu ti wọn le wu oun. O kuro ni ọdọ awọn ọrẹ rẹ bi ẹnipe wọn ko ni pade mọ, o si mu ọna rẹ pon ti oun ti ero wipe ó n mu oun lọ si ibi idana-sunni. Bi o tilẹ jẹ wipe o gba iwe idaabobo kan lọwọ ọba Bohemia, ti o tun gba omiran lọwọ Sigismund ninu ajo rẹ, o ṣe ohun gbogbo silẹ bi ẹnipe iku le de.ANN 44.3

  Ninu iwe kan ti o kọ si awọn ọrẹ rẹ ni Prague, o sọ pe: “Ẹyin ara mi, . . . mo n lọ pẹlu iwe idaabobo lati ọwọ ọba lati lọ pade awọn ọta mi ti wọn pọ niye ti wọn ko si dẹyin. . . . Mo fi gbogbo igbẹkẹle mi sinu Ọlọrun alagbara, sinu Olugbala mi; mo gbagbọ wipe yoo tẹti si adura atọkanwa yin, wipe yoo fi ọgbọn ati oye Rẹ si mi lẹnu ki n baa le doju ija kọ wọn; ki O si fun mi ni Ẹmi Mimo Rẹ lati le fun mi ni okun ninu otitọ, ki n le fi igboya doju kọ idanwo, ọgba ẹwọn ati bi o ba pan dandan, iku oró. Jesu Kristi jiya fun awọn ayanfẹ Rẹ; nitori naa ṣe o yẹ ki o ya wa lẹnu wipe O fi apẹẹrẹ lelẹ fun wa bi, ki awa pẹlu baa le fi suuru fi ara da ohun gbogbo nitori igbala wa? Oun ni Ọlọrun, awa si ni ẹda Rẹ; Oun ni Oluwa, awa si ni iranṣẹ Rẹ; Oun ni Oluwa gbogbo aye, awa si jẹ otoṣi ẹlẹran ara—sibẹ O jiya! Kilo wa de ti awa pẹlu ko fi nilati jiya, niwọn igba ti ijiya wa fun ifọmọ wa? Nitori naa ẹyin ololufẹ, bi iku mi yoo ba fi kun ogo Rẹ, ẹ gbadura ki o yara wa kankan, ki O si ran mi lọwọ lati fi ara da gbogbo wahala mi pẹlu iduroṣinṣin. Ṣugbon bi pipada mi wa si ọdọ yin yoo ba dara julọ, ẹ jẹ ki a gbadura ki n le pada wa laisi abawọn—ki n ma baa fi eyi ti o kere julọ ninu otitọ iyinrere pamọ, ki n baa le fi apẹẹrẹ ti o dara lelẹ fun awọn arakunrin mi lati tẹle. Nitori naa, o ṣe e ṣe ki ẹ ma ri oju mi ni Prague mọ; ṣugbọn bi ifẹ Ọlọrun alagbara julọ yoo ba ṣe e ki n pada si ọdọ yin, ẹ jẹ ki a tẹsiwaju pẹlu ọkan ti o gboya si ninu imọ ati ifẹ ofin Rẹ.”ANN 44.4

  Ninu lẹta miran ti o kọ si alufa ti o di ọmọ ẹyin iyinrere, Huss sọ nipa awọn aṣiṣe ara rẹ pẹlu irẹlẹ ọkan, o ba ara rẹ wi “fun nini ifẹ ninu wiwọ aṣọ olowo iyebiye ati fifi akoko ṣofo ninu awọn iṣẹ ti ko nitumọ.” O wa fi awọn igbaniniyanju ti wọn fi ọwọ bani lọkan wọnyi kun: “Ki kíkó ọrọ ati ile jọ o maṣe gba ọkan rẹ kan bikoṣe ogo Ọlọrun ati igbala ọkan awọn eniyan. Ṣọra fun titọju ile rẹ ju ọkan rẹ lọ; ati ju gbogbo rẹ lọ fi iyè si ile ẹmi rẹ. Jẹ onifọkansin ati onirẹlẹ pẹlu awọn alaini, ki o ma siṣe lo awọn ohun ini rẹ lori onjẹ. Bi o ko ba tun igbesi aye rẹ ṣe, ki o si yipada kuro ninu asan, mo bẹru wipe à á bá ọ wi pupọpupọ gẹgẹ bi a ti ṣe si mi. . . . O mọ awọn ikọni mi, nitori ti iwọ ti gba awọn ẹkọ mi lati ọdọmọde rẹ wa; nitori naa mi o nilo lati kọwe si o mọ. Ṣugbọn mo rọ ọ pẹlu aanu Oluwa lati maṣe tẹle apẹẹrẹ mi ninu awọn asan ti o ri ti mo ti ṣubu.” O fikun lẹyin apo iwe naa wipe: “Mo rọ ọ, ọrẹ mi lati maṣe ja edidi yii titi iwọ yoo fi ri daju wipe mo ti ku.”ANN 44.5

  Ninu irin ajo rẹ, Huss ri ami itankalẹ awọn ikọni rẹ, o si ri bi awọn eniyan ti fi oju rere wo iṣẹ rẹ. Ọpọ awọn eniyan ni wọn lọ pade rẹ, ninu awọn ilu miran, awọn alaṣẹ ilu sin in kọja laarin ilu wọn.ANN 45.1

  Nigba ti o de Constance, a fun Huss ni ominira kikun. Yatọ si iwe idaabo ọba, popu funra rẹ tun fi da a loju wipe yoo ri aabo. Ṣugbọn, ni aibikita si awọn ọrọ wọnyi, lẹyin akoko diẹ, pẹlu aṣẹ popu ati ti awọn kadina, a mu Alatunṣe naa, a si ti i mọ inu ọgba ẹwọn ẹlẹgbin. Lẹyin eyi a gbe e lọ si ile iṣọ alagbara kan ti o wa ni ikọja odo Rhine, o si wa nibẹ gẹgẹ bi ẹlẹwọn. Èrè kekere ni popu naa jẹ pẹlu aiṣootẹ rẹ, nitori laipẹ jọjọ a ju oun naa si inu ọgba ẹwọn kan naa. A fi idi rẹ mulẹ niwaju igbimọ wipe o jẹbi awọn iwa ọdaran ti wọn buru julọ, pẹlu ipaniyan, tita awọn ini ijọ, ati agbere, “awọn ẹṣẹ ti ko yẹ ki a daruko.” Ohun ti igbimọ naa sọ niyi, a gba ade kuro ni ori rẹ, a si sọ ọ si ọgba ẹwọn. A yọ awọn iyooku ti wọn jijọ n du ipo popu kuro loye pẹlu, a si yan popu miran.ANN 45.2

  Bi o tilẹ jẹ wipe popu funra rẹ jẹbi awọn iwa ọdaran ti wọn tobi ju eyi ti Huss fi ẹsun rẹ kan awọn alufa lọ, ti o si n beere fun atunṣe nitori wọn, sibẹ ajọ naa ti o yọ popu loye tẹsiwaju lati pa Alatunṣe naa. Itimọle Huss fa ibinu nla ni Bohemia. Awọn ijoye alagbara ṣe atako si iṣekuṣe yii ninu igbimo naa. Ọba, ti inu rẹ ko dun si bi a ko ṣe bọwọ fun iwe idaabobo, tako bi a ṣe fẹ ṣe igbẹjọ rẹ. Ṣugbọn awọn ọta Alatunṣe naa buru, ọkan wọn si ti yigbi. Wọn ṣipẹ si aimọkan, ibẹru, ati itara ọba naa fun ijọ. Wọn sọ idi ti ko fi yẹ “ki a pa adehun mọ pẹlu awọn ẹlẹkọ odi, tabi ẹnikẹni ti a ba funra si wipe o ni ẹkọ odi, bi o ba tilẹ gba iwe idaabobo lati ọdọ ọba.” Nitori naa wọn bori.ANN 45.3

  Aisan ati itimọle ti sọ ọ di alaare,—nitori otutu ati afefe rirun inu ọgba ẹwọn naa jẹ ki o ni iba ti o fere gba ẹmi rẹ—lẹyin-ọrẹyin, a mu Huss wa siwaju igbimọ. Pẹlu ẹwọn ni ara rẹ o duro niwaju ọba, ẹni ti o fi ọwọ ati inu rere ṣe ileri lati daabo bo o. Ni gbogbo akoko gbọọrọ ti a fi ṣe ayẹwo rẹ, o duro gbọin pẹlu otitọ, o si fi tọkantọkan tako awọn aṣiṣe inu ijọ niwaju awọn oloye ijọ ati ti ilu ti wọn pejọ pọ. Nigba ti a beere lọwọ rẹ boya yoo kọ awọn ikọni rẹ silẹ tabi ki o jiya iku, o yan atubọtan ajẹriku.ANN 45.4

  Oore ọfẹ Ọlọrun fun ni okun. Alaafia ọrun kun inu ọkan rẹ ni aarin awọn ọṣẹ ṣaaju ki a to ṣe idajọ rẹ. O sọ fun ọrẹ rẹ kan wipe, “Mo kọ iwe yii ninu ọgba ẹwọn mi, pẹlu ẹwọn ni ọwọ mi, ti mo si n reti idajọ iku mi ni ọla. . . . Pẹlu iranlọwọ Jesu Kristi, nigba ti a a ba pade ninu alaafia didun ọjọ iwaju, wa a mọ bi Ọlọrun ti fi ara Rẹ han ni alaanu si mi, bi O ṣe ran mi lọwọ to laarin awọn idanwo ati wahala mi.”ANN 45.5

  O ri iṣẹgun igbagbọ tootọ ninu okunkun ile tubu rẹ. Ninu ala rẹ o pada si ile ijọsin ni Prague, nibi ti o ti waasu iyinrere, o ri popu ati awọn biṣọbu rẹ ti wọn n pa aworan Kristi ti o ya si ara ogiri rẹ. “Iran yii ko iporuuru ọkan ba: ṣugbọn ni ọjọ keji o ri ọpọlọpọ awọn ayaworan ti wọn n tun awọn aworan yii yà si ibi ti o pọ si, ati pẹlu awọn ọda to han ketekete si. Nigba ti wọn pari iṣẹ wọn tan, awọn ayaworan naa ti ọpọ awọn eniyan rọgba yi ka sọ wipe, ‘Ẹ jẹ ki awọn popu ati awọn biṣọbu wa nisinsinyii; wọn ki yoo si le pa wọn rẹ mọ!’” Bi o ti n rọ ala rẹ, Alatunṣe naa sọ wipe: “Eyi damiloju wipe a ki yoo le pa aworan Kristi rẹ laelae. Wọn fẹ lati pa a run, ṣugbọn awọn oniwaasu ti wọn dara ju mi lọ yoo tun-un kun ni ọkan awọn eniyan.”ANN 45.6

  A mu Huss wa siwaju igbimọ fun igba ikẹyin. Ọpọ awọn eniyan ati awọn ẹni nla ni wọn wa nibe—ọba, awọn ijoye ijọba naa, awọn iranṣẹ ọba, awọn kadina, biṣọbu, ati awọn alufa, ati ọgọọrọ awọn eniyan ti wọn wa lati wo iṣẹlẹ ọjọ naa. Lati gbogbo ibi ti a ti n ṣe ẹsin Kristẹni ni awọn eniyan ti wa lati wa jẹri si irubọ nla akọkọ ninu ijakadi ọlọjọ gbọọrọ ti yoo funni ni ominira ẹri ọkan yii.ANN 45.7

  Nigba ti a pe e fun ipinu ikẹyin rẹ, Huss sọ wipe oun kọ lati yi ohùn pada, nigba ti o tẹju mọ ọba ti a fi ainitiju kọ ileri ti o ṣe silẹ, o sọ wipe: “Mo pinu lati inu ọkan mi wa lati fi ara han niwaju igbimọ yii, labẹ idaabobo ati ootọ inu ọba ti o wa nibi.” Oju Sigismund pọn bi gbogbo awọn ti wọn wa ninu igbimọ naa ti yi oju si ọdọ rẹ.ANN 45.8

  Nigba ti a ṣe idajọ rẹ tan, a bẹrẹ ètò ifiniṣẹsin. Awọn biṣọbu wọ ẹlẹwọn wọn ni aṣọ ni bi a ti n wọ awọn alufa ni aṣọ, bi o ti n wọ aṣọ alufa, o sọ pe: “A wọ Jesu Kristi Oluwa wa ni aṣọ funfun, nigba ti Hẹrodu ran An lọ si ọdọ Pilatu gẹgẹ bi ọna lati tabuku Rẹ.” Ni igba ti a tun gba a niyanju ki o yi ọrọ rẹ pada, o yi oju pada si awọn eniyan, o dahun wipe: “Iru oju wo ni maa wa fi wo ọrun? Bawo ni maa ṣe wo ọgọọrọ awọn eniyan ti mo ti waasu iyinrere alailabawọn fun? Rara; igbala wọn niyelori loju mi ju ara otoṣi ti a yan fun iku yii lọ.” A wa bọ awọn ewu naa nikọọkan, olukuluku awọn biṣọbu si n fi gegun bi wọn ti n ṣe ipa ti wọn. Nikẹyin, “wọn fi ade alufa ti a fi pepa ṣe, ti a ya awọn ẹmi eṣu si lara lọna ti o banilẹru, de e lori; a kọ ‘Olori awọn asọrọ odi’ si niwaju lọna to han gedegbe. Huss sọ wipe, tayọtayọ ni maa fi de ade itiju nitori Rẹ Jesu, ẹni ti o de ade ẹgun nitori mi.’”ANN 46.1

  Nigba ti a ṣe eyi tan, “awọn alufa sọ wipe, ‘Nisinsinyii, a fi ọkan rẹ le eṣu lọwọ.’ John Huss, ni gbigbe oju rẹ si oke ọrun, sọ wipe, ‘Emi fi ẹmi mi si ọwọ Rẹ, Jesu Oluwa, nitori pe O ti gbamila.’”ANN 46.2

  A wa file awọn alaṣẹ ilu lọwọ, wọn si mu u lọ si ibi ti a o ti pa a. Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn to lọwọọwọ lọ sibẹ, awọn jagunjagun, awọn alufa ati awọn biṣọbu ninu aṣọ igunwa wọn, ati awọn ti n gbe ni ilu Constance. Nigba ti a de e mọ òpó, ti o ku ki a da ina si lara, a tun rọ ajẹriku naa lati gba ara rẹ la nipa kikọ awọn aṣiṣe rẹ silẹ. Huss dahun pe, “Iru aṣiṣe wo ni maa kọ silẹ? Emi ko jẹbi ohunkohun. Mo fi Ọlọrun ṣe ẹlẹri wipe ohun gbogbo ti mo kọ silẹ ti mo si waasu rẹ jẹ pẹlu erongba lati gba awọn ọkan la kuro ninu ẹṣẹ ati iparun; nitori naa mo fi tayọtayọ fi idi ohun gbogbo ti mo kọ silẹ ti mo si waasu rẹ mulẹ pẹlu ẹjẹ mi.” Nigba ti ina n jo yii ka, o bẹrẹ si ni kọrin pe, “Jesu Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣaanu fun mi,” bi o ṣe kọrin niyi titi ti ohùn rẹ fi dakẹ titi lae.ANN 46.3

  Iduro akọni rẹ ya awọn ọta rẹ paapa lẹnu. Onifọkansin atẹle popu sọ nipa ijẹriku Huss, ati ti Jerome ẹni ti o ku laipẹ rẹ bayi wipe: “Awọn mejeeji ṣe ọkan wọn giri nigba ti wakati ikẹyin wọn de. Wọn mura silẹ fun ina afi bi ẹni ti n lọ si ibi ase igbeyawo. Wọn kò kigbe oró. Nigba ti ina n jo, wọn bẹrẹ si i kọ orin; pẹlu agbara ni ina ti n jo fi dawọ orin wọn duro.”ANN 46.4

  Nigba ti ara Huss jo tan, a ko eeru rẹ, pẹlu erupẹ ti o jo le lori, a si da wọn sinu odo Rhine, ti o gbe lọ sinu agbami okun. Awọn oninunibini rẹ ro ninu asan wọn wipe wọn ti fa otitọ ti o waasu rẹ tu. Ko ye wọn daradara wipe eeru ti omi gbe lọ fọn lọ si gbogbo orilẹ ede aye; wipe ni ilẹ ti a koi tii mọ yoo so eso pupọ ni ijẹri si otitọ. Ohùn ti o fọ ninu gbọngan igbimọ ni Constance yoo ró ni gbogbo akoko ti n bọ. Huss kò sí mọ, ṣugbọn awọn otitọ ti o ku nitori rẹ ko le parun mọ lae. Apẹẹrẹ igbagbọ ati iduroṣinṣin rẹ yoo fun ọpọ awọn eniyan lokun lati duro ṣinṣin fun otitọ loju ijiya ati iku. Bi a ṣe pa fi iwa ika ati imọọmọ ṣẹtan Romu han gbogbo aye. Bi o tilẹ jẹ wipe awọn ọta otitọ ko mọ, wọn n ran iṣẹ otitọ lọwọ, eyi ti wọn n ṣiṣẹ lasan lati parun.ANN 46.5

  Amọ a yoo tun gbe igi idanasuni miran ro ni Constance. Ẹjẹ ajẹri otitọ miran yoo jẹri si otitọ. Nigba ti Jerome n ki Huss pe o digboṣe nigba ti o n lọ si igbimọ, o gba a niyanju lati duro ṣinṣin ki o si ni igboya, o tun sọ wipe, bi o ba bọ sinu wahala kankan, oun funra oun yoo wa ran an lọwọ. Nigba ti o gbọ wipe a sọ Alatunṣe naa si atimọle, ọmọlẹyin tootọ yii mura kankan lati mu ileri rẹ ṣẹ. Laisi iwe idaabobo oun ati olubakọwọrin kan lọ si Constance. Nigba ti o debẹ, o ri mọ wipe oun tilẹ fi ẹmi ara oun wewu ni, laisi anfani lati ṣe ohunkohun lati gba Huss silẹ. O sa kuro ni ilu naa, ṣugbọn a fi ipa mu nigba ti o n pada si ile, a da pada, a fi ẹwọn de e, a si fi si ikawọ awọn ẹgbẹgun kan. Nigba ti a kọkọ mu wa siwaju igbimọ, ariwo “Ẹ sun nina! ẹ sun nina!” ni a fi bo akitiyan rẹ lati dahun si gbogbo ẹsun ti a fi kan an mọlẹ. A ju u sinu ọgba ẹwọn, a de e ni ọna ti yoo gba ni i lara, a si n fun ni burẹdi ati omi. Lẹyin oṣu diẹ inira itimọle rẹ fẹ gba ẹmi rẹ, nitori ti awọn ọta rẹ bẹru ki o ma baa bọ kuro ni ọwọ wọn, wọn ko fi iya pupo jẹ mọ, bi o tilẹ jẹ wipe o wa ninu ọgba ẹwọn fun ọdun kan.ANN 46.6

  Iku Huss ko yori si ohun ti awọn atẹle popu lero. Bi wọn ti tapa si iwe idaabobo rẹ fa wahala ibinu nla, nitori naa, gẹgẹ bi ohun ti o rọrun diẹ si, igbimọ naa pinnu, bi o ba ṣe e ṣe lati fi ipa mu Jerome lati yi igbagbọ rẹ pada, dipo ki wọn o sun un nina. A mu wa siwaju igbimọ, a wa fi lọ ọ boya yoo yi igbagbọ rẹ pada, tabi ki a pa nipa sisun nina. I ba jasi aanu bi o ba ti ku ni ibẹrẹ itimọle rẹ bi a ba fi we ijiya nla ti o ti o ti jẹ; ṣugbọn nisisinyii, aisan, inira inu ọgba ẹwọn, ati ijiya iporuuru ọkan ati ireti ohun ti o n bọ ti sọ di alailera; ko si awọn ọrẹ rẹ ni ọdọ rẹ, iku ọrẹ rẹ Huss si ba a ninu jẹ, awọn nnkan wọnyi ko irẹwẹsi ba, o si gba lati ṣe ifẹ igbimọ. O jẹjẹ lati duro ninu igbagbọ ijọ Katoliki, o si gba ipinu igbimọ ni bi wọn ti bu ẹnu atẹ lu awọn ikọni Wycliffe ati ti Huss, ayafi awọn “otitọ mimọ” ti wọn kọni.ANN 47.1

  Nipa ọgbọn ẹwẹ rẹ, Jerome gbero lati pa ẹri ọkan rẹ lẹnu mọ, ki o si bọ kuro ninu iparun rẹ. Ṣugbọn nigba ti o danikan wa ninu tubu, o ri ohun ti o ṣe kedere. O ro nipa igboya ati iṣotitọ Huss, o wa fi we bi oun ti sẹ otitọ. O ro nipa Oluwa ọrun Ẹni ti o ti ṣe ileri lati sin, ti o titori rẹ fi ara da iku agbelebu. Ṣaaju ki o to kọ igbagbọ rẹ silẹ, o ri itunu ninu idaniloju ojurere Ọlọrun laarin gbogbo ijiya rẹ; ṣugbọn nisinsinyii, iyemeji ati ikẹdun ni o n jẹ ọkan rẹ niya. O mọ wipe oun yoo tun ṣe ikọsilẹ awọn nnkan miran ki oun to le wa ni alaafia pẹlu Romu. Ifasẹyin patapata ni ọna ti o n rin yii yoo yọri si. O ṣe ipinu ọkan rẹ: Ko ni sẹ Oluwa re lati le bọyọ kuro ninu ijiya ranpẹ.ANN 47.2

  Laipẹ, a tun da pada wa siwaju igbimọ. Ohun ti o sọ ko tẹ awọn adajọ rẹ lọrun. Iku Huss ti ta oungbe wọn fun ẹjẹ ji, wọn wa n beere fun ẹran tuntun. Nipa kikọ otitọ silẹ patapata nikan ni Jerome fi le da ẹmi rẹ si. Ṣugbọn o ti pinu lati fi idi igbagbọ rẹ mulẹ, ati lati tẹle ajẹriku arakunrin rẹ lọ sinu ina.ANN 47.3

  O sọ wipe oun ko kọ igbagbọ oun silẹ mọ, ati bi ẹni ti o n ku lọ, o beere fun anfani lati wi awijare oun. Nitori pe wọn bẹru agbara ọrọ rẹ, awọn alufa ṣe e ni dandan wipe ki o kan fi idi otitọ awọn ẹsun ti wọn fi kan an mulẹ lasan ni tabi ki o sẹ wọn. Jerome ko faramọ iru iwa ika ati ifiyajẹni yii. O sọ pe, “Fun ọta-din-nirinwo ọjọ ni ẹ fi ti mi mọ ọgba ẹwọn buruku yii, laarin idọti, irira, oorun, ati aini fun ohun gbogbo; ẹ wa mu mi wa siwaju yin, mo tẹti mi silẹ lati gbọ ti awọn ọta kikoro mi, ẹ wa kọ lati gbọ temi. . . . Bi ẹ ba jẹ ọlọgbọn eniyan nitootọ, ati imọlẹ aye, ẹ ṣọra ki ẹ ma ba a ṣẹ si otitọ. Bi o ba jẹ ti emi ni, ẹlẹran ara alailagbara ni mi; ẹmi mi ko ṣe pataki pupọ; nigba ti mo sọ fun yin lati maṣe ṣe idajọ èké, mi o sọrọ nitori ara mi bikoṣe nitori yin”ANN 47.4

  Lẹyin-ọrẹyin, a gba a laaye. Jerome kunlẹ niwaju awọn adajọ rẹ, o si gbadura ki Ẹmi ọrun o dari ero ati ọrọ oun, ki o ma ba a sọ ohunkohun ti o yatọ si otitọ tabi ti ko yẹ Oluwa rẹ. Ni ọjọ naa ni ileri Oluwa fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ wa si imuṣẹ fun: “A yoo mu yin wa siwaju awọn alaṣẹ ati ọba nitori Mi. . . . Ṣugbọn nigba ti a ba fi yin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣe aniyan nitori ohun ti ẹyin yoo wi tabi bi ẹyin yoo ti sọrọ: nitori ni wakati naa ni a o fun yin ni ohun ti ẹyin yoo wi. Nitori ki i ṣe ẹyin ni o n sọrọ, bikoṣe Ẹmi Baba yin ni o n soro ninu yin.” Matiu 10:18—20.ANN 47.5

  Ani ẹnu ya awọn ọta Jerome, ọrọ rẹ si jọ wọn loju. Fun odindi ọdun kan ni o ti wa ninu ọgba ẹwọn, ti ko le kawe tabi riran, ti o n jiya ti ara ati iporuuru ọkan. Sibẹ, ọrọ rẹ yeni yekeyeke, o si lagbara a fi bi ẹnipe o n kẹkọ laisi idiwọ. O tọka awọn olugbọ rẹ si ọpọ awọn eniyan mimọ ti awọn adajọ alaiṣootọ da lẹbi. Ni gbogbo igba a maa n ri awọn ti a maa n kẹgan ti a si n ṣaata, bi o tilẹ jẹ wipe wọn n ṣe akitiyan lati yọ ori awọn eniyan akoko wọn sókè; ṣugbọn nikẹyin a maa n ri wipe wọn yẹ fun iyin. Igbimọ alailootọ da Kristi funra Rẹ lẹbi gẹgẹ bi oniṣẹ ibi.ANN 47.6

  Nigba ti o n kọ igbagbọ rẹ silẹ, Jerome fi ọwọ si otitọ idajọ ti o da Huss lebi; o wa sọ wipe oun ti ronupiwada, o si jẹri si iwa ailẹṣẹ ati iwa mimọ ajeriku naa. O sọ pe, “Mo mọ ọ lati igba ọdọmọde rẹ wa.” “O jẹ eniyan rere, oniwa otitọ, ati oniwa mimọ; a da a lẹbi bi o tilẹ jẹ wipe o wa lailẹṣẹ. . . . Emi pẹlu—ani emi ṣetan lati ku: emi ko ni sa fun ijiya ti awọn ẹlẹri èké ati awọn ọta mi pese silẹ fun mi, awọn ti yoo jiyin aiṣododo wọn niwaju Ọlọrun nla Ẹni ti ohunkohun ko le tanjẹ.”ANN 47.7

  Ni dida ara rẹ lẹbi pẹlu bi o ti sẹ otitọ, Jerome tẹsiwaju: “Ninu gbogbo awọn ẹṣẹ ti mo ti ṣẹ lati igba èwe mi wa, ko si eyi ti o wuwo ni ọkan mi ti o si bami lọkan jẹ bi eyi ti mo ṣẹ ninu ile buburu yii, nigba ti mo fara mọ idajọ ẹṣẹ ti a ṣe fun Wyclffe, ati si ajẹriku mimọ, John Huss, ọga mi ati ọrẹ mi. Bẹẹ ni! Mo jẹwọ rẹ lati inu ọkan mi, mo tun sọ wipe, mo wariri pẹlu itiju, nigba ti mo kọ awọn ikọni wọn silẹ nitori ibẹru iku. Nitori naa, mo bẹ . . . Ọlọrun Alagbara lati fi aanu dari awọn ẹṣẹ mi ji mi, ati eyi ni pataki julọ, eyi ti o buru julọ ninu wọn.” O na ika si awọn onidajọ, o wa sọ pẹlu igboya wipe: “Ẹ da Wycliffe ati John Huss lẹbi, ki i ṣe nitori pe wọn yi awọn ikọni ijọ pada, ṣugbọn nitori pe wọn ba iwa ibajẹ ti awọn alufa n wu wi—ìwúga wọn, igberaga wọn, ati gbogbo iwa ọdaran awọn alufa ati adari ijọ. Awọn ohun ti wọn sọ, ti ẹ ko le yipada, ohun naa ni emi ro ti mo si sọ bii ti wọn.”ANN 48.1

  Wọn da ọrọ rẹ duro. Awọn alufa agba wariri pẹlu ibinu, wọn kigbe wipe: “Ẹri wo ni a tun n wa? A ti fi oju ara wa ri ẹlẹkọ odi ti o yigbi julọ!”ANN 48.2

  Laimira nitori awọn ariwo wọnyi, Jerome sọ wipe: “Kini! ṣe ẹ ro wipe mo bẹru lati ku ni? Ẹ fi mi sinu ọgba ẹwọn buburu yii fun odindi ọdun kan, ohun ti o buru ju iku funra rẹ lọ. Iwa ika ti ẹ wu si mi ju eyi ti ẹ le wu si musulumi, Ju tabi abọriṣa lọ, ti ẹran ara mi ti fẹrẹ jẹ kuro lara egungun mi laaye; sibẹ mi o ṣe awawi, nitori awawi ko yẹ ẹni ti ẹmi ati ọkan rẹ ba ṣe giri; ṣugbọn emi ko le sọ bi iyalẹnu mi si iru iwa buburu nla ti a wu si Kristẹni yii ti pọ to.”ANN 48.3

  Iji ibinu tun tu jade, a si yara da Jerome pada sinu ọgba ẹwọn. Sibẹ awọn kan wa ninu igbimọ naa ti ọrọ rẹ wọ lọkan pupọpupọ, ti wọn si fẹ lati gba ẹmi rẹ la. Awọn ijoye ijọ bẹ ẹ wo wọn si rọ ọ lati gba ipinu igbimọ naa. A gbe awọn ohun ti o dara kalẹ siwaju rẹ gẹgẹ bi ẹbun bi o ba le yipada kuro ninu atako rẹ si Romu. Ṣugbọn Jerome duro gbọin bi i ti Oluwa rẹ nigba ti a fi ogo aye yii lọ Ọ.ANN 48.4

  O sọ wipe, “Ẹ fi han mi lati inu Iwe Mimọ ibi ti mo ti ṣe aṣiṣe, emi yoo si kọ ọ silẹ.”ANN 48.5

  Ọkan ninu awọn ti n dan wo sọ wipe, “Iwe Mimọ! ṣe ohun gbogbo ni ki a maa fi dán wo ni? Tani o le ni òye wọn ayafi bi ijọ ba ṣe itumọ wọn?”ANN 48.6

  Jerome dahun wipe, “Ṣe ẹkọ eniyan wa yẹ lati gbagbọ ju iyinrere Olugbala wa lọ ni?” “Pọlu ko gba awọn ti o kọwe si niyanju lati tẹti si ẹkọ eniyan, ṣugbọn o sọ pe, ‘Ẹ wa Iwe Mimọ.’”ANN 48.7

  “Ẹlẹkọ odi! O dun mi wipe mo bẹbẹ pẹlu rẹ fun igba ti o pẹ bayi,” ni a fi da lohun. “Mo ri wipe eṣu ni o n ti ọ lẹyin.”ANN 48.8

  Laipẹ jọjọ, a ṣe idajọ idalẹbi fun. A mu lọ si ibi kan naa ti Huss ti padanu ẹmi rẹ. O n kọrin bi o ti n lọ, oju rẹ mọlẹ pẹlu ayọ ati alaafia. O tẹ oju mọ Kristi, iku ko si ba a lẹru mọ. Nigba ti ẹni ti yoo pa fẹ tan ina si igi naa, o duro si ẹgbẹ rẹ, ajẹriku naa sọ wipe: “Fi igboya wa siwaju; tan ina naa ni iṣoju mi. Bi ẹru ba n ba mi ni, n ki ba ti wa nibi.”ANN 48.9

  Adura ni awọn ọrọ ti o sọ kẹyin bi ina ti n ru bo o mọlẹ. O kigbe, “Oluwa Baba Alagbara, ṣaanu fun mi, ki o si dari awọn ẹṣẹ mi ji mi; nitori pe Iwọ mọ wipe mo fẹran otitọ Rẹ.” Ohùn rẹ dakẹ, ṣugbọn ètè rẹ si n mi ninu adura. Nigba ti ina ṣe iṣẹ rẹ tan, a ko eeru ajẹriku naa, ati ilẹ ibi ti o jo si, bii ti Huss, a da a sinu odo Rhine.ANN 48.10

  Bayi ni awọn olotitọ Ọlọrun ti n tan imọlẹ ṣe ku. Ṣugbọn imọlẹ otitọ ti wọn n polongo—imọlẹ apẹẹrẹ akọni wọn—ni a ko le paku. Bi awọn eniyan ba ti ṣe le ṣe aṣeyọri to lati di oorun lọwọ ninu iṣẹ rẹ, bẹẹ naa ni wọn ṣe le ṣe aṣeyọri lati di ọjọ ti n yọ si ori aye lọwọ.ANN 49.1

  Bi a ti ṣe pa Huss tan ina ibinu ati ibẹru ni Bohemia. Gbogbo orilẹ ede naa ni wọn mọ wipe n ṣe ni o ṣubu si ọwọ arankan awọn alufa ati ẹtan ọba. A sọ wipe o jẹ ẹni ti n fi tọkantọkan kọni ni otitọ, wọn si sọ wipe igbimọ ti o dajọ iku fun jẹbi ẹsun ipaniyan. Awọn eniyan wa n fiye si ikọni re ju ti atẹyinwa lọ. Popu ti paṣe ki a sun awọn iwe Wycliffe nina. A wa ko awọn ti a ko parun sita lati inu ibi ti a ko wọn pamọ si, a si n kọ wọn ni ibamu pẹlu Bibeli, tabi eyikeyi ti awọn eniyan ba le ri, ọpọlọpọ ninu wọn si ti ipa eyi gba igbagbọ ti a tunṣe.ANN 49.2

  Awọn ti wọn pa Huss ko kawọ gbinra lati maa wo ki otitọ o bori. Popu ati ọba parapọ lati pa ẹgbẹ naa run, wọn si dari awọn ọmọ ogun Sigismund wa si Bohemia.ANN 49.3

  Ṣugbọn a gbe oludande kan dide. Ziska, ẹni ti oju rẹ fọ patapata laipẹ ti wọn bẹrẹ ogun, sibẹ ti o jẹ ọkan ninu awọn adari ogun ti wọn muna doko julọ ni akoko rẹ, ni olori awọn ara Bohemia. Wọn gbẹkẹle iranlọwọ Ọlọrun ati ododo ohun ti wọn n ja fun, awọn eniyan wọnyi doju ija kọ ẹgbẹgun ti o lagbara julọ ti a le ko wa ba wọn jagun. Lati igba de igba ni ọba n ko awọn ẹgbẹgun tuntun jọ, ti o si n kọlu Bohemia, ṣugbọn pẹlu itiju ni a fi maa n le wọn pada. Awọn atẹle Huss ni igboya kọja ibẹru iku, kò sì sí ohun ti o le doju kọ wọn. Lẹyin ọdun diẹ ti a bẹrẹ ogun yii, Ziska onigboya ku; ṣugbọn Procopius, ẹni ti o ni igboya ti o si ni ọgbọn bii tire, ti o tun jẹ adari ti o dara ju u lọ ninu awọn ibomiran, ni o gba ipo rẹ.ANN 49.4

  Nigba ti awọn ọta Bohemia mọ wipe jagunjagun afọju ni ti ku, wọn ri gẹgẹ bi anfani ti o dara lati ri ohun gbogbo ti wọn ti padanu gba pada. Popu wa kede ogun ẹsin si awọn atẹle Huss, bi i ti tẹle, ẹgbẹgun nla tun dó ti Bohemia, ṣugbọn ibaku nla ni wọn tun ri. A tun pe ogun ẹsin miran. A ko awọn eniyan, owó, ati ohun ija ogun jọ lati gbogbo orilẹ ede ti wọn ti n ṣe ẹsin ijọ padi ni Europe. Ọgọọrọ awọn eniyan ni wọn lọ si abẹ asia ijọ paadi, ọkan wọn balẹ wipe nikẹyin, wọn yoo fi opin si awọn ẹlẹkọ odi atẹle Huss. Pẹlu idaniloju iṣẹgun, ẹgbẹgun nla yii wa si Bohemia. Awọn eniyan naa ko ara wọn jọ pọ lati le wọn sa. Awọn ẹgbẹgun mejeeji n sunmọ ara wọn titi ti o fi jẹ wipe odo kan ni o la wọn. “Awọn ologun ẹsin ni wọn pọ ju ni iye, ṣugbọn dipo ki wọn rọ wọ inu odo naa, ki wọn si wọya ija pẹlu awọn atẹle Huss ti wọn ti ọna jijin wa baja, n ṣe ni wọn duro ti wọn n wo awọn jagunjagun wọnyi ni idakẹrọrọ.” Lojiji, ipaya nla bọ lu ẹgbẹgun naa. Laiṣe ikọlu kankan, ẹgbẹ nla naa fọ, wọn si tuka afi bi ẹnipe agbara airi ni o tu wọn ka. Awọn ẹgbẹgun atẹle Huss pa wọn lẹgbẹlẹgbẹ, wọn si n le awọn ti wọn sa kuro ni oju ogun lọ, ọpọ ikogun ni o bọ si ọwọ awọn aṣẹgun, ti o fi jẹ wipe, dipo ki ogun naa o sọ wọn di otoṣi, n ṣe ni o sọ awọn Bohemia di ọlọrọ.ANN 49.5

  Ni ọdun diẹ si, labẹ popu miran, a tun bẹrẹ ogun ẹsin miran. Bii ti tẹlẹ, a ko awọn eniyan ati ohun èlò jọ lati gbogbo orilẹ ede ti n ṣe ẹsin ijọ paadi ni Europe. Ileri nla ni a ṣe fun awọn ti yoo ba kopa ninu iṣẹ ti o lewu yii. A ṣe ileri idariji ẹṣẹ ni kikun fun ẹṣẹ ti o ba buru julọ fun gbogbo awọn onija ẹsin. A ṣe ileri ẹbun nla ni ọrun fun gbogbo awọn ti wọn ba ku si ogun, awọn ti wọn ba si ye a gba ọla ati ọrọ ti wọn ba ri loju ogun. A tun ko ẹgbẹgun nla jọ, wọn tun wọ ibodè Bohemia. Awọn ẹgbẹgun atẹle Huss rọra sa pada niwaju wọn, nipa eyi wọn n tan wọn wa si ibi ti o tẹju, ti eyi si jẹ ki wọn o maa ka iṣẹgun ti wọn ti ri na. Nikẹyin ẹgbẹgun Procopius duro, wọn yiju si awọn ọta wọn, wọn tẹsiwaju lati doju ija kọ wọn. Awọn jagunjagun ẹsin wa ri aṣiṣe wọn, wọn duro si ibi agọ wọn, wọn n reti ikọlu. Bi wọn ti gbọ iro ẹgbẹgun ti n bọ, ani ki wọn to ri awọn atẹle Huss, ibẹru bo awọn jagunjagun ẹsin. Awọn ijoye, awọn adari ogun ati awọn ọmọ ogun lasan, sọ ihamọra wọn danu, wọn si tuka si ibikibi ti wọn ba le sa si. Lasan ni aṣoju popu, ti o jẹ adari ogun naa, ṣe lati ko awọn ẹgbẹgun rẹ ti ẹru ba ti wọn si ti tuka jọ. Pẹlu gbogbo wahala rẹ, oun pẹlu sa lọ pẹlu awọn ti wọn sa kuro ni oju ogun. A le wọn patapata, bii ti tẹlẹ, ikogun nla tun bọ si ọwọ awọn aṣẹgun.ANN 49.6

  Bayii ni igba keji, ẹgbẹgun nla ti awọn orilẹ ede ti wọn lagbara julọ ni Europe ran jade, awọn onigboya, ti wọn fẹran ogun, ti a kọ, ti a si pese silẹ fun ogun, sá laisi ikọlu niwaju awọn ti wọn n gbeja orilẹ ede kekere ti ko lagbara. Eyi jẹ ifihan agbara Ọlọrun. Ẹru lati ọrun wa ni o kọlu awọn ti n gbe ija koni yii. Ẹni ti o bi ẹgbẹgun Farao ṣubu sinu Okun Pupa, ti o le awọn ẹgbẹgun Midiani sá kuro niwaju Gidioni ati ọgọrun mẹta eniyan rẹ, ti o bi ẹgbẹgun awọn Asiria onigberaga wó ni aṣalẹ kan ṣoṣo, ni O tun na ọwọ Rẹ lati sẹ agbara aninilara rọ. “Wọn wa ninu ibẹru nla nibi ti ẹru ko si: nitori Ọlọrun ti fọn egungun ẹni ti o dó ti ọ ka: iwọ tì wọn loju nitori Ọlọrun ti ta wọn nu.” O. Dafidi 53:5.ANN 50.1

  Nigba ti awọn adari ijọ aguda ri wipe wọn ko le ṣẹgun pẹlu ipa, wọn wa lo ọgbọn ẹwẹ. Wọn ṣe adehun pẹlu wọn, eyi ti o tan wọn si ọwọ agbara Romu, nigba ti o n fi ara han bi ẹnipe o n fun awọn ara Bohemia ni ominira ẹri ọkan. Awọn ara Bohemia sọ ohun mẹrin ti o le jẹ ki wọn wa ni alaafia pẹlu Romu: wiwaasu Bibeli laisi idiwọ, ki gbogbo ijọ o ni ẹtọ si akara ati waini ara Oluwa, ati lilo ede abinibi wọn ninu ijọsin; yiyọ awọn alufa kuro ninu gbogbo ipo ati ibi aṣẹ ilu; ati nigba ti iwa ọdaran ba ṣẹlẹ, ki ile ẹjọ o ni aṣẹ lori alufa ati ọmọ ijọ bakan naa. Nikẹyin, awọn alaṣẹ ijo paadi “fi ohùn ṣọkan lati gba awọn ohun ti awọn atẹle Huss n wi, ṣugbọn igbimọ—eyi i ni ọba ati popu—ni yoo ni ẹtọ lati ṣe alaye wọn, lati ṣe eyi tumọ si wipe awọn ni wọn a le sọ ohun ti o n wi gan an.” Wọn wa ṣe iwe adehun lori awọn nnkan wọnyi, ohun ti Romu ko le gba pẹlu ipa, o wa ri gba pẹlu ẹtan ati ayinike; nitori nipa ṣiṣe itumọ ifẹ awọn atẹle Huss gẹgẹ bi o ti ṣe si Bibeli, o le yi itumọ wọn pada fun anfani ara rẹ.ANN 50.2

  Ọpọlọpọ awọn ara Bohemia ri wipe o tako ominira wọn, wọn kò si fi ọwọ si iwe naa. Ija ati iyapa wa bẹrẹ, eyi ti o fa rogbodiyan ati itajẹsilẹ laarin wọn. Ninu wahala yii ni Procopius kú si, ti ominira awọn ara Bohemia si bọ sọnu.ANN 50.3

  Sigismund, ẹni ti o fi Huss ati Jerome han wa di ọba Bohemia, bi o tilẹ jẹ wipe o jẹjẹ lati daabobo ẹtọ awọn ara Bohemia, o tẹsiwaju lati fi idi ẹsin popu mulẹ. Ṣugbọn èrè perete ni o ri pẹlu bi o ti ṣe ṣe igbọran si Romu. Ogún ọdun ninu gbesi aye rẹ kun fun wahala ati idamu. Awọn ọmọ ogun rẹ ṣofo, bẹẹ si ni ọrọ rẹ jo tan lori ogun ọlọjọ gbọọrọ ti ko mu èrè wá; lẹyin ti o ṣe akoso fun ọdun kan o ku, o fi ijọba rẹ silẹ ni bèbè ogun abẹle, o si fi orukọ ti a kó ẹgan bá silẹ fun awọn ọmọ rẹ.ANN 50.4

  Rukerudo, ija, ati itajẹsilẹ n tẹsiwaju, awọn ẹgbẹgun ilẹ ajeji tun wa ko ogun ja Bohemia, bẹẹ si ni ija abẹle n ba orilẹ ede naa finra. A si ṣe inunibini kikan si awọn ti wọn si jẹ olootọ si iyinrere.ANN 50.5

  Bi ti awọn ara wọn iṣaaju, nipa ṣiṣe adehun pẹlu Romu, wọn gba awọn aṣiṣe rẹ, awọn ti wọn si jẹ olootọ si igbagbọ igba atijọ parapọ di ijọ miran, wọn pe orukọ ara wọn ni “United Brethren.” Gbogbo awọn eniyan ni wọn sọ ọrọ buburu si wọn nitori eyi. Sibẹ wọn si duro ṣinṣin. O di dandan fun wọn lati wa aabo ninu igbó ati ihò ilẹ, sibẹ wọn si n pejọ pọ lati ka ọrọ Ọlọrun ati lati jumọ pọ jọsin Rẹ.ANN 50.6

  Nipasẹ awọn iranṣẹ ti a ran jade lọ si awọn orilẹ ede miran ni bonkẹlẹ, wọn mọ wipe nihin, lọhun, “awọn atẹle otitọ ti wọn farasin wa, diẹ ni ilu yii, diẹ ni ilu ọhun, ti a n ṣe inunibini si bii ti wọn; ati pe ijọ atijọ wa ni aarin awọn oke Alps, ti o duro lori ipilẹ Iwe Mimọ, ti o si n tako awọn iwa ibajẹ ẹsin ibọriṣa Romu.” Wọn gba imọ yii pẹlu ayọ nla, wọn si bẹrẹ ifọrọwerọ pẹlu awọn Kristẹni Waldenses.ANN 50.7

  Pẹlu iduroṣinṣin si iyinrere, awọn ara Bohemia la aṣalẹ inunibini kọja, ninu okunkun ti o dudu julọ, wọn n sọna bi awọn ti wọn n wọna fun owurọ. “A ṣe ipinu lori wọn ni ọjọ buburu, ṣugbọn . . . wọn ranti awọn ọrọ ti Huss kọkọ sọ, ti Jerome tun tun sọ, wipe ọgọrun ọdun yoo kọja ki oju o to mọ. Eyi dabi ọrọ ti Josẹfu sọ fun awọn ẹya ti wọn wa ni igbekun wipe: ‘Mo n ku lọ, Ọlọrun yoo si bẹ yin wo ni tootọ, yoo si mu yin jade,’ ni eti awọn ara Tabori [awọn atẹle Huss]. “Opin ọrundun karundinlogun ri bí awọn ijọ Ara ti n pọ si bi o tilẹ jẹ wipe ko yara kankan. Lootọ a n fi iya jẹ wọn, ṣugbọn wọn ni isinmi diẹ. Ni ibẹrẹ ọrundun kẹrindinlogun, ijọ wọn ti to igba (200) ni Bohemia ati Moravia.” “Bayi ni awọn aṣẹku ti wọn sa asala kuro ninu ibinu apanirun ti ida ati ina ṣe ṣe ori ire lati ri bi ọjọ ti Huss sọ tẹlẹ ṣe n yọ.”ANN 50.8

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents