Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸRINLELOGUN—NINU IBI MIMỌ JULỌ

    Koko ọrọ ibi mimọ ni kọkọrọ ti o tu aṣiri ijakulẹ 1844. O ṣi ilana otitọ ti o peye silẹ kedere, eyi ti o wa ni asopọ ati irẹpọ ti o fihan wipe Ọlọrun ni o dari ẹgbẹ ipadabọ nla ti o si n fi ojuṣe ti akoko yii han bi o ti n fi ipo ati iṣẹ awọn eniyan Rẹ han. Gẹgẹ bi awọn ọmọ ẹyin Jesu lẹyin aṣalẹ kikoro ti iporuuru ọkan ati ijakulẹ, “inu wọn dun lati ri Oluwa wọn,” bẹẹ gẹgẹ ni inu awọn ti wọn n fi igbagbọ wọna fun wiwa Rẹ lẹẹkeji dun. Wọn ti n reti Rẹ lati farahan ninu ogo lati fun awọn iranṣẹ Rẹ ni èrè. Bi ireti wọn ti jakulẹ, wọn gbe oju kuro lọdọ Jesu, wọn kigbe pẹlu Maria ni iboji: “Wọn ti gbe Oluwa mi lọ, n o si mọ ibi ti wọn gbe tẹ Ẹ si.” Bayi ní ibi mimọ julọ wọn tun ri Olu Alufa alaanu wọn lẹẹkansi, ti yoo farahan laipẹ gẹgẹ bi ọba ati olugbala wọn. Imọlẹ lati inu ibi mimọ tan imọlẹ si ohun ti o ti ṣẹlẹ sẹyin, ohun ti o n ṣẹlẹ lọwọlọwọ ati ọjọ iwaju. Wọn mọ wipe, bi i ti awọn ọmọ ẹyin akọkọ, awọn paapa kuna lati ni oye iṣẹ iranṣẹ ti wọn n waasu rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe o tọna patapata. Ni wiwaasu rẹ wọn mu erongba Ọlọrun ṣẹ, iṣẹ wọn ko si jasi lasan ninu Oluwa. A “tun wọn bi sinu ireti ti n bẹ laaye,” wọn yọ “pẹlu ayọ ti o kun fun ogo ti ko ṣe e fẹnusọ.”ANN 188.1

    Asọtẹlẹ Danieli 8:14, “Titi di 2300 ọjọ; nigba naa ni a o ya ibi mimọ si mimọ;” ati iṣẹ iranṣẹ angẹli akọkọ, “Bẹru Ọlọrun ki ẹ si fi ogo fun; nitori ti wakati idajọ Rẹ de,” tọka si iṣẹ iranṣẹ Kristi ninu ibi mimọ julọ, si idajọ iyẹwewo, ki i si i ṣe si wiwa Kristi fun irapada awọn eniyan Rẹ ati iparun awọn eniyan buburu. Aṣiṣe naa ko si ninu iṣọwọka akoko isọtẹlẹ, ṣugbọn ninu iṣẹlẹ ti yoo ṣẹlẹ ni opin 2300 ọjọ. Aṣiṣe yii ni o fa ijakulẹ awọn onigbagbọ, sibẹ ohun gbogbo ti asọtẹlẹ yii sọ tẹlẹ, ati ohun gbogbo ti Iwe Mimọ gba wọn laaye lati reti ni wọn wa si imuṣẹ. Ni akoko gan an ti wọn n kẹdun fun ijakulẹ ireti wọn, iṣẹlẹ ti iṣẹ iranṣẹ yii sọ tẹlẹ n wa si imuṣẹ, eyi ti o gbọdọ ṣẹlẹ ki Oluwa to wa lati fi ẹbun fun awọn iranṣẹ Rẹ.ANN 188.2

    Kristi lọ, kii ṣe sinu aye, bi wọn ti n reti Rẹ, ṣugbọn bi apẹẹrẹ ti ṣe afihan rẹ, O lọ sinu ibi mimọ julọ ninu tẹmpili Ọlọrun ni ọrun. Òhun ni Daniẹli ṣe apejuwe Rẹ pẹlu wiwa, ni akoko yii, si ọdọ Arugbo Ọjọ: “Mo ri ninu awọn iran oru, si kiyesi, ẹnikan ti o dabi Ọmọ eniyan wa pẹlu ikuuku awọsanma, o si wá”—ki i ṣe sinu aye ṣugbọn—”si ọdọ Arugbo Ọjọ, a si mu wa siwaju Rẹ.” Danieli 7:13.ANN 188.3

    Woli Malaki tun ṣe asọtẹlẹ nipa wiwa yii: “Oluwa, ẹni ti ẹyin n wa, yoo wa sinu tẹmpili Rẹ lojiji, ani Iranṣẹ majẹmu, ẹni ti inu yin dun si: kiyesi, yoo wa, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi.” Malaki 3:1. Wiwa Oluwa sinu tẹmpili Rẹ jẹ ni ojiji ati ni airotẹlẹ fun awọn eniyan Rẹ. Wọn ko rò lati ri nibẹ. Wọn reti pe ki O wa si aye, “pẹlu ina ti n jo lati gbẹsan lara awọn ti ko mọ Ọlọrun, ti wọn ko si ṣe igbọran si iyinrere.” 2 Tẹsalonika 1:8.ANN 188.4

    Ṣugbọn awọn eniyan koi ti i ṣetan lati pade Oluwa wọn. Iṣẹ igbaradi ṣi wa fun wọn lati ṣe. A yoo fun wọn ni imọlẹ ti yoo dari iye wọn sinu tẹmpili Ọlọrun ni ọrun; ati bi wọn ba ṣe n fi igbagbọ tẹle Olu Alufa wọn ninu iṣẹ iranṣẹ nibẹ, ojuṣe tuntun yoo fi ara han fun wọn. A yoo fun ijọ ni iṣẹ iranṣẹ ikilọ ati ikọni miran.ANN 188.5

    Woli naa sọ pe: “Tani yoo le duro ni ọjọ wiwa Rẹ? tani yoo si le duro nigba ti O ba fi ara han? nitori oun dabi ina ẹni ti n da fadaka, ati bi ọṣẹ afọṣọ: Oun o si joko bi ẹni ti n yọ, ti o si n da fadaka: yoo si fọ awọn ọmọ Lefi mọ, yoo si fọ wọn mọ bi wura oun fadaka, ki wọn le mu ọrẹ wa fun Oluwa ninu ododo.” Malaki 3:2, 3. Awọn ti wọn ba wa laaye lori ilẹ aye nigba ti Kristi ba dawọ ẹbẹ duro ninu ibi mimọ loke yoo duro niwaju Ọlọrun mimọ laisi olubalaja. Aṣọ wọn nilati wa ni ailabawọn, a nilati fọ iwa wọn mọ kuro ninu ẹṣẹ nipasẹ ẹjẹ. Nipasẹ oore ọfẹ Ọlọrun ati iṣẹ atọkanwa wọn, wọn nilati di aṣẹgun ninu ijakadi pẹlu iwa buburu. Nigba ti idajọ iyẹwewo n lọ lọwọ ni ọrun, nigba ti a n mu ẹṣẹ awọn onigbagbọ ti wọn ronupiwada kuro ninu ibi mimọ, iṣẹ pataki ti ifọmọ, ti mimu ẹṣẹ kuro nilati maa lọ laarin awọn eniyan Ọlọrun ninu aye. Iṣẹ yii ni a ṣe afihan rẹ ninu awọn iṣẹ iranṣẹ ti Ifihan 14.ANN 188.6

    Nigba ti a ba pari iṣẹ yii, awọn atẹle Kristi a ti wa ni imuratan fun ifarahan Rẹ. “Nigba naa ni inu Oluwa yoo dun si ọrẹ Juda ati ti Jerusalẹmu, gẹgẹ bi o ti wa ni awọn ọjọ ogbó wa, ati ni awọn ọdun atẹyinwa.” Malaki 3:4. Nigba naa ni ijọ ti Oluwa yoo gba fun ara Rẹ ni igba wiwa Rẹ yoo jẹ “ijọ ologo ti ko ni abawọn, tabi aleebu, tabi iru nnkan bawọni.” Efesu 5:27. Nigba naa ni yoo tan bi owurọ, yoo ni ẹwa bi oṣupa, yoo mọ bi oorun, yoo si ni ẹru bi ẹgbẹgun pẹlu ọpagun.” Orin Solomoni 6:10.ANN 189.1

    Ni afikun si wiwa Oluwa sinu tẹmpili Rẹ, Malaki tun sọtẹlẹ nipa ipadabọ lẹẹkeji, wiwa Rẹ lati ṣe idajọ bayii: “Emi yoo si sun mọ yin fun idajọ, emi yoo si ṣe ẹlẹri yiyara si awọn oṣó, ati si awọn panṣaga, ati si awọn abura eke, ẹni ti n ni alagbaṣe lara ninu owo ọya re, ati opó ati alainibaba, ati si ẹni ti n rẹ alejo jẹ, ti wọn ko si bẹru Mi, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi.” Malaki 3:5. Juda sọ nipa iṣẹlẹ kan naa nigba ti o wipe, “Kiyesi, Oluwa n bọ wa pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan mimọ Rẹ, lati ṣe idajọ gbogbo eniyan, ati lati da awọn alaiwabiọlọrun laarin wọn lẹbi nitori awọn iwa alaiwabiọlọrun wọn.” Juda 14, 15. Wiwa yii, ati wiwa Oluwa sinu tẹmpili Rẹ, jẹ iṣẹlẹ ti wọn yatọ si ara wọn patapata.ANN 189.2

    Wiwa Kristi gẹgẹ bi olu alufa si inu ibi mimọ julọ, fun fifọ ibi mimọ mọ ti a sọ ninu Daniẹli 8:14, wiwa Ọmọ eniyan si ọdọ Arugbo Ọjọ, bi a ti ṣe alaye rẹ ninu Daniẹli 7:13, ati wiwa Oluwa sinu tẹmpili Rẹ, ti Malaki ṣe asọtẹlẹ rẹ jẹ alaye iṣẹlẹ kan naa; eyi pẹlu ni a ṣe afihan rẹ pẹlu wiwa ọkọ iyawo si ibi igbeyawo, ti Kristi ṣe alaye ninu owe awọn wundia mẹwa ti Matiu 25.ANN 189.3

    Ni igba ẹrun ati igba ikore 1844, a ṣe ikede, “Kristi Ọkọ iyawo n bọ.” Nigba naa ni awọn ẹgbẹ mejeeji ti a ṣe afihan wọn pẹlu wundia ọlọgbọn ati alaigbọn dide—ẹgbẹ kan ti n fi ayọ wọna fun wiwa Oluwa, to si n fi tọkantọkan mura silẹ lati pade Rẹ; ati ẹgbẹ miran ti o wuwa nitori ibẹru, ti o n ṣe ipinu laimọ ohun ti a n sọ, wọn jẹ ki agbekalẹ otitọ o tẹ wọn lọrun, ṣugbọn wọn ko ni oore ọfẹ Ọlọrun. Ninu owe naa, nigba ti ọkọ iyawo de, “awọn ti wọn wa ni imuratan lọ pẹlu rẹ si ibi igbeyawo.” Nibi a ri wipe wiwa ọkọ iyawo ṣaaju eto igbeyawo. Igbeyawo duro fun gbigba ti Kristi gba ijọba Rẹ. Ilu mimọ naa, Jerusalẹmu Tuntun, ti o jẹ olu ilu ati aṣoju ijọba naa, ni a pe ni “iyawo, iyawo Ọdọ Aguntan.” Angẹli naa sọ fun Johanu wipe: “Maa bọ nibi, emi yoo fi iyawo Ọdọ Aguntan naa han ọ.” Woli naa sọ pe “O gbe mi lọ ninu ẹmi, o si fi ilu nla naa han mi, Jerusalẹmu mimọ ti o n sọkalẹ wa lati ọdọ Ọlọrun.” Ifihan 21:9, 10. O han gbangba wipe iyawo naa duro fun Ilu Mimọ naa, awọn wundia ti wọn lọ pade ọkọ iyawo si duro fun ijọ. Ninu Ifihan a sọ wipe awọn eniyan Ọlọrun jẹ alejo nibi ase igbeyawo. Ifihan 19:9. Bi wọn ba jẹ alejo, a ko le fi iyawo ṣe akajuwe wọn. Bi woli Daniẹli ti sọ, Kristi yoo gba, “agbara, ati ogo, ati ijọba” lọwọ Arugbo Ọjọ ni ọrun; yoo gba Jerusalẹmu Tuntun, olu ilu ijọba Rẹ, “ti a pese gẹgẹ bi iyawo ti a ṣe lọṣọ fun ọkọ rẹ.” Daniẹli 7:14; Ifihan 21:2. Lẹyin ti O ba gba ijọba naa tan, yoo wa ninu ogo Rẹ, gẹgẹ bi Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa, fun irapada awọn eniyan Rẹ, ti yoo “joko pẹlu Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu,” ni ori tabili Rẹ ninu ijọba Rẹ (Matiu 8:11; Luku 22:30), lati kopa ninu onjẹ alẹ ti igbeyawo Ọdọ Aguntan.ANN 189.4

    Ikede wipe, “Wo o Ọkọ iyawo n bọ wa” ni igba ẹrun 1844, mu ki ọpọ eniyan o reti wiwa Oluwa lọgan. Ni akoko ti a yan Ọkọ iyawo wa, ki i ṣe sinu aye, bi awọn eniyan ti n reti, ṣugbọn lọ si ọdọ Arugbo Ọjọ ni ọrun, lọ si ibi igbeyawo, gbigba ijọba Rẹ. “Awọn ti wọn ṣetan wọle pẹlu Rẹ lọ si ibi igbeyawo: a si ti ilẹkun.” Wọn ki yoo wa nibi igbeyawo naa ni ti ara; nitori ti yoo waye ni ọrun, nigba ti awọn wa lori ilẹ aye. Awọn atẹle Kristi nilati “duro de Oluwa wọn, nigba ti yoo ba pada de lati ibi igbeyawo.” Luku 12:36. Ṣugbọn wọn nilati ni oye iṣẹ Rẹ, ki wọn si fi igbagbọ tẹle bi O ti n wọle siwaju Ọlọrun. Ni ọna yii ni a fi le sọ wipe wọn lọ si ibi igbeyawo.ANN 189.5

    Ninu owe naa awọn ti wọn ni epo sinu kolobo wọn pẹlu fitila wọn ni wọn wọle si ibi igbeyawo. Awọn ti wọn ni imọ otitọ lati inu Iwe Mimọ, ti wọn tun ni Ẹmi ati oore ọfẹ Ọlọrun, ti wọn si fi suuru duro, ti wọn n wa Bibeli fun imọlẹ ti o mọlẹ si ni aṣalẹ idanwo kikoro—awọn wọnyi ri otitọ nipa ibi mimọ ni ọrun, ati bi Olugbala ti yipada ninu iṣẹ iranṣẹ Rẹ, pẹlu igbagbọ wọn tẹle ninu iṣẹ Rẹ ni ibi mimọ loke. Gbogbo awọn ti wọn gba otitọ kan naa latari ẹri Iwe Mimọ, n tẹle Kristi nipa igbagbọ bi O ti n wọle siwaju Ọlọrun lati ṣe iṣẹ ibalaja ti o kẹyin, ati ni opin rẹ, yoo gba ijọba Rẹ—gbogbo awọn wọnyi ni a ṣe afihan wọn wipe wọn wọle si ibi igbeyawo.ANN 189.6

    Ninu owe Matiu 22 akawe ti igbeyawo kan naa ni a lo, a si fihan kedere wipe idajọ iyẹwewo waye ṣaaju igbeyawo. Ṣaaju ki igbeyawo to ṣẹlẹ, ọba wa lati wa wo awọn alejo, lati ri boya gbogbo wọn ni wọn wọ aṣọ igbeyawo, aṣọ iwa mimọ ti a fọ, ti a sọ di funfun ninu ẹjẹ Ọdọ Aguntan. Matiu 22:11; Ifihan 7:14. A sọ ẹni ti ko kun oju oṣuwọn sita, ṣugbọn gbogbo awọn ti a ri wipe wọn wọ aṣọ igbeyawo lẹyin ti a yẹ wọn wo ni Ọlọrun gba ti a si ka wọn yẹ lati ni ipin ninu ijọba Rẹ ati lati joko lori itẹ Rẹ. Iṣẹ yiye iwa wo yii, ti mímọ awọn ti a pese silẹ fun ijọba Ọlọrun, ni i ṣe idajọ iyẹwewo, iṣẹ aṣekagba ninu ibi mimọ loke.ANN 190.1

    Nigba ti iṣẹ iyẹwewo ba pari, nigba ti a ba ti ṣe ayẹwo, ti a si ṣe idajọ gbogbo awọn ti wọn sọ wipe wọn jẹ atẹle Kristi ni gbogbo akoko, nigba naa ni akoko oore ọfẹ yoo pari, ilẹkun aanu yoo si ti. Bayi ni akotan, “Awọn ti wọn ṣetan ba wọle sinu ibi igbeyawo: a si ti ilẹkun,” a fi iṣẹ iranṣẹ Olugbala titi de akoko ikẹyin han wa titi fi di akoko ti a o pari iṣẹ nla fun igbala eniyan.ANN 190.2

    Ninu isin ibi mimọ ti aye yii, eyi ti, gẹgẹ bi a ti ri, jẹ apẹẹrẹ isin ninu ibi mimọ ti ọrun, nigba ti olu alufa ni Ọjọ Iwẹnumọ ba wọ inu ibi mimọ julọ, iṣẹ iranṣẹ ninu yara akọkọ a pari. Ọlọrun paṣẹ pe: “Ẹnikẹni ko gbọdọ si ninu agọ ajọ nigba ti a ba wọle lati ṣe iwẹnumọ ninu ibi mimọ, titi ti yoo fi jade.” Lefitiku 16:17. Nitori naa nigba ti Kristi wọ ibi mimọ julọ lati ṣe iṣẹ aṣekagba ti iwẹnumọ, O pari iṣẹ iranṣẹ ninu yara akọkọ. Ṣugbọn nigba ti iṣẹ iranṣẹ ninu yara akọkọ ba pari, iṣẹ iranṣẹ ninu yara keji a bẹrẹ. Ninu iṣẹ apẹẹrẹ, nigba ti olu alufa ba kuro ni ibi mimọ ni Ọjọ Iwẹnumọ, yoo lọ siwaju Ọlọrun pẹlu ẹjẹ ẹbọ ẹṣẹ fun awọn ọmọ Israeli ti wọn ronupiwada fun ẹṣẹ wọn nitootọ. Bẹẹ gẹgẹ Kristi ṣẹṣẹ pari abala kan ninu iṣẹ Rẹ gẹgẹ bi alagbawi wa ni, lati le bẹrẹ abala miran ninu iṣẹ Rẹ, O si n fi ẹjẹ Rẹ bẹbẹ niwaju Baba nitori ẹlẹṣẹ.ANN 190.3

    Koko ọrọ yii ko ye awọn Onireti ni 1844. Nigba ti akoko ti a n reti Olugbala kọja, wọn si gbagbọ wipe wiwa Rẹ sunmọ etile; wọn gba wipe wọn de ibi iṣoro nla, ati wipe iṣẹ Kristi gẹgẹ bi alagbawi wọn niwaju Baba ti pari. Wọn ri wipe a kọni ninu Bibeli wipe akoko oore ọfẹ fun eniyan yoo pari ni akoko diẹ ṣaaju wiwa Oluwa ninu ikuuku awọsanma. Eyi fi ara han lati inu ẹṣẹ Iwe Mimọ ti wọn tọka si akoko ti awọn eniyan a wa kiri, ti wọn a kan lẹkun, ti wọn a kigbe ni ẹnu ọna aanu, ti ki yoo si ṣi. Wọn wa n ro wipe boya akoko ti wọn n reti wiwa Kristi ni yoo jẹ ibẹrẹ akoko ti yoo wa ṣaaju wiwa Rẹ. Lẹyin ti wọn ti ṣe ikilọ nipa idajọ ti o sunmọ tosi, wọn ro wipe iṣẹ wọn fun araye ti pari, wọn si padanu ifẹ wọn fun igbala awọn ẹlẹṣẹ, wọn tun ri isọrọ- odi pẹlu igboya awọn alaiwabiọlọrun gẹgẹ bi idi miran lati gbagbọ wipe a ti gba Ẹmi Ọlọrun kuro lọdọ awọn ti wọn ti kọ aanu Rẹ silẹ. Gbogbo awọn nnkan wọnyi tubọ mu ki wọn gbagbọ wipe akoko oore ọfẹ ti pari, tabi, bi wọn ti sọ nigba naa, “a ti ti ilẹkun aanu.”ANN 190.4

    Ṣugbọn imọlẹ ti o han kedere ṣi wa pẹlu ayẹwo koko ọrọ ibi mimọ. Wọn ri wipe wọn tọna lati gbagbọ wipe opin 2300 ọjọ ní 1844 sami si iṣoro nla. Ṣugbọn nigba ti o jẹ otitọ wipe ilẹkun ireti ati ti aanu nipasẹ eyi ti awọn eniyan fi ri aaye si ọdọ Ọlọrun fun 1800 ọdun ti tì, ilẹkun miran ṣi silẹ, a fun awọn eniyan ni idariji ẹṣẹ nipasẹ iṣẹ ẹbẹ Kristi ni ibi mimọ julọ. Abala kan ninu iṣẹ iranṣẹ Re ti pari, ṣugbọn o jẹ ki omiran o bẹrẹ ni. Ilẹkun miran wa ṣí silẹ wọ inu ibi mimọ ni ọrun, nibi ti Kristi ti n ṣiṣẹ nitori ẹlẹṣẹ.ANN 190.5

    Ni bayii, a wa ri itumọ awọn ọrọ Kristi ninu Ifihan, ti o sọ fun ijọ ni akoko yii gan wipe: “Awọn nkan wọnyi ni Ẹni ti o jẹ mimọ, ti i ṣe otitọ, ti O ni kọkọrọ Dafidi, Ẹni ti O ṣi, ti ẹnikẹni ko le tì; ti O tì, ti ẹnikẹni ko le ṣi wí; Emi mọ iṣẹ rẹ: kiyesi Mo gbe ilẹkun ti a ṣi silẹ siwaju rẹ, ti ẹnikẹni ko le ti.” Ifihan 3:7, 8.ANN 190.6

    Awọn ti wọn tẹle Kristi ninu iṣẹ nla iwẹnumo nipa igbagbọ ni yoo gba anfani ibalaja Rẹ fun wọn, nigba ti awọn ti wọn kọ imọlẹ ti o ṣe alaye iṣẹ iranṣẹ yii silẹ ki yoo ri ibukun rẹ. Awọn Ju ti wọn kọ imọlẹ ti a fifun wọn ni igba wiwa Kristi ni akọkọ sile, ti wọn kọ lati gbagbọ ninu Rẹ gẹgẹ bi Olugbala araye, ko le ri idariji ẹṣẹ nipa Rẹ. Nigbati Kristi goke lọ si ọrun, O wọ inu ibi mimọ lọ pẹlu ẹjẹ ara Rẹ lati tan ibukun igbala Rẹ si ori awọn ọmọ ẹyin Rẹ, a fi awọn Ju silẹ ninu okunkun biribiri lati tẹsiwaju ninu ẹbọ ati ọrẹ wọn, eyi ti ko ni itumọ. Iṣẹ iranṣẹ apẹẹrẹ ati ojiji ti pari. Ilẹkun yẹn, nibi ti awọn eniyan ti ri aaye wa si ọdọ Ọlọrun tẹlẹ ko le ṣi mọ. Awọn Ju kọ lati wa ni ọna kan ṣoṣo ti wọn fi le ri, nipasẹ iṣẹ iranṣẹ Rẹ ninu ibi mimọ ni ọrun. Nitori naa, wọn ko ni ibaṣepọ pẹlu Ọlọrun. A ti ti ilẹkun naa mọ wọn. Wọn ko ni oye Kristi gẹgẹ bi ẹbọ tootọ ati olubalaja kan ṣoṣo niwaju Ọlọrun; nitori naa wọn ko le gba ibukun iṣẹ igbala Rẹ.ANN 190.7

    Ipo ti awọn Ju ti wọn jẹ alaigbagbọ wa ṣe apejuwe ipo ti awọn alaibikita ati alaigbagbọ laarin awọn Kristẹni wa, awọn ti wọn mọọmọ jẹ alaimọkan nipa iṣẹ Olu Alufa alaanu wa. Ninu isin ti apẹẹrẹ, nigba ti olu alufa ba wọ inu ibi mimọ julọ, gbogbo Israeli ni yoo pejọ pọ yi ibi mimọ ka, wọn a si fi tọwọtọwọ rẹ ọkan wọn silẹ niwaju Ọlọrun, ki wọn baa le gba idariji fun ẹṣẹ wọn ati ki a ma baa ge wọn kuro ninu ijọ. Bawo ni o ti ṣe pataki to ninu amuṣẹ apẹẹrẹ Ọjọ Iwẹnumọ lati ni oye iṣẹ Olu Alufa wa, ki a si mọ ojuṣe ti a n fẹ lati ọdọ wa.ANN 191.1

    Awọn eniyan ko le maa kọ ikilọ ti Ọlọrun ran si wọn ninu aanu silẹ laijiya. A ran iṣẹ iranṣẹ lati ọrun si araye ni akoko Noah, igbala wọn si duro lori bi wọn ba ti ṣe dahun si iṣẹ iranṣẹ naa. Nitori ti wọn kọ ikilọ naa silẹ, a mu Ẹmi Ọlọrun kuro lọdọ iran ẹlẹṣẹ, wọn si ṣegbe sinu Ikun Omi. Ni akoko Abrahamu, aanu kọ lati bẹbẹ fun awọn ti wọn jẹbi ninu awọn olugbe Sodomu, gbogbo wọn ayafi Lọti pẹlu iyawo ati awọn ọmọbinrin rẹ meji ni wọn ṣegbe ninu ina ti a ran lati ọrun. Bẹẹ gẹgẹ ni o ri ni awọn akoko Kristi. Ọmọ Ọlọrun sọ fun awọn Ju alaigbagbọ ni akoko naa pe: “A fi ile yin silẹ fun yin ni isọdahoro” Matiu 23:38. Ni wiwo sun un dé igba ikẹyin, Agbara ayeraye kan naa sọ nipa awọn ti wọn “ko gba ifẹ fun otitọ, ki a baa le gba wọn la:” “Nitori idi eyi Ọlọrun yoo ran itanjẹ ti o lagbara si wọn, ki wọn baa le gba irọ gbọ, ki gbogbo awọn ti ko gba otitọ gbọ ṣugbọn ti wọn ni inudidun ninu aiṣododo baa le di ẹni egbe.” 2 Tẹsalonika 2:10—12. Bi wọn ti kọ awọn ikọni ọrọ Rẹ silẹ, Ọlọrun gba Ẹmi Rẹ, O si fi wọn silẹ pẹlu itanjẹ ti wọn yan.ANN 191.2

    Ṣugbọn Kristi ṣi n bẹbẹ nitori eniyan, a yoo si fi imọlẹ fun ẹnikẹni ti o ba wa. Bi o tilẹ jẹ wipe awọn Onireti ko kọkọ ni oye eyi, nikẹyin o han kedere si wọn bi Iwe Mimọ ti o ṣe alaye ipo ti wọn wa gan an ti n ṣi silẹ niwaju wọn.ANN 191.3

    Akoko idanwo nla ni o tẹle ikọja akoko ni 1844 fun awọn ti wọn ṣi ni igbagbọ ninu ipadabọ. Itunu kan ṣoṣo ti wọn ni, gẹgẹ bi o ti ni i ṣe pẹlu ipo wọn nitootọ ni imọlẹ ti o dari ọkan wọn si ibi mimọ ni oke. Awọn miran kọ igbagbọ wọn silẹ ninu iṣọwọka akoko iṣọtẹlẹ ti wọn n lo tẹlẹ, wọn si sọ wipe agbara Satani tabi iṣẹ eniyan ni agbara Ẹmi Mimọ ti o tẹle ẹgbẹ ipadabọ. Awọn ẹgbẹ miran gbagbọ tọkantọkan wipe Oluwa ni O dari wọn ninu iriri wọn latẹyin wa; bi wọn si ti duro ti wọn n wọna ti wọn si n gbadura lati mọ ifẹ Ọlọrun, wọn ri wipe Olu Alufa nla wọn ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ miran, ati ni titẹle pẹlu igbagbọ a dari wọn lati ri iṣẹ aṣekagba ti ijọ. Wọn ni oye ti o yè kooro si nipa iṣẹ iranṣẹ angẹli ikini ati ekeji, a si pese wọn silẹ lati gba ati lati fi ikilọ ẹlẹru ti iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta ti Ifihan 14 fun araye.ANN 191.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents