Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸRINDINLỌGBỌN—IṢẸ ATUNṢE

    Iṣẹ atunṣe ọjọ Isinmi ti a yoo ṣe ni ọjọ ikẹyin ni a sẹ tẹlẹ ninu asọtẹlẹ Aisaya: “Bayii ni Oluwa wi, Ẹ pa idajọ mọ, ki ẹ si ṣe ododo: nitori ti igbala Mi sunmọ etile, ati lati fi ododo Mi han. Ibukun ni fun ẹni naa ti o ṣe eyi, ati ọmọ eniyan naa ti o ṣe e; ti o pa ọjọ Isinmi Mi mọ lati maṣe ba a jẹ, ti o si pa ọwọ rẹ mọ kuro ninu ṣiṣe ibi.” “Ọmọ ajeji ti o so ara rẹ pọ mọ Oluwa, lati sin In, ati lati fẹran orukọ Oluwa, lati jẹ iranṣẹ Rẹ, ẹnikẹni ti o ba yẹ ẹṣẹ rẹ kuro ninu ọjọ Isinmi lati ba a jẹ, ti o si di majẹmu Mi mu; ani oun ni Emi yoo mu wa si oke mimọ Mi, Emi yoo si mu inu rẹ dun ninu ile adura Mi.” Aisaya 56:1, 2, 6, 7.ANN 200.1

    Awọn ọrọ wọnyi ni i ṣe pẹlu akoko Kristẹni gẹgẹ bi o ti fi ara han: “Oluwa Ọlọrun Ẹni ti o ṣa atanu Israeli jọ wi pe, Emi yoo ṣa awọn miran jọ sọdọ rẹ, pẹlu awọn ti a ti ṣa jọ sọdọ rẹ.” Ẹsẹ 8. Nibi ni a ti ṣe asọtẹlẹ kiko awọn keferi wọle nipasẹ iyinrere. A ṣi ṣe ibukun sori awọn ti yoo bọwọ fun ọjọ Isinmi nigba naa. Ni bayii ojuṣe ofin kẹrin gun lọ kọja agbelebu, ajinde, igoke re ọrun Kristi, titi fi di akoko ti awọn iranṣẹ Rẹ yoo waasu iṣẹ iranṣẹ iroyin ayọ si gbogbo orilẹ ede.ANN 200.2

    Oluwa pa woli kan naa laṣẹ wipe: “Di ẹri naa, fi edidi di ofin naa laarin awọn ọmọlẹyin Mi.” Aisaya 8:16. A ri edidi ofin Ọlọrun ninu ofin kẹrin. Eyi nikan ni aarin awọn mẹwa, ni o sọ orukọ ati àpèlé Afunnilofin. O pe E ni Ẹlẹda ọrun ati aye nipa eyi o fihan wipe O ni ẹtọ si ijọsin ju ohunkohun lọ. Laisi ilana yii, ko si ohunkohun ninu Ofin Mẹwa lati ṣe afihan aṣe ẹni ti o funni ni ofin. Nigba ti agbara ijọ padi yi ọjọ Isinmi pada, a mu edidi kuro lara ofin. A pe awọn ọmọlẹyin Jesu lati da pada nipa gbigbe ọjọ Isinmi ti ofin kẹrin ga si ipo ti o tọ si gẹgẹ bi ohun iranti Ẹlẹda ati ami aṣẹ Rẹ.ANN 200.3

    “Si ofin ati si ẹri.” Nigba ti awọn ikọni ati ironu ti wọn tako ara wọn wọpọ, ofin Ọlọrun jẹ odiwọn ti ko baku eyi ti a nilati fi dan gbogbo ero, ikọni ati ironu wo. Woli naa sọ pe: “Bi wọn ko ba sọrọ gẹgẹ bi ọrọ yii, nitori pe ko si imọlẹ ninu wọn ni.” Ẹsẹ 20.ANN 200.4

    Lẹẹkan si a paṣẹ: “Kigbe kikan, maṣe da sí, gbe ohun rẹ soke bii kakaki, ki o si fi irekọja awọn eniyan Mi han wọn, ati ile Jakobu ẹṣẹ wọn.” Ki i ṣe aye buburu yii, bikoṣe awọn ti Ọlọrun pe ni “eniyan Mi” ni a nilati bawi fun irekọja wọn. O tẹsiwaju: “Sibẹ wọn n wa ni ojoojumọ, wọn si n fẹ lati mọ ọna Mi gẹgẹ bi orilẹ ede ti n ṣe ododo, ti ko kọ agbekalẹ Ọlọrun wọn silẹ.” Aisaya 58:1, 2. Nibi ni a ti ṣe alaye ẹgbẹ kan ti wọn ro wipe wọn jẹ olododo ti o si dabi ẹnipe wọn ni ifẹ nla si iṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn ibawi lile ti o lẹru Ẹni ti n yẹ ọkan wo fihan wipe wọn n tẹ ilana mimọ loju.ANN 200.5

    Bayii woli naa tọka si ilana ti wọn kọ silẹ: “Ẹyin yoo gbe ipilẹ ọjọ pipẹ ro; a yoo si pe yin ni olutun ibi ẹya kọ, olumupada ọna nì lati maa gbe inu rẹ. Bi iwọ ba yi ẹsẹ rẹ pada kuro ninu ọjọ Isinmi lati ṣe afẹ rẹ ni ọjọ mimọ Mi; ti o si pe ọjọ Isinmi Mi ni adun, ọjọ mimọ Oluwa, ọlọwọ; ti iwọ si bọwọ fun, ti o ko rin ni ọna ara rẹ, tabi wa afẹ rẹ tabi sọ ọrọ ara rẹ: nigba naa ni iwọ yoo ni inu didun ninu Oluwa.” Ẹsẹ 12—14. Asọtẹlẹ yii ni itumọ ni akoko wa yii pẹlu. A da alafo sinu ofin Ọlọrun nigba ti agbara Romu yi ọjọ Isinmi pada. Ṣugbọn akoko ti to lati tun agbekalẹ mimọ naa ṣe. A nilati tun alafo naa kọ ki a si gbe ipilẹ ọlọjọ gbọọrọ naa ro.ANN 200.6

    Ẹlẹda yaa si mimọ pẹlu isinmi ati ibukun, Adamu pa ọjọ Isinmi mọ nigba ti o wa ni ailẹṣẹ ni Edẹni mimọ; o pa a mọ nigba ti o ronupiwada lẹyin ti o ṣubu, nigba ti a le kuro ninu ile alayọ rẹ. Gbogbo awọn baba nla ni wọn pa a mọ, lati ori Abeli titi de ori Noah olododo, de ori Abrahamu, titi de Jakọbu. Nigba ti awọn ti a yan wa ninu igbekun ni Ijibiti, ọpọlọpọ wọn, laarin ẹsin ibọriṣa ti o gbilẹ kan, padanu imọ wọn nipa ofin Ọlọrun; ṣugbọn nigba ti Oluwa gba Israeli silẹ, O kede ofin Rẹ si awujọ wọn ni ọna ti o banilẹru, ki wọn le mọ ifẹ Rẹ, ati ki wọn le bẹru Rẹ, ki wọn si ṣe igbọran si titi lae.ANN 200.7

    Lati ọjọ naa lọ titi di akoko yii imọ ofin Ọlọrun ti wa ninu aye, ti a si ti n pa ọjọ Isinmi ofin kẹrin mọ. Bi o tilẹ jẹ wipe “ẹni ẹṣẹ” ṣe aṣeyọri ninu titẹ ọjọ mimọ Ọlọrun labẹ ẹsẹ rẹ, sibẹ ani ni akoko ijẹgaba rẹ, awọn olootọ wa ninu ibi kọlọfin wọn ti wọn ti n bọwọ fun. Lati akoko Atunṣe, awọn kan wà lati iran de iran ti wọn n pa a mọ. A n jẹri latigbadegba nipa iwalaaye titi lae ofin Ọlọrun ati ojuṣe mimọ ti ọjọ Isinmi ti ìgbà ti a dá aye, bi o tilẹ jẹ wipe eyi saba maa n waye laarin ẹgan ati inunibini.ANN 201.1

    Awọn otitọ wọnyi, ti a gbekalẹ ninu Ifihan 14 ni asopọ pẹlu “iyinrere ainipẹkun” yoo ya ijọ Kristi sọtọ ni akoko ifarahan Rẹ. Nitori latari ikede iṣẹ iranṣẹ onipelemẹta naa a kede wipe: “Iwọnyi ni awọn ti wọn pa ofin Ọlọrun ati igbagbọ Jesu mọ.” Iṣẹ iranṣẹ yii ni eyi ti o kẹyin ti a o funni ki Oluwa o to wa. Lọgan lẹyin ti a ṣe ikede rẹ, woli naa ri Ọmọ eniyan, ti O n bọwa ninu ogo lati wa kore aye.ANN 201.2

    Awọn ti wọn gba imọlẹ nipa ibi mimọ ati iwatiti lae ofin Ọlọrun kun fun ayọ ati iyanu bi wọn ti ri ẹwa ati irẹpọ agbekalẹ otitọ ti o ṣi si iye wọn. Wọn fẹ ki imọlẹ ti o ṣe iyebiye si wọn o tan si gbogbo Kristẹni, wọn si gbagbọ wipe tayọtayọ ni wọn a fi gba a. Ṣugbọn ọpọlọpọ ti wọn pe ara wọn ni atẹle Kristi ko ni gba otitọ ti yoo mu wọn wa ni iṣọta pẹlu aye. Igbọran si ofin kẹrin nilo irubọ ti ọpọlọpọ ko le ṣe.ANN 201.3

    Bi a ti n ṣe alaye ojuṣe ti ọjọ isinmi, ọpọlọpọ ni wọn ronu ni ọna ti aye. Wọn sọ pe: “A ti n pa ọjọ Sọnde mọ lati ẹyin wa, awọn baba wa pa a mọ, ọpọlọpọ awọn eniyan rere ti wọn jẹ ọlufọkansin ni wọn ku pẹlu ayọ nigba ti wọn n pa a mọ. Ti wọn ba tọna, awa naa tọna pẹlu. Pipa ọjọ Isinmi tuntun yii mọ yoo mu ki ọpọlọpọ wa ni airẹpọ pẹlu aye, a ki yoo si ni ipa lori wọn. Ki ni ẹgbẹ kekere ti n pa ọjọ keje mọ ni ireti lati ṣe laarin ọgọọrọ ninu aye ti wọn n pa ọjọ Sọnde mọ?” Pẹlu iru iṣọwọsọrọ bayi ni awọn Ju fi gbiyanju lati da ara wọn lare nigba ti wọn kọ Kristi silẹ. Ọlọrun gba awọn baba wọn pẹlu ọrẹ ẹbọ wọn, ki lo wa di awọn ọmọ lọwọ lati ri igbala nipa titẹle ilana kan naa? Bẹẹ gẹgẹ ni akoko Luther awọn atẹle popu ronu wipe awọn Kristẹni tootọ ku ninu igbagbọ Katoliki, nitori naa ẹsin naa tó fun igbala. Iru iṣọwọronu yii yoo ṣe idena gbogbo idagbasoke igbagbọ ẹsin ati iṣesi.ANN 201.4

    Ọpọ sọ wipe pipa ọjọ Sọnde mọ jẹ ikọni ti a fi idi rẹ mulẹ ati iṣesi ti ijọ ti tan kalẹ fun ọpọlọpọ ọdun. Ni atako si iṣọwọronu yii, a ri wipe ọjọ Isinmi pẹlu iṣọwọpaamọ jẹ eyi ti o pẹ ti o si tan kalẹ, o pẹ ani bi aye ti pẹ funra rẹ, o si ni ifọwọsi awọn angẹli ati ti Ọlọrun. Nigba ti a ṣe ipilẹ aye, nigba ti awọn irawọ owurọ jumọ kọrin papọ, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun kigbe fun ayọ, nigba naa ni a ṣe ipilẹ ọjọ Isinmi. Jobu 38:6, 7; Jẹnẹsisi 2:1—3. Agbekalẹ yii nilo ibọwọfun wa; ki i ṣe aṣẹ eniyan ni o gbe kalẹ, ko si sinmi lori ikọni eniyan. Arugbo Ọjọ ni o fi idi rẹ lelẹ, ọrọ ayeraye Rẹ ni o si pa a laṣẹ.ANN 201.5

    Bi a ti n pe akiyesi awọn eniyan si koko ọrọ atunṣe nipa ọjọ isinmi, awọn alufa ti wọn gbajugbaja yi ọrọ Ọlọrun pada, wọn ṣe itumọ eri rẹ ni ọna ti o mu ki ẹni ti o ba fẹ mọ si dakẹ. Awọn ti wọn ko wa inu Iwe Mimọ funra wọn fara mọ lati gba idahun ti o wa ni ibamu pẹlu ifẹ ọkan wọn. Nipa ariyanjiyan, ọgbọn ẹwẹ, aṣa awọn Baba, ati aṣẹ ijọ, ọpọlọpọ gbiyanju lati bi otitọ ṣubu. Awọn ti wọn n kede rẹ ṣi yi si Bibeli lati fi idi ẹsẹ ofin kẹrin mulẹ. Awọn onirẹlẹ eniyan, ti wọn kun fun ọrọ otitọ nikan, duro lati kọju ija si atako awọn ọmọwe, wọn si n ri pẹlu iyalẹnu ati ibinu wipe ète wọn ko ni agbara lati tako ironu ti o ja geere awọn ti wọn kun fun Iwe Mimọ dipo ọgbọn arekereke ti o wa ni ile ẹkọ.ANN 201.6

    Nitori ti wọn ko ni ẹri Bibeli ni ọdọ wọn, ọpọlọpọ laikaarẹ n sọ wipe—wọn ti gbagbe bi wọn ti lo iru ọrọ kan naa lati tako Kristi ati awọn apostoli Rẹ: “Kilode ti awọn eniyan nla wa ko fi ni oye nipa ọjọ Isinmi yii? Ṣugbọn awọn perete ni wọn gba a gbọ bii ti yin. Ẹ kole tọna nigba ti gbogbo awọn ọmọwe aye a wa ṣina.”ANN 201.7

    Eniyan ko nilo ju ki o sọ nipa awọn ikọni Iwe Mimọ ati itan iṣesi Oluwa pẹlu awọn eniyan Rẹ latẹyinwa lati le tako iṣọwọsọrọ yii. Ọlọrun n ṣiṣẹ nipasẹ awọn ti wọn tẹti si ti wọn si n ṣe ohun ti O wi, awọn ti o jẹ wipe, bi o ba nilo bẹẹ, wọn a sọ otitọ ti ko dun mọni leti, awọn ti wọn ko bẹru lati bá ẹṣẹ ti o gbilẹ wi. Idi ti ki I fi saba maa n yan awọn ọmọwe ati awọn ti wọn ni ipo giga lati jẹ aṣaaju ninu ẹgbẹ alatunṣe ni wipe wọn gbẹkẹle ohun ti wọn gbagbọ, ninu ero wọn ati ilana wọn nipa Ọlọrun, wọn ko si ri wipe wọn nilo ẹkọ lati ọdọ Ọlọrun. Awọn ti wọn ni ibaṣepọ timọtimọ pẹlu Orisun ọgbọn nikan ni wọn le ni oye tabi ṣe alaye Iwe Mimọ. Awọn ti wọn ni ẹkọ kekere ni ile iwe ni a saba maa n pe lati ṣe ikede otitọ, ki i ṣe nitori pe wọn ko mọwe, ṣugbọn nitori pe wọn ko ri ara wọn bi ẹni ti o to tan, ti Ọlọrun ko le kọ. Wọn kẹkọ ninu ile ẹkọ Kristi, irẹlẹ ati igbọran wọn si sọ wọn di nla. Ni fifun wọn ni imọ otitọ Rẹ, Ọlọrun bọwọ fun wọn ni ọna ti o jẹ wipe ọwọ aye ati titobi eniyan jẹ asan ni afiwe.ANN 201.8

    Ọpọlọpọ awọn Onireti kọ otitọ nipa ibi mimọ ati ofin Ọlọrun silẹ, ọpọlọpọ si kọ igbagbọ wọn ninu ẹgbẹ ipadabọ silẹ, wọn gba ero ti kò peye tó, ti wọn tako ara wọn nipa iṣẹ naa. Awọn miran bọ sinu aṣiṣe lati maa da akoko fun wiwa Kristi. Imọlẹ ti o wa n tan bayii lori koko ọrọ ibi mimọ i ba fihan wọn wipe ko si akoko isọtẹlẹ ti o lọ de akoko ipadabọ lẹẹkeji mọ; wipe a ko sọ asọtẹlẹ nipa akoko gan an ti wiwa yii yoo jẹ. Ṣugbọn ni yiyi kuro ninu imọlẹ, wọn tẹsiwaju lati da akoko fun Oluwa lati wá, bẹẹ si ni wọn n ri ijakulẹ.ANN 202.1

    Nigba ti awọn ijọ Tẹsalonika gba ero ti ko tọ nipa wiwa Kristi, apostoli Pọlu gba wọn niyanju lati fi ọrọ Ọlọrun dan ireti ati afojusun wọn wo daradara. O sọ fun wọn awọn asọtẹlẹ ti wọn ṣe afihan awọn iṣẹlẹ ti yoo ṣẹlẹ ki Kristi o to wa, o si fihan wipe wọn ko ni idi lati reti Rẹ ni akoko wọn. “Ẹ maṣe jẹ ki ẹnikẹni o tan yin jẹ ni ọnakọna.” (2 Tẹsalonika 2:3), ni ọrọ ikilọ rẹ. Bi wọn ba wa ni ireti ti Iwe Mimọ ko fi ọwọ si, wọn a ṣe ohun ti ko tọna; ijakulẹ a mu ki awọn alaigbagbọ o kẹgan wọn, wọn a si wa ninu ewu ati fi ara silẹ fun ijakulẹ, wọn a wa ninu idanwo lati ṣe iyemeji nipa awọn otitọ ti wọn ṣe pataki fun igbala wọn. Iyanju apostoli naa si awọn ara Tẹsalonika ní ẹkọ nla fun awọn ti wọn wa laaye ni akoko ikẹyin. Ọpọ awọn Onireti ni wọn ro wipe ayafi bi wọn ba gbe igbagbọ wọn le akoko kan pato fun wiwa Oluwa, wọn ko ni ni itara to bẹẹni wọn ko ni mura ninu iṣẹ imurasilẹ. Ṣugbọn bi ireti wọn ti n ru soke, ti o si n pade ijakulẹ, igbagbọ wọn a mi debi pe ko ni ṣe e ṣe fun wọn mọ lati gba awọn otitọ nla ti isọtẹlẹ.ANN 202.2

    Ọlọrun ni o ṣe eto iwaasu nipa akoko kan pato fun idajọ ni igba iwaasu iṣẹ iranṣẹ akoko. Iṣiro akoko isọtẹlẹ eyi ti iṣẹ iranṣẹ naa duro le lori, ti o fi si opin 2300 ọjọ ni akoko ikore 1844, duro ni aiyẹ. Akitiyan latigbadegba lati ri ọjọ tuntun fun ibẹrẹ ati opin akoko isọtẹlẹ ati iṣọwọronu ti ko peye ti wọn nilo lati fi idi awọn ọrọ wọnyi mulẹ yi ọkan ọpọlọpọ kuro ninu otitọ akoko yii, bẹẹ ni o tun ko ẹgan ba gbogbo akitiyan lati ṣe alaye awọn asọtẹlẹ. Bi wọn ba ṣe n da akoko fun ipadabọ lẹẹkeji to, ati bi a ba ṣe fi kọni to, bẹẹ ni o ṣe tẹ erongba Satani lọrun to. Nigba ti akoko naa kọja, o ru ẹsin ati ẹgan awọn ti n kede rẹ soke, bayi ni o ṣe ko ẹgan ba ẹgbẹ ipadabọ nla ti 1843 ati 1844. Awọn ti wọn tẹsiwaju ninu aṣiṣe yii yoo mu ọjọ ti o lọ jinna réré gẹgẹ bi akoko wiwa Kristi. Bayii ni wọn a ṣe ni ifọkanbalẹ ninu igbẹkẹle asan wọn, ọpọlọpọ ni yoo si wa ninu itanjẹ titi ti a fi pẹ ju.ANN 202.3

    Itan Israeli atijọ jẹ apejuwe ti o yanilẹnu fun iriri ẹgbẹ Onireti. Ọlọrun dari awọn eniyan Rẹ ninu ẹgbẹ Onireti, ani bi O ti dari awọn ọmọ Israeli lati Ijibiti wa. Ninu ijakulẹ nla a dan igbagbọ wọn wo bi a ti dan awọn Heberu wo ni okun pupa. Bi o ba ṣe wipe wọn gbẹkẹle ọwọ ti o ti n dari wọn ninu iriri wọn latẹyinwa ni, wọn i ba ri igbala Ọlọrun. Bi o ba ṣe wipe gbogbo awọn ti wọn ṣiṣẹ pẹlu iṣọkan ninu iṣẹ 1844 ni wọn gba iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta, ti wọn si waasu rẹ ninu agbara Ẹmi Mimọ ni, Oluwa i ba ṣe iyanu pẹlu akitiyan wọn. Igbi imọlẹ i ba tan si ori aye. Ni ọdun diẹ sẹyin, a ba ti ṣe ikilọ fun awọn olugbe aye, iṣẹ aṣekagba i ba ti pari, Kristi i ba si ti wa fun irapada awọn eniyan Rẹ.ANN 202.4

    Ki i ṣe ifẹ Ọlọrun ni ki Israeli o rin ninu aginju fun ogoji ọdun; O nifẹ lati dari wọn taara lọ si ilẹ Kenaani ki O si fi ẹsẹ wọn mulẹ nibẹ gẹgẹ bi eniyan mimọ, alayọ. Ṣugbọn “wọn ko le wọ ibẹ nitori aigbagbọ.” Heberu 3:19. Nitori ipẹyinda ati ifasẹyin wọn, wọn ṣegbe ninu aṣalẹ, a si gbe awọn miran dide lati wọ ilẹ ileri. Ni ọna kan naa, ki i ṣe ifẹ Ọlọrun ki wiwa Kristi o pẹ bayii, ki awọn eniyan Rẹ o ṣi wa ninu aye ẹṣẹ ati ibanujẹ fun ọdun pipẹ. Ṣugbọn aigbagbọ ni o pin wọn niya kuro ni ọdọ Ọlọrun. Bi wọn ti kọ lati ṣe iṣẹ ti O fun wọn, a gbe awọn miran dide lati kede iṣẹ iranṣẹ naa. Ninu aanu si araye, Jesu fa wiwa Rẹ sẹyin, ki ẹlẹṣẹ le ni anfani lati gbọ ikilọ naa ki wọn si ri aabo ninu Rẹ ki a to tu ibinu Ọlọrun sita.ANN 202.5

    Bayi gẹgẹ bi o ti wa ni iṣaaju iwaasu otitọ ti yoo ba ẹṣẹ ati aṣiṣe wi yoo ru atako soke. “Gbogbo ẹni ti n wuwa ibi korira imọlẹ, bẹẹ ni ki yoo wa si imọlẹ ki a ma baa ba iṣẹ rẹ wi.” Johanu 3:20. Bi awọn eniyan ti ri wipe wọn ko le gbe ara wọn lẹyin pẹlu Iwe Mimọ, ọpọlọpọ pinu lati maṣe naani ewu ti o wa nibẹ, pẹlu ẹmi arankan, wọn ṣe atako iwa ati erongba awọn ti wọn duro lati gbeja otitọ, ti awọn eniyan ko fẹran. Ohun kan naa ni o n ṣẹlẹ ni gbogbo igba. A sọ wipe Elija ni ẹni ti n yọ Israeli lẹnu, Jeremaya jẹ ọdalẹ, Pọlu jẹ ẹni ti n ba tẹmpili jẹ. Lati ọjọ naa lọ titi di oni, a si maa n pe awọn ti wọn ba maa ṣe igbọran si otitọ ni ọlọtẹ, ẹlẹkọ eke, ati oluyapa. Ọpọlọpọ ti aigbagbọ wọn pọ to bẹẹ gẹẹ ti wọn ko ni igbagbọ ninu ọrọ isọtẹlẹ ti o daniloju, yoo gba laiṣe aiwadi ẹsunkẹsun ti a ba fi kan awọn ti yoo ba ẹṣẹ ti gbogbo eniyan fẹran wi. Iru ẹmi yii yoo tubọ maa pọ si. Bibeli si sọ ọ ni gbangba wipe akoko n sunmọ etile ti ofin ilu yoo tako ofin Ọlọrun gidigidi debi wipe ẹnikẹni ti yoo ba ṣe igbọran si gbogbo ofin Ọlọrun yoo ni igboya lati gba ẹgan ati itiju bi aṣebi.ANN 203.1

    Pẹlu eleyi, kini ojuṣe ojiṣẹ otitọ? Ṣe ki o sọ wipe a ko gbọdọ waasu otitọ ni, nigba ti o jẹ wipe ko le ṣe ju lati mu ki awọn eniyan o yago fun tabi ki wọn ṣe atako rẹ lọ? Rara; ko ni idi kankan lati maṣe waasu ẹri ọrọ Ọlọrun nitori ti o fa atako ju bi awọn Alatunṣe iṣaaju ti ni lọ. A ṣe akọsilẹ ijẹwọ igbagbọ tí awọn eniyan mimọ ati ajẹriku ṣe fun anfani awọn iran ti n bọ lẹyin. Awọn apẹẹrẹ ti wọn duro titi lae, fun iwa mimọ ati iduro ṣinṣin wa lati fun awọn ti a pe bayi lati duro gẹgẹ bi ajẹri fun Ọlọrun ni igboya. Wọn gba oore ọfẹ ati otitọ, ki i ṣe fun ara wọn nikan, ṣugbọn nipasẹ wọn, ki imọ Ọlọrun le tan ka ilẹ aye. Njẹ Ọlọrun fun awọn iranṣẹ Rẹ ni imọlẹ ni akoko yii bi? Nitori naa ki wọn jẹ ki o tan sinu aye.ANN 203.2

    Ni igba atijọ Oluwa sọ fun ẹnikan ti o sọrọ ni orukọ Rẹ wipe: “Ile Israeli ki yoo tẹti si ọ; nitori ti wọn ki yoo gbọ Mi.” Sibẹ, O sọ pe: “Iwọ yoo sọ ọrọ Mi fun wọn, boya wọn yoo gbọ, tabi boya wọn ki yoo gbọ.” Isikiẹli 3:7; 2:7. A pa aṣẹ yii fun awọn iranṣẹ Ọlọrun ni akoko yii pe: “Gbe ohùn soke bi kakaki, ki o si fi irekọja awọn eniyan Mi han wọn, ati ẹṣẹ ile Israeli.”ANN 203.3

    Ni bi anfani rẹ ba ti pọ to, gbogbo eniyan ti wọn gba imọlẹ otitọ ni wọn ni ojuṣe ọlọwọ ati ẹlẹru kan naa bii ti woli Israeli ẹni ti ọrọ Ọlọrun wa ba nì wipe: “Ọmọ eniyan, Mo ti yan ọ ni alore si ile Israeli; nitori naa iwọ yoo gbọ ọrọ ni ẹnu Mi, iwọ yoo si kì wọn nilọ fun Mi. Nigba ti mo ba sọ fun ẹlẹṣẹ, Iwọ ẹlẹṣẹ, kiku ni iwọ yoo ku; bi iwọ ko ba sọrọ lati ki ẹlẹṣẹ naa nilọ kuro ni ọna rẹ, ẹlẹṣẹ naa yoo ku ninu ẹṣẹ rẹ; ṣugbọn ẹjẹ rẹ ni Emi yoo beere ni ọwọ rẹ. Ṣugbọn bi iwọ ba ki ẹlẹṣẹ naa nilọ lati yipada kuro ninu ọna rẹ, bi ko ba yipada kuro ninu ọna rẹ, yoo ku ninu ẹṣẹ rẹ, ṣugbọn iwọ ti gba ọkan rẹ là.” Isikiẹli 33:7—9.ANN 203.4

    Idiwọ nla ti o ba gbigba ati wiwaasu otitọ ni wipe o n mu inira ati ẹgan wa. Eyi nikan ni atako si otitọ ti awọn ti n waasu rẹ koi tii le dahun. Ṣugbọn eleyi ko le di atẹle Kristi tootọ lọwọ. Awọn wọnyi ko ni duro titi ti gbogbo eniyan a fi gba otitọ. Nigba ti wọn mọ ojuṣe wọn, wọn mọọmọ gba agbelebu, pẹlu Pọlu apostoli wọn ri “inira kekere wa, ti o wa fun igba diẹ ṣiṣẹ ogo ti o tayọ jọjọ, ti o si wuwo fun wa,” pẹlu ẹni ogbó ni, “wọn ri ẹgan Kristi gẹgẹ bi ọrọ ti o pọ ju iṣura Ijibiti lọ.” 2 Kọrintin 4:17; Heberu 11:26.ANN 203.5

    Iru iṣẹ ti o ba wu ki wọn maa ṣe, awọn olujọsin aye ninu ọkan wọn nikan ni wọn maa n wuwa nitori ayika dipo nitori ohun ti wọn gbagbọ ninu ọrọ ẹsin. A yan lati ṣe ohun ti o tọ nitori ti o tọ, a yoo si fi atubọtan rẹ lé Ọlọrun lọwọ. Aye ri gbogbo iṣẹ atunṣe ti wọn n ṣe ninu rẹ nitori awọn ti wọn wuwa nitori igbagbọ ọkan wọn, ti wọn nigbagbọ ti wọn tun nigboya. Iṣẹ atunṣe fun akoko yii yoo tẹsiwaju nipasẹ iru awọn eniyan wọnyi.ANN 203.6

    Bayii ni Oluwa wi: “Ẹ gbọ temi ẹyin ti o mọ ododo, ẹyin eniyan ti o ni ofin Mi ninu ọkan yin; ẹ maṣe bẹru ẹgan eniyan, ki ẹ ma si ṣe foya ẹgan. Nitori kokoro yoo jẹ wọn bi ẹwu, ìdin yoo si jẹ wọn bi owu: ṣugbọn ododo Mi yoo wa titi lae, ati igbala Mi lati iran de iran.” Aisaya 5:7, 8.ANN 204.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents